ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 May ojú ìwé 4
  • May 13-19

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May 13-19
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 May ojú ìwé 4

MAY 13-19

SÁÀMÙ 38-39

Orin 125 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Máa Dá Ara Ẹ Lẹ́bi Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ

(10 min.)

Tá a bá ń dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, ṣe ló máa dà bí ìgbà tá a gbé ẹrù tó ju agbára wa lọ (Sm 38:3-8; w20.11 27 ¶12-13)

Dípò ká máa ronú ṣáá lórí àwọn àṣìṣe tá a ti ṣe sẹ́yìn, ṣe ló yẹ ká pinnu láti fi ayé wa sin Jèhófà (Sm 39:4, 5; w02 11/15 20 ¶1-2)

Máa gbàdúrà kódà bí ẹ̀rí ọkàn tó ń dá ẹ lẹ́bi bá mú kó ṣòro fún ẹ láti ṣe bẹ́ẹ̀ (Sm 39:12; w21.10 15 ¶4)

Àwòrán: 1. Arákùnrin kan gbé ẹrù tó wúwo, àmọ́ kò rọrùn fún un. 2. Arákùnrin náà ti gbé ẹrù yẹn sílẹ̀, ara tù ú, ọkàn ẹ̀ sì balẹ̀.

Tó bá jẹ́ pé gbogbo ìgbà ni ọkàn ẹ máa ń dá ẹ lẹ́bi, fi sọ́kàn pé Jèhófà máa ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ tó bá ronú pìwà dà ní “fàlàlà.”—Ais 55:7.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 39:1—Àwọn ìgbà wo ló máa pọn dandan pé ká “fi ìbonu bo ẹnu” wa? (w22.09 13 ¶16)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 38:1-22 (th ẹ̀kọ́ 2)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀—Ohun Tí Pọ́ọ̀lù Ṣe

(7 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà, kẹ́ ẹ sì jíròrò lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 1-2.

5. Máa Fọgbọ́n Bá Àwọn Èèyàn Sọ̀rọ̀ —Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù

(8 min.) Ìjíròrò tó dá lórí lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3-5 àti “Tún Wo.”

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 44

6. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ

(15 min.)

7. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 9 ¶17-24, àpótí ojú ìwé 73

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 84 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́