MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI
Ṣé O Máa Ń Kíyè sí Bí Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Ẹ?
Ọ̀pọ̀ àpẹẹrẹ àwọn àdúrà tí Jèhófà dáhùn ló wà nínú Bíbélì. Kò sí àní-àní pé nígbà táwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run rí bí Jèhófà ṣe dáhùn àdúrà wọn, tó sì ràn wọ́n lọ́wọ́, ìgbàgbọ́ wọn túbọ̀ lágbára. Torí náà, nígbàkigbà tá a bá ń gbàdúrà láyè ara wa, á dáa ká jẹ́ kí àdúrà wa ṣe pàtó, ká wá kíyè sí bí Jèhófà ṣe máa dáhùn àdúrà náà. Ká má gbàgbé pé ọ̀nà tí Ọlọ́run lè gbà dáhùn àdúrà wa lè yàtọ̀ sí ohun tá a rò tàbí kó tiẹ̀ ṣe ju ohun tá a béèrè. (2Kọ 12:7-9; Ef 3:20) Kí làwọn nǹkan tí Jèhófà lè ṣe fún wa tá a bá gbàdúrà sí i?
Ó lè fún wa ní okun nípa tara tàbí ìgbàgbọ́ tá a nílò láti kojú ìṣòro kan.—Flp 4:13
Ó lè fún wa ní ọgbọ́n táá jẹ́ ká lè ṣe ìpinnu tó tọ́.—Jem 1:5
Ó lè mú kó wù wá láti gbé ìgbésẹ̀ kan, kó sì fún wa lágbára láti ṣe é.—Flp 2:13
Ó lè jẹ́ kí ọkàn wa balẹ̀ nígbà tá a bá ń ṣàníyàn.—Flp 4:6, 7
Ó lè mú káwọn míì ràn wá lọ́wọ́ kí wọ́n sì tù wá nínú.—1Jo 3:17, 18
Ẹ WO FÍDÍÒ NÁÀ JÈHÓFÀ NI “OLÙGBỌ́ ÀDÚRÀ,” KẸ́ Ẹ SÌ DÁHÙN ÀWỌN ÌBÉÈRÈ YÌÍ:
Báwo ni ìrírí Arákùnrin Shimizu ṣe lè fún wa níṣìírí tí àìsàn ò bá jẹ́ ká lè ṣe tó bá a ṣe ń ṣe tẹ́lẹ̀?
Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Arákùnrin Shimizu?