Ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀
Ṣé ìgbà kan wà tó o gbàdúrà, àmọ́ tó o rò pé Ọlọ́run ò gbọ́ àdúrà rẹ? Tó bá jẹ́ bẹ́ẹ̀, kì í ṣèwọ nìkan, ọ̀pọ̀ èèyàn náà ló nírú èrò yìí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ti gbàdúrà pé kí Ọlọ́run ran àwọn lọ́wọ́, síbẹ̀ ìṣòro wọn ò yanjú. Ìwé yìí sọ àwọn ohun tó máa jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run ń gbọ́ àdúrà wa. Ó tún sọ ìdí tí Ọlọ́run kì í fi dáhùn àwọn àdúrà kan àti bá a ṣe lè gbàdúrà tí Ọlọ́run á sì gbọ́ àdúrà wa.