APRIL 1-7
SÁÀMÙ 23-25
Orin 4 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. “Jèhófà Ni Olùṣọ́ Àgùntàn Mi”
(10 min.)
Jèhófà ń darí wa (Sm 23:1-3; w11 5/1 31 ¶3)
Jèhófà ń dáàbò bò wá (Sm 23:4; w11 5/1 31 ¶4)
Jèhófà ń bọ́ wa (Sm 23:5; w11 5/1 31 ¶5)
Bí olùṣọ́ àgùntàn onífẹ̀ẹ́ kan ṣe ń bójú tó àwọn àgùntàn rẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni Jèhófà ń bójú tó àwa ìránṣẹ́ rẹ̀.
BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn nǹkan wo ni Jèhófà ti ṣe fún mi tó mú kí n gbà pé ó ń bójú tó mi?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 23:3—Kí ni “ipa ọ̀nà òdodo,” kí la lè ṣe tá ò fi ní kúrò ní ipa ọ̀nà yìí? (w11 2/15 24 ¶1-3)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 23:1–24:10 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ẹni náà sọ pé inú òun ò dùn sí báwọn èèyàn ṣe ń ba àyíká jẹ́. Ka ẹsẹ Bíbélì kan táá fi í lókàn balẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fún ẹni tó gba ìwé Gbádùn Ayé Rẹ Títí Láé!—Ìbẹ̀rẹ̀ Ẹ̀kọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 14 kókó 4 (lmd ẹ̀kọ́ 11 kókó 3)
Orin 54
7. Má Ṣe Fetí sí Ohùn Àwọn Àjèjì
(15 min.) Ìjíròrò.
Àwọn àgùntàn mọ ohùn olùṣọ́ àgùntàn wọn, wọ́n sì máa ń tẹ̀ lé e. Àmọ́, wọ́n máa ń sá fún àjèjì torí wọn ò mọ ohùn rẹ̀. (Jo 10:5) Lọ́nà kan náà, a máa ń fetí sí ohùn àwọn Olùṣọ́ Àgùntàn wa, ìyẹn Jèhófà àti Jésù torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ wa, wọ́n sì ṣeé fọkàn tán. (Sm 23:1; Jo 10:11) Àmọ́, a kì í fetí sí ohùn àwọn àjèjì tí wọ́n lè fi “ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn” ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.—2Pe 2:1, 3.
Jẹ́nẹ́sísì orí kẹta jẹ́ ká mọ ìgbà àkọ́kọ́ tá a gbọ́ ohùn àjèjì láyé. Sátánì ò jẹ́ kí Éfà mọ irú ẹni tóun jẹ́ nígbà tó yọ sí i. Ó ṣe bí ọ̀rẹ́ sí Éfà, ó sì parọ́ fún un pé Jèhófà ò ní ire ẹ̀ lọ́kàn. Ó bani nínú jẹ́ pé Éfà tẹ́tí sí ohùn àjèjì yìí, èyí sì kóyà jẹ òun àtàwọn àtọmọdọ́mọ rẹ̀.
Lónìí, Ṣátánì máa ń mú káwọn èèyàn parọ́ tàbí kí wọ́n sọ ọ̀rọ̀ àìdáa nípa Jèhófà àti ètò rẹ̀, ká lè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì. Tá a bá gbọ́ ohùn àjèjì, kí ló yẹ ká ṣe? Ó yẹ ká sá tèfètèfè! Ó máa léwu gan-an tá a bá lọ tẹ́tí sí wọn kódà kó jẹ́ fún ìgbà díẹ̀ torí pé a fẹ́ ṣe ojúmìító. Ká rántí pé ìwọ̀nba ọ̀rọ̀ díẹ̀ ni Sátánì fi tan Éfà jẹ. (Jẹ 3:1, 4, 5) Àmọ́, tó bá jẹ́ pé ẹnì kan tá a mọ̀, tó nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì ní ire wa lọ́kàn ló fẹ́ sọ ohun tí ò dáa nípa ètò Ọlọ́run ńkọ́, kí la máa ṣe?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Yẹra fún “Ohùn Àwọn Àjèjì.” Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí lo kọ́ nínú ohun tí Jade ṣe nígbà tí ìyá rẹ̀ tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà fẹ́ sọ ohun tí ò dáa nípa ètò Ọlọ́run?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 8 ¶1-4, àwọn àpótí ojú ìwé 61-62