ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 March ojú ìwé 10-11
  • April 8-14

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • April 8-14
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 March ojú ìwé 10-11

APRIL 8-14

SÁÀMÙ 26-28

Orin 34 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Ọba Dáfídì ń gbàdúrà tọkàntọkàn.

1. Ohun Tí Dáfídì Ṣe Kó Lè Jẹ́ Olóòótọ́

(10 min.)

Dáfídì bẹ Jèhófà pé kó yọ́ òun mọ́ (Sm 26:1, 2; w04 12/1 14 ¶8-9)

Dáfídì ò bá àwọn èèyàn burúkú kẹ́gbẹ́ (Sm 26:4, 5; w04 12/1 15 ¶12-13)

Inú Dáfídì máa ń dùn láti jọ́sìn Jèhófà (Sm 26:8; w04 12/1 16 ¶17-18)

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì ṣe àwọn àṣìṣe kan, ọkàn tó tọ́ ló fi sin Jèhófà. (1Ọb 9:4) Ó hàn gbangba pé Dáfídì jẹ́ olóòótọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ó sì fi gbogbo ọkàn rẹ̀ sìn ín.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 27:10—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe lè tù wá nínú tí àwọn tó sún mọ́ wa bá pa wá tì? (w06 7/15 28 ¶15)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 27:1-14 (th ẹ̀kọ́ 2)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn ìwé kékeré tó wà nínú Àpótí Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́. (th ẹ̀kọ́ 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jíròrò ìbéèrè tó wà lẹ́yìn ìwé kékeré tó o fi sílẹ̀ nígbà tó o kọ́kọ́ wá. Tọ́ka sí ìkànnì jw.org tó wà níbẹ̀, kó o sì fi àwọn nǹkan tó wà lórí ìkànnì yẹn hàn án. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 3—Àkòrí: Kò Ní Sáwọn Nǹkan Tó Ń Ba Ayé Jẹ́ Mọ́, Ayé Máa Di Párádísè. (th ẹ̀kọ́ 13)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 128

7. Àwọn Ọ̀dọ́ Tó Kọ̀ Láti Ṣe Ìṣekúṣe

(15 min.) Ìjíròrò.

Ọ̀dọ́kùnrin kan ń ronú lórí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kà tán. Ó ń wo fídíò “Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi​—Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Kan Bá Fẹ́ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó?” lórí fóònù ńlá. Àwòrán bí Jósẹ́fù ṣe ń sá kúrò níwájú ìyàwó Pọ́tífárì wà lójú fóònú náà.

Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ Kristẹni gbọ́dọ̀ sapá kí wọ́n má bàa lọ́wọ́ sí ìṣekúṣe. Àwọn nǹkan kan sì wà tó máa ń jẹ́ kó ṣòro fún wọn láti pa ara wọn mọ́. Ọ̀kan lára ẹ̀ ni pé aláìpé ni gbogbo wa, ohun míì ni ìgbà ìtànná èwe tí wọ́n wà, ìyẹn àsìkò tí ìfẹ́ láti ní ìbálòpọ̀ máa ń lágbára gan-an, tó sì lè mú kí wọ́n ṣèpinnu tí kò tọ́. (Ro 7:21; 1Kọ 7:36) Kò mọ síbẹ̀ o, àwọn míì tún máa ń fúngun mọ́ wọn látìgbàdégbà pé kí wọ́n lọ́wọ́ nínú ìṣekúṣe, yálà láàárín ọkùnrin àti ọkùnrin tàbí obìnrin sí obìnrin, àmọ́ wọn kì í gbà. (Ef 2:2) Inú wa dùn gan-an pé àwọn ọ̀dọ́ wa pinnu láti jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi—Kí Ni Mo Lè Ṣe Táwọn Kan Bá Fẹ́ Kí N Ní Ìbálòpọ̀ Ṣáájú Ìgbéyàwó? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni àwọn ọmọ iléèwé Cory àti Kamryn fẹ́ kí wọ́n ṣe?

  • Kí ló mú kí wọ́n jẹ́ olóòótọ́?

  • Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ táwọn míì bá fẹ́ kó o ṣèṣekúṣe?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 8 ¶5-12

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 38 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́