ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 May ojú ìwé 5-16
  • May 20-26

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May 20-26
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 May ojú ìwé 5-16

MAY 20-26

SÁÀMÙ 40-41

Orin 102 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́?

(10 min.)

A máa láyọ̀ tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ (Sm 41:1; w18.08 22 ¶16-18)

Jèhófà máa ràn wá lọ́wọ́ tá a bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́ (Sm 41:2-4; w15 12/15 24 ¶7)

À ń fi ìyìn fún Jèhófà tá a bá ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ (Sm 41:13; Owe 14:31; w17.09 12 ¶17)

Arábìnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń kọ́ arábìnrin àgbàlagbà kan bó ṣe máa lo fóònù rẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ẹnì kan wà nínú ìjọ tí kò mọ bí wọ́n ṣe ń lo JW Library tí mo lè ràn lọ́wọ́?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 40:5-10—Bó ṣe wà nínú ẹsẹ Bíbélì yìí, kí ló yẹ ká ṣe tá a bá gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ? (it-2 16)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 40:1-17 (th ẹ̀kọ́ 12)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tí inú ẹ̀ ń dùn. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Bẹ̀rẹ̀ ìjíròrò pẹ̀lú ẹnì kan tí ojú ẹ̀ kọ́rẹ́ lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 14 kókó 6. Jíròrò kókó kan látinú àpilẹ̀kọ náà “Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ” tó wà ní apá “Ṣèwádìí” pẹ̀lú akẹ́kọ̀ọ́ kan tí kì í fẹ́ dáhùn nípàdé. (th ẹ̀kọ́ 19)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 138

7. Máa Ran Àwọn Àgbàlagbà Lọ́wọ́

(15 min.) Ìjíròrò.

Jèhófà mọyì gbogbo iṣẹ́ táwọn àgbàlagbà tó jẹ́ olóòótọ́ nínú ìjọ ń ṣe, àwa náà sì mọyì wọn. (Heb 6:10) Ọjọ́ pẹ́ tí wọ́n ti ń dá àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin lẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì ń fún wọn níṣìírí. Ó dájú pé ìwọ náà á rántí àwọn ìgbà tí wọ́n ti ràn ẹ́ lọ́wọ́. Báwo lo ṣe lè fi hàn pé o mọrírì gbogbo ohun tí wọ́n ti ṣe sẹ́yìn, àti ohun tí wọ́n ń ṣe báyìí nínú ìjọ?

Apá kan nínú fídíò ‘Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣe Rere fún Àwọn Ará Wa.’ Àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ń bá Arákùnrin Ho-jin Kang tún ilé ẹ̀ ṣe.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ ‘Ẹ Jẹ́ Ká Máa Ṣe Rere fún Àwọn Ará Wa.’ Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni Ji-Hoon kọ́ lọ́dọ̀ Arákùnrin Ho-jin Kang?

  • Kí ló wù ẹ́ jù lára àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ rẹ?

  • Kí la rí kọ́ nínú àpèjúwe ará Samáríà tó jẹ́ aládùúgbò rere?

  • Kí nìdí tó o fi gbà pé ó dáa bí Ji-Hoon ṣe mú àwọn míì dání nígbà tó fẹ́ lọ ran Arákùnrin Ho-jin Kang lọ́wọ́?

Tá a bá ronú jinlẹ̀ nípa ohun táwọn àgbàlagbà tó wà ní ìjọ wa nílò, a máa rí i pé onírúurú nǹkan la lè ṣe fún wọn. Tá a bá sì kíyè sí i pé wọ́n nílò nǹkan kan, ó yẹ ká ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.—Jem 2:15, 16.

Ka Gálátíà 6:10. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn ọ̀nà wo lo lè gbà “máa ṣe rere fún” àwọn àgbàlagbà tó wà níjọ rẹ?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 10 ¶1-4, àpótí ojú ìwé 79

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 8 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́