ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w91 9/15 ojú ìwé 4-6
  • Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?
  • Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹri Pe Ọlọrun Ndahun Awọn Adura
  • Idi Ti A Ko Fi Dahun Awọn Adura Kan
  • Jesu ‘Ni A Fi Ojurere Gbọ́ Tirẹ’
  • Bi Jehofa Ṣe Ndahun Awọn Adura Lonii
  • Adura Wọn Ni A Dahun
  • Sún Mọ́ Ọlọ́run Nípasẹ̀ Àdúrà
    Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an?
  • Báwo Ni Jèhófà Ṣe Ń Dáhùn Àdúrà Wa?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2023
  • Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2021
  • Ǹjẹ́ Ọlọrun a Maa Fetisilẹ Nigba Ti Iwọ Bá Gbadura Bi?
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1992
Àwọn Míì
Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1991
w91 9/15 ojú ìwé 4-6

Adura Awọn Wo Ni A Ndahun?

JEHOFA ni Ọlọrun ti ndahun awọn adura. Nitootọ, Ọrọ rẹ̀, Bibeli, pe e ni “Olugbọ adura.” (Saamu 65:2, New World Translation) O muratan lati dahun awọn adura. Ṣugbọn adura awọn wo ni ó ndahun niti gidi?

Ọlọrun ndahun adura awọn ẹni ti wọn nṣe ohun ti o wù ú. Wọn ni iṣarasihuwa ọlọwọ ti onisaamu naa tí ó wi pe: “Bi agbọrin ti maa mi hẹlẹ si ipadò omi, Ọlọrun, bẹẹ ni ọkan mi nmi hẹlẹ si ọ. Oungbẹ Ọlọrun ngbẹ ọkàn mi, ti Ọlọrun alaaye.” (Saamu 42:1, 2) Sibẹ, ẹri wo ni o wà nibẹ lati fihan pe Jehofa ndahun adura awọn olujọsin rẹ̀ tootọ?

Ẹri Pe Ọlọrun Ndahun Awọn Adura

Bibeli ní akọsilẹ jàn-ànràn jan-anran ti nfi ẹri han pe Jehofa ndahun adura awọn iranṣẹ rẹ̀ oluṣotitọ. Fun apẹẹrẹ, nigba ti Ọba Jehoṣafati ti Juuda gbadura fun ìdáǹdè, Ọlọrun dahun awọn adura rẹ o si fun un ni iṣẹgun nipa mimu ki awọn ọta rẹ̀ pa araawọn ẹnikinni keji. (2 Kironika 20:1-26) Lọna ti o farajọra nigba ti Ọba Hesekaya dojukọ agbo ologun ti o ṣoro lati ṣẹgun, o fi tirẹlẹ tirẹlẹ gbadura si Ọlọrun fun iranlọwọ. Hesekaya ri igbala Jehofa nigba ti angẹli kan lu 185,000 awọn ara Asiria pa ni òru kan.—Aisaya 37:14-20, 36-38.

Eeṣe ti Ọlọrun fi dahun awọn adura wọnni? Ninu ọran mejeeji, awọn ọba naa bẹbẹ pe pipadanu ogun naa yoo mu abuku bá orukọ Jehofa. (2 Kironika 20:6-9; Aisaya 37:17-20) Wọn daniyan nipa orukọ rere rẹ̀. Iwe gbédègbẹ́yọ̀ naa, The International Standard Bible Encyclopedia wi pe, “Ete gigajulọ ti adura kii ṣe kiki ire ẹni ti ńjírẹ̀ẹ́bẹ̀ nikan ṣugbọn ibọla fun orukọ Ọlọrun.” Nitori naa, awọn iranṣẹ Jehofa oluṣotitọ le ni idaniloju pe oun yoo ran wọn lọwọ “nitori orukọ rẹ̀.” Akọsilẹ naa ti nfi ẹri hàn pé iru awọn adura bẹẹ ni a ti dahun fún awọn eniyan Ọlọrun ni igbọkanle pe ó ngbọ awọn adura wọn.—Saamu 91:14, 15; 106:8; Owe 18:10.

Bi o ti wu ki o ri, bi ipo kan ba tilẹ wémọ́ orukọ Jehofa paapaa, Ọlọrun ni npinnu yala lati dahun awọn adura kan tabi bẹẹkọ. Oun le ni awọn idi ti o lẹsẹnilẹ lati maṣe dahun awọn adura kan. Bi a ba nimọlara pe awọn adura wa ni a ko gbọ́, ó dara lati gbé idi ti eyi fi le jẹ bẹẹ yẹwo.

Idi Ti A Ko Fi Dahun Awọn Adura Kan

Jehofa sọ fun awọn ọmọ Isirẹli nigba kan rí pe: “Nigba ti ẹyin ba gba adura pupọ, emi ki yoo gbọ́.” Ni titọka si idi rẹ̀, o nbaa lọ pe: “Ọwọ yin kun fun ẹjẹ.” (Aisaya 1:15) Bawo ni ẹnikan ṣe le ṣá ofin Ọlọrun tì sibẹ ki o si ni anfaani jíjẹ́ ẹni tí Ọlọrun fetisilẹ si? Owe Bibeli kan funni ni idahun kedere, ni wiwi pe: “Ẹni ti o mu eti rẹ̀ kuro lati gbọ́ ofin, ani adura rẹ̀ paapaa yoo di irira.”—Owe 28:9.

Bibeli funni ni idi miiran ti awọn adura kan fi di eyi ti a ko gbọ́, nigba ti o wi pe: “Ẹyin beere, ẹ ko si rígbà, nitori ti ẹyin ṣì í beere, ki ẹyin ki o le lo o fun ifẹkufẹẹ ara yin.” (Jakọbu 4:3) Bẹẹkọ, Jehofa ki yoo dahun awọn adura fun titẹ ifẹ-ọkan ti ko tọna lọrun. Awa tun gbọdọ ranti pe Ọlọrun kii gba aṣẹ lati ọdọ eniyan, ki a sọ ọ lọna bẹẹ. Oun ni Ẹni naa ti npinnu bi oun yoo ṣe dahun awọn adura wa.

Awọn adura ti ó daju pe a o dahun ni eyi ti o lọ si ọdọ Ọlọrun lati inu ọkan-aya mimọ, pẹlu isunniṣe titọna, ati ni ọna rẹ̀ ti o yàn—nipasẹ Jesu Kristi. (Johanu 14:6, 14) Ṣugbọn awọn wọnni ti adura wọn kun oju iwọn iru awọn ohun bẹẹ ti a beere fun paapaa ti nimọlara ni awọn igba miiran pe a ko gbọ wọn. Eeṣe ti Ọlọrun ki yoo fi dahun adura awọn iranṣẹ rẹ̀ kan ni pataki lẹsẹkẹsẹ?

Jehofa mọ akoko ti o dara julọ lati dahun awọn adura. Bi o tilẹ jẹ pe ọmọkunrin kan le beere fun kẹ̀kẹ́, baba rẹ̀ le ma ra a fun un titi di igba ti ọmọ naa ba dagba tó lati gun un laisewu. Ohun kan naa ni o jẹ otitọ pẹlu diẹ lara awọn adura awọn wọnni ti wọn fẹran Ọlọrun. Ni mimọ ohun ti o dara julọ fun wọn, o yọnda ohun ti wọn nilo ni akoko ti o wọ̀ julọ.

Sibẹ, awọn iranṣẹ Jehofa kii ri gbogbo ohun ti wọn le gbadura fun gbà. Bi wọn ti jẹ alaipe, wọn le fẹ awọn ohun kan ti o le ma dara fun wọn. Baba wọn onifẹẹ ti ọrun ki yoo fun wọn ni ohunkohun ti o lewu, nitori pe oun ni Olufunni ni “gbogbo ẹbun rere ati gbogbo ẹbun pipe.” (Jakọbu 1:17) Bakan naa, Ọlọrun le má yọnda ohun kan ti ko pọndandan lati oju-iwoye rẹ̀. (Fiwe 2 Kọrinti 12:7-10.) Ó ndahun awọn adura ni ibamu pẹlu ifẹ-inu ati ete rẹ̀ fun awọn eniyan rẹ̀.—1 Johanu 5:14, 15.

Jesu ‘Ni A Fi Ojurere Gbọ́ Tirẹ’

Jesu jẹ ẹni ti o maa ngbadura. (Matiu 6:9-13; Johanu 17:1-26) O ni igbọkanle kikun pe Baba rẹ̀ ọrun yoo gbọ yoo si dahun awọn adura rẹ̀. Jesu sọ lẹẹkan ri pe: “Baba, . . . emi si ti mọ pe, iwọ a maa gbọ ti emi nigba gbogbo.” (Johanu 11:41, 42) Ṣugbọn a ha já Jesu kulẹ ni opin ọna igbesi-aye rẹ̀ lori ilẹ-aye gan an bi? Oun ko ha ké jade pe: “Ọlọrun mi, Ọlọrun mi, eeṣe ti iwọ fi kọ̀ mi silẹ?”—Matiu 27:46.

Nigba ti Jesu sọ awọn ọrọ wọnni, ó daju pe ó nmu asọtẹlẹ kan nipa iku rẹ̀ ṣẹ. (Saamu 22:1) Ni itumọ ti o ni aala, Jesu tun le ti ni in lọkan pe Jehofa ti mu aabo rẹ kuro ti o si jẹ ki Ọmọkunrin rẹ̀ ku iku onirora ati onitiju ki o ba le dan iwatitọ rẹ̀ wò dé gongo. Ayẹwo awọn iṣẹlẹ ọjọ ti o kẹhin igbesi-aye Jesu lori ilẹ-aye yẹn fihan pe Ọlọrun gbọ awọn adura rẹ̀.

Ni alẹ ti a fi aṣẹ ọba mu un, Jesu gbadura ninu ọgba Getisemani. Lẹẹmẹta o bẹbẹ pe: “Baba mi, bi o ba le ṣe, jẹ ki ago yii ki o kọja kuro lori mi.” (Matiu 26:39, 42, 44) Jesu ko lọra lati fi iwalaaye rẹ̀ funni gẹgẹ bi irapada fun araye onigbagbọ. Bẹẹkọ, ṣugbọn oun ni kedere ndaniyan lọna ti o jinlẹ nipa ṣiṣeeṣe ti ó wà pe ki oun ṣai bọla fun Baba rẹ̀ ọ̀wọ́n ati onifẹẹ nipa kiku lori opo igi idaloro gẹgẹ bi asọrọ odi ẹni ifibu kan. Njẹ Jehofa gbọ adura Jesu bi?

Ni ọpọ ọdun lẹhin naa apọsiteli Pọọlu kọwe pe: “Ni ọjọ rẹ̀ ninu ara Kristi gba awọn adura ẹbẹ ati awọn ibeere ẹbẹ pẹlu si Ẹni naa ti o le gba a la lọwọ iku, pẹlu igbe kikankikan ati omije, a si fi ojurere gbọ́ tirẹ nitori ibẹru oniwa bi Ọlọrun rẹ̀.” (Heberu 5:7, NW; Luuku 22:42, 44) Bẹẹni, ni alẹ onirora ti o ṣaaju iku rẹ̀, Jesu ‘ni a fi ojurere gbọ́ tirẹ.’ Ṣugbọn bawo?

Jehofa ran angẹli kan ẹni ti o fi ara han [Jesu ti] o sì fun un lokun.” (Luuku 22:43, NW) Bi a ti tipa bayii fun un lokun, Jesu le dojukọ iku lori opo igi idaloro. Ni kedere, Jehofa lẹhin naa fun un ni idaniloju pe iku rẹ̀ lori opo igi ki yoo mu ẹ̀gàn wa sori orukọ atọrunwa naa ṣugbọn yoo jẹ ohun naa gan an ti a lo lati sọ ọ di mimọ ni asẹhinwa asẹhinbọ. Dajudaju, iku Jesu lori opo igi idaloro ṣí ọna silẹ fun awọn Juu, ti wọn iba ti jẹ́ ẹni ifibu labẹ Ofin bi ko ba rí bẹẹ, lati di awọn ti a gbala kuro lọwọ idalẹbi si iku.—Galatia 3:11-13.

Ọjọ mẹta lẹhin naa, Jehofa ji Jesu dide o si mu ẹsun isọrọ odi eyikeyii ti o ṣeeṣe kuro lori rẹ̀ nipa gbigbe e ga si ipo gigalọla ju ni ọrun. (Filipi 2:7-11) Ẹ wo ọna agbayanu ti a gba dahun adura Jesu nipa “ago yii”! Adura yẹn ni a dahun ni ọna ti Jehofa. Jesu si niriiri awọn ibukun agbayanu nitori pe o ti sọ fun Baba rẹ̀ ọrun pe: “Ifẹ ti emi kọ́, bikoṣe tirẹ ni ki a ṣe.”—Luuku 22:42.

Bi Jehofa Ṣe Ndahun Awọn Adura Lonii

Bii Jesu, awọn wọnni ti wọn nfẹ lati wu Jehofa lonii nilati maa beere nigba gbogbo pe ki ifẹ-inu Ọlọrun di ṣiṣe. Wọn nilati ni igbagbọ pe Jehofa yoo dahun awọn adura wọn ni ọna kan ti yoo ṣanfaani fun wọn julọ. Nitootọ, ohun yoo ‘ṣe lọpọlọpọ ju gbogbo eyi ti wọn nbeere tabi ti wọn rò.’—Efesu 3:20.

Obinrin Kristẹni ọdọ kan ti ngbe pẹlu awọn obi rẹ̀ alaigbagbọ niriiri ijotiitọ iwe mimọ yẹn. Ninu lẹta kan lati ọdọ Watch Tower Society, a sọ fun un pe ki o fi taduratadura gbe ṣiṣeeṣe ti titẹwọgba akanṣe iṣẹ ijihin iṣẹ Ọlọrun yẹwo. Bi o tilẹ jẹ pe ifẹ atọkanwa rẹ ni lati duro ni ile lati ran awọn obi rẹ̀ lọwọ lati di Kristẹni, o sọ fun Ọlọrun ninu adura pe: “Ki ni o jẹ ifẹ-inu rẹ? Ṣe ki ntẹwọgba ikesini yii laika atako awọn obi mi si ni, tabi o ha jẹ lati ran awọn obi mi lọwọ nipa biba a lọ lati maa gbe pẹlu wọn?” Ni gbogbo igba ti o ba ti gbadura, ẹri ọkan rẹ̀ a sọ fun un pe ki o tẹwọgba ikesini naa. O pinnu pe eyi jẹ idahun lati ọdọ Jehofa.

Ọlọrun fun obinrin yii lokun lati rọ̀ mọ́ ipinnu rẹ̀ timọtimọ. Nigba ti a sọ fun un pe ki o ṣí lọ si Erekuṣu Awaji, Japan, awọn obi rẹ̀ ni a mu wárìrì ti wọn si mu atako wọn pọ sii. Bi o ti wu ki o ri, nigba ti wọn ko le yi i lọkan pada lati yí ero rẹ̀ pada, iya rẹ̀ pinnu lati kẹkọọ Bibeli kiki lati ri idi rẹ̀ ti ọmọbinrin rẹ̀ fi ṣe iru ipinnu bẹẹ. Oṣu mẹta lẹhin naa awọn obi rẹ̀ ṣebẹwo sọdọ rẹ. Ni riri bi awọn Ẹlẹ́rìí Jehofa miiran ti ṣe ntọju rẹ̀ daradara, baba rẹ̀ ni a wu lori gidigidi ti o si sunkun nigba ti ko si ẹnikẹni nitosi. Laipẹ oun pẹlu bẹrẹ sii kẹkọọ Bibeli. Asẹhinwa asẹhinbọ awọn obi ọdọbinrin yii mejeeji gba iribọmi wọn si bẹrẹ sii ṣiṣẹsin Jehofa pẹlu iṣotitọ. Jehofa ko ha bukun Kristẹni obinrin yii lọpọlọpọ bi?

Adura Wọn Ni A Dahun

Iwọ ha ranti awọn ọrọ obinrin ti a mẹnukan ni ibẹrẹ ọrọ-ẹkọ ti iṣaaju? Oun kò tii nimọlara ti riri i ki a dahun awọn adura rẹ̀ rí. Sibẹ, o wá loye lẹhin naa pe Ọlọrun ndahun awọn adura rẹ̀. Obinrin naa ti pa akọsilẹ awọn koko adura rẹ̀ mọ́. Ni ọjọ kan o wo iwe akọsilẹ naa lọ gaaraga o si mọ daju pe Jehofa ti dahun ọpọjulọ ninu awọn adura rẹ̀, ani awọn wọnni ti oun funraarẹ ti gbagbe paapaa! Ó tipa bayii mọ pe Ọlọrun bikita fun oun o si ndahun awọn adura rẹ̀ lọna jẹlẹnkẹ ti o ṣanfaani fun un julọ.

Bi iwọ ba nimọlara pe awọn adura rẹ ni a kò dahun, beere lọwọ araarẹ pe: ‘Mo ha ni ipo ibatan ara ẹni pẹlu Jehofa, “Olugbọ adura” bi? Bi ko ba ri bẹẹ, mo ha ngbegbeesẹ lati kẹkọọ nipa rẹ̀ ki nsi di ọkan lara awọn iranṣẹ rẹ̀ ti a yà si mimọ?’ O ndahun adura awọn wọnni ti wọn nifẹẹ rẹ̀ ti wọn si nṣe ifẹ-inu rẹ̀. Wọn “duro gangan ninu adura” a si nfi ojurere gbọ wọn, gẹgẹ bii ti Jesu. (Roomu 12:12) Nitori naa, ‘tú ọkan rẹ jade’ si Jehofa ki o si ṣe ifẹ-inu rẹ̀. (Saamu 62:8) Nigba naa awọn adura rẹ ni a o gbọ.

Lonii, araadọta ọkẹ awọn eniyan ngbadura fun ohun akanṣe kan. Bẹẹni, awọn adura wọn ni a si ti ngbọ. Ẹ jẹ ki a wo idi ti a fi le ni idaniloju pe iru awọn adura bẹẹ ni a o dahun.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́