Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2023 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MAY 8-14
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 20-21
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1271 ¶1-2
Jèhórámù
Jèhórámù ò tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rere Jèhóṣáfátì bàbá rẹ̀. Kí nìdí? Ọ̀kan lára ìdí náà ni pé Ataláyà ìyáwó rẹ̀ ní ipa búburú lórí rẹ̀. (2Ọb 8:18) Níbẹ̀rẹ̀, Jèhórámù pa àwọn àbúrò rẹ̀ mẹ́fẹ̀ẹ̀fà àti àwọn kan lára ìjòye Júdà. Yàtọ̀ síyẹn ó tún mú kí àwọn tó ń ṣàkóso lé lórí máa bọ òrìsà dípò kí wọ́n máa jọ́sìn Jèhófà. (2Kr 21:1-6, 11-14) Ní gbogbo ọdún tó fi ṣàkóso làwọn tó ń ṣàkóso lé lórí àti àwọn èèyàn láti ibòmíì ń fa wàhálà fún un. Lákọ̀ọ́kọ́, Édómù ṣọ̀tẹ̀ sí Júdà, lẹ́yìn ìyẹn Líbínà náà ṣọ̀tẹ̀ sí i. (2Ọb 8:20-22) Wòlíì Èlíjà kọ lẹ́tà kan sí Jèhórámù láti kìlọ̀ fún un pé: “Jèhófà yóò mú àjálù ńlá bá àwọn èèyàn rẹ, àwọn ọmọ rẹ, àwọn ìyàwó rẹ àti gbogbo ohun ìní rẹ.” Bákan náà, ó tún sọ fún Ọba Jèhórámù pé, “oríṣiríṣi àìsàn máa ṣe ọ́ pẹ̀lú àrùn tó máa mú ọ ní ìfun, títí àwọn ìfun rẹ á fi tú jáde nítorí àìsàn tí á máa ṣe ọ́ lójoojúmọ́.”—2Kr 21:12-15.
Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn. Jèhófà gbà kí àwọn Filísínì àti àwọn ará Arébíà fipá wọ ilẹ̀ náà, wọ́n sì kó àwọn ọmọ rẹ̀ àti àwọn ìyàwó rẹ̀ nígbèkùn. Ọlọ́run dá ẹ̀mí ọmọ ẹ̀ kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù sí, ìyẹn Jèhóáhásì àbíkẹ́yìn rẹ̀ (tó tún ń jẹ́ Ahasáyà). Torí májẹ̀mú Ìjọba tó bá Dáfìdì dá ló ṣe dá ẹ̀mí ọmọ náà sí. ‘Lẹ́yìn gbogbo èyí, Jèhófà fi àìsàn kan tí kò ṣeé wò sàn kọ lu [Jèhórámù] ní ìfun rẹ̀.’ Lẹ́yìn ọdún méjì, “ìfun rẹ̀ tú jáde” ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀ ó kú. Bí ọkùnrin burúkú yìí ṣe pàdánù ẹ̀mí ẹ̀ nìyẹn, ‘kò sì sẹ́ni tí ikú rẹ̀ dùn.’ Wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì, “àmọ́ kì í ṣe ní ibi tí wọ́n sin àwọn ọba sí.” Ahasáyà ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀.—2Kr 21:7, 16-20; 22:1; 1Kr 3:10, 11.
MAY 15-21
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 22-24
“Jèhófà Máa Ń San Àwọn Tó Bá Nígboyà Lẹ́san”
it-1 379 ¶5
Ìsìnkú, Àwọn Ibi Ìsìnkú
Torí pé Àlùfáà Àgbà Jèhóádà jẹ́ olódodo, nígbà tó kú “wọ́n sin ín sí Ìlú Dáfídì níbi tí wọ́n ń sin àwọn ọba sí,” òun nìkan lẹni tí kò wá láti ìlà ìdílé ọba tí wọ́n bọlá fún lọ́nà yẹn.—2Kr 24:15, 16.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 1223 ¶13
Sekaráyà
12. Ọmọ Àlùfáà Àgbà Jèhóádà. Lẹ́yìn ikú Jèhóádà, Ọba Jèhóáṣì fi ìjọsìn tòótọ́ sílẹ̀, dípò kó tẹ́tí sí àwọn wòlíì Jèhófà, ìmọ̀ràn tí ò dáa ló ń fetí sí. Sekaráyà, tó jẹ́ ìbátan Jèhóáṣì (2Kr 22:11) kìlọ̀ fáwọn èèyàn náà kíkankíkan lórí ọ̀rọ̀ yìí, àmọ́ kàkà kí wọ́n fetí sí i ṣe ní wọ́n sọ ọ́ lókùúta ní àgbàlá tẹ́ńpìlì. Bí Sekaráyà ṣe ń kú lọ, ó sọ pé: “Kí Jèhófà rí sí i, kí ó sì pè ọ́ wá jíhìn.” Ọ̀rọ̀ yìí sì rí bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́, torí àwọn ará Síríà ba ilẹ̀ Júdà jẹ́ gan-an, àwọn ìránṣẹ́ Jèhóáṣì méjì sì pa á “nítorí ó ti ta ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọ àlùfáà Jèhóádà sílẹ̀.” Bíbélì Septuagint ti èdè Gíríìkì àti Bíbélì Vulgate lédè Latin sọ pé wọ́n pa Jèhóáṣì láti gbẹ̀san ẹ̀jẹ̀ “ọmọ” Jèhóádà. Wọ́n lo ọ̀rọ̀ náà “àwọn ọmọ” nínú ọ̀rọ̀ táwọn Másórétì dà kọ àti Bíbélì Syriac Peshitta, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ àpọ́nlé ni ọ̀rọ̀ ẹlẹ́ni púpọ̀ yìí tí wọ́n fi pe Sekaráyà ọmọ Jèhóádà tó jẹ́ àlùfáà àti wòlíì.—2Kr 24:17-22, 25.
MAY 22-28
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 25-27
“Jèhófà Mọ Bó Ṣe Máa Fi Èyí Tó Pọ̀ Ju Bẹ́ẹ̀ San Án Fún Ọ”
it-1 1266 ¶6
Jèhóáṣì
Jèhóáṣì tún fi ọ̀kẹ́ márùn-ún jagunjagun rẹ̀ tó lákíkanjú háyà fún ọba Júdà, kí wọ́n lè fi bá àwọn ará Édómù jà. Àmọ́, ọba Júdà dá wọn padà torí “èèyàn Ọlọ́run tòótọ́” kan sọ pé kó ṣe bẹ́ẹ̀, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti fún wọn ní ọgọ́rùn-ún tálẹ́ńtì fàdákà (660,600 owó dọ́là) tẹ́lẹ̀. Inú bí wọn gidigidi sí Júdà, bí wọ́n ṣe dá wọn pa dà sílé torí wọn ò ní rí ìpín wọn gbà nínú owó náà bí wọ́n ṣe rò. Bí àwọn ọmọ ogun náà ṣe ń pa dà sí Àríwá, wọ́n kó ẹrù àwọn tó ń gbé ní gúúsù láti Samáríà títí dé Bẹti-hórónì.—2Kr 25:6-10, 13.
JUNE 5-11
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 30-31
“Ó Dáa Ká Máa Lọ Sípàdé”
it-1 1103 ¶2
Hẹsikáyà
Ó Ní Ìtara fún Ìjọsìn Tòótọ́. Ẹni ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (25) ni Hẹsikáyà nígbà tó dọba, bó ṣe gorí ìtẹ́ ló ti fi hàn pé òun ní ìtara fún ìjọsìn tòótọ́. Ohun tó kọ́kọ́ ṣe ni pe ó ṣí tẹ́ńpílì, ó sí ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ. Lẹ́yìn náà, ó pe àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì jọ, ó sọ fún wọn pé: “Ó jẹ́ ìfẹ́ ọkàn mi láti bá Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì dá májẹ̀mú.” Hẹsikáyà dá májẹ̀mú òdodo kó lè sọ májẹ̀mú Òfin dọ̀tun ní Júdà torí pé wọ́n ti pa májẹ̀mú Òfin tì bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ lásìkò yẹn. Ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ló ṣètò àwọn ọmọ Léfì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, ó sì ṣètò àwọn ohun èlò ìkọrin àti bí wọ́n á ṣe máa kọrin ìyìn. Ìgbà yẹn bọ́ sí oṣù Nísàn, ìyẹn oṣù tí wọ́n máa ń ṣe àjọyọ̀ Ìrékọjá, àmọ́ tẹ́ńpìlì, àwọn àlùfàá àti àwọn ọmọ Léfì ṣì jẹ́ aláìmọ́. Nígbà tó fi máa di ọjọ́ kẹrìndínlógún oṣù Nísàn, wọ́n ti sọ tẹ́ńpìlì àtàwọn ohun èlò tó wà nínú ẹ̀ di mímọ́. Lẹ́yìn náà, wọ́n rú ẹbọ tó ṣàrà ọ̀tọ̀ fún gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Lákọ̀kọ́, àwọn ìjòyè ìlú mú ẹbọ wá, ẹbọ ẹ̀ṣẹ̀ fún ìjọba náà àti fún ibi mímọ́ àti fún àwọn èèyàn náà. Ẹ̀yìn náà làwọn èèyàn náà mú ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹbọ sísun wá.—2Kr 29:1-36.
it-1 1103 ¶3
Hẹsikáyà
Àwọn èèyàn náà ò le ṣe àjọyọ̀ ìrékọjá lákòókò tó yẹ kí wọ́n ṣe é torí wọ́n jẹ́ aláìmọ́, Hẹsikáyà wá lo àǹfààní ohun tí òfin sọ pé àwọn tó jẹ́ aláìmọ́ lè ṣe àjọyọ̀ ìrékọjá lóṣù kan lẹ́yìn náà. Ó wá fi lẹ́tà pe gbogbo Ísírẹ́lì àti Júdà nípasẹ̀ àwọn asáréjíṣẹ́ láti Bíá-ṣébà dé Dánì. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn ló fi àwọn asáréjíṣẹ́ náà ṣe yẹ̀yẹ́; àmọ́ àwọn kan láti Áṣérì, Mánásè àti Sébúlúnì rẹ ara wọn sílẹ̀ wọ́n sì wá, kódà, àwọn kan láti Éfúrémù àti Ísákà wá síbi àjọyọ̀ náà. Bákan náà, ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì àmọ́ tí wọ́n jẹ́ olùjọsìn Jèhófà náà wá. Àmọ́, ó ṣeé ṣe kó má rọrùn fún àwọn olùjọ́sìn Jèhófà tó wà ní àríwá láti wá síbi àjọyọ̀ náà torí pé àwọn èèyàn lè máa ta kò wọ́n tàbí fi wọ́n ṣe yẹ̀yẹ́ bíi ti àwọn asáréjíṣẹ́ yẹn. Ohun míì tún ni pé ìjọsìn èké ló gbilẹ̀ ní Ìjọba ẹ̀yà mẹ́wàá náà, wọ́n sì tún lè kó sọ́wọ́ àwọn ará Ásíríà tó ń halẹ̀ mọ́ wọn.—.2Kr 30:1-20; Nọ 9:10-13.
it-1 1103 ¶4-5
Hẹsikáyà
Lẹ́yìn Àjọyọ̀ Ìrékọjá, wọ́n ṣe Àjọyọ̀ Búrẹ́dì Aláìwú fún ọjọ́ mẹ́rìnlá dípò ọjọ́ méje tó yẹ kí wọn fi ṣe é torí ìdùnnú tó kún ọkàn wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ewu ni wọ́n doju kọ lásìkò yẹn, ìbùkún Jèhófà ṣì jẹ́ kí “Ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní Jerúsálẹ́mù, torí pé láti ìgbà ayé Sólómọ́nì ọmọ Dáfídì ọba Ísírẹ́lì, irú èyí ò ṣẹlẹ̀ ní Jerúsálẹ́mù.”—2Kr 30:21-27.
Ohun tó ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn àjọyọ̀ náà jẹ́ ká rí i pé wọ́n ti dá ìjọsìn mímọ́ padà bọ̀ sípò. Bí àpẹẹrẹ, kí wọ́n tó padà sílé, àwọn èèyàn náà lọ sí àwọn ìlú, wọ́n gé àwọn òpó òrìṣà lulẹ̀, wọ́n sì wó àwọn ibi gíga àti àwọn pẹpẹ lulẹ̀ ní gbogbo Júdà àti Bẹ́ńjámínì pẹ̀lú Éfúrémù àti Mánásè. (2Kr 31:1) Hẹsikáyà fi àpẹẹrẹ tó dáa lé lẹ̀ nípa bó ṣe fọ́ ejò bàbà tí Mósè ṣe, torí àwọn èèyàn náà ti sọ ọ́ di òrìṣà, tí wọn sì ń mú ẹbọ rú èéfín sí i. (2Ọb 18:4) Lẹ́yìn àjọyọ̀ náà, Hẹsikáyà ṣe àwọn ohun táá jẹ́ kí ìjọsìn mímọ́ lè ma báa lọ. Ó yan ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn àlùfáà sẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wọn, ó fi àwọn nǹkan kan ṣètìlẹyìn kí iṣẹ́ tí wọ́n ń ṣe ní tẹ́ńpìlì lè rọrùn; bákan náà, ó rọ àwọn èèyàn láti máa mú ìdá mẹ́wàá àti àkọ́so irè oko wọn wá fún àwọn ọmọ Léfì àti àwọn àlùfáà bí Òfin ṣe sọ. Tọkàntọkàn làwọn èèyàn náà sì fi ṣe bẹ́ẹ̀.—2Kr 31:2-12.
JUNE 12-18
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 32-33
“Máa Fún Àwọn Míì Níṣìírí Nígbà Ìṣòro”
it-1 204 ¶5
Ásíríà
Senakérúbù. Senakérúbù, ọmọ Ságónì Kejì, gbéjà ko gbogbo ìlú Júdà ní ọdún kẹrìnlá ìṣàkóso Hẹsikáyà (732 Ṣ.S.K.). (2Ọb 18:13; Ais 36:1) Torí ohun tí Áhásì ṣe, abẹ́ ìṣàkóso Ásíríà ni Júdà wà, àmọ́ Hẹsikáyà ṣọ̀tẹ̀ sí wọn, ó sì kọ̀ láti sìn wọ́n. (2Ọb 18:7) Torí èyí, Senakérúbù wá gbógun ja àwọn ìlú Júdà, ó sì ṣẹ́gun àwọn ìlú mẹ́rìndínláàdọ́ta (46) (fi wé Ais 36:1, 2), lẹ́yìn náà láti Lákíṣì, ó ránṣẹ́ sí Hẹsikáyà pé kó fi ìṣàkọọ́lẹ̀ ọgbọ̀n tálẹ́ńtì wúrà (nǹkan bíi 11,560,000 owó dọ́là) àti ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) tálẹ́ńtì fàdákà ránṣẹ́ (nǹkan bíi 1,982,000 owó dọ́là). (2Ọb 18:14-16; 2Kr 32:1; fi wé Ais 8:5-8.) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Hẹsikáyà san owó náà, Senakérúbù ṣì rán àwọn ìránṣẹ́ ẹ̀ pé kí àwọn ará Jerúsálẹ́mù túúbá fún òun. (2Ọb 18:17–19:34; 2Kr 32:2-20) Bí Jèhófà ṣe pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án ó lé ẹgbẹ̀rún márùn-ún (185,000) àwọn ọmọ ogun Ásíríà mú kí ọba agbéraga yẹn fi ìtìjú pa dà sí ìlú Nínéfè. (2Ọb 19:35, 36) Bó ṣe dé Nínéfè àwọn ọmọ rẹ̀ fi idà pa á, Esari-hádónì ọmọ rẹ̀ sì jọba ní ipò rẹ̀. (2Ọb 19:37; 2Kr 32:21, 22; Ais 37:36-38) Gbogbo ìṣẹ̀lẹ̀ yìí ló wà lákọsílẹ̀ nínú wàláà Senakérúbù àti ọ̀kan lára ti Esari-hádónì, yàtọ̀ sí bí àwọn ọmọ ogun Ásíríà ṣe parun.—ÀWÒRÁN, Ìdìpọ̀ 1, ojú ìwé 957.
JUNE 19-25
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN | 2 KÍRÓNÍKÀ 34-36
“Ṣé Ò Ń Ṣiṣẹ́ Lórí Ohun Tí Ò Ń Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?”
it-1 1157 ¶4
Húlídà
Nígbà tí Jòsáyà gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ inú “ìwé Òfin náà” tí Hilikáyà àlùfáà àgbà rí nigbà tí wọ́n ń tún tẹ́ńpìlì ṣe, ó sọ pé kí wọ́n lọ wádìí lọ́dọ̀ Jèhófà. Wọ́n lọ sọ́dọ̀ Húlídà, ó sì sọ ọ̀rọ̀ Jèhófà fún wọ́n pé gbogbo àjálù tó wà nínú “ìwé” náà máa bá orílẹ̀-èdè apẹ̀yìndà yẹn tóri àìgbọnràn wọn. Húlídà tún sọ pé, torí Jòsáyà rẹ ara ẹ̀ sílẹ̀ níwájú Jèhófà, àjálù náà ò ní ṣẹlẹ̀ lójú ẹ̀, àmọ́ wọ́n máa kó o jọ sọ́dọ̀ àwọn baba ńlá rẹ̀, a sì máa tẹ́ ẹ sínú sàréè rẹ̀ ní àlàáfíà.—2Ọb 22:8-20; 2Kr 34:14-28.