ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 May ojú ìwé 6-7
  • May 27–June 2

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May 27–June 2
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 May ojú ìwé 6-7

MAY 27–JUNE 2

SÁÀMÙ 42-44

Orin 86 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Máa Fi Ohun Tí Jèhófà Ń Kọ́ Wa Sílò

(10 min.)

Máa jọ́sìn Jèhófà pẹ̀lú àwọn ará lójúkojú tó bá ti lè ṣeé ṣe tó (Sm 42:4, 5; w06 6/1 9 ¶4)

Kọ́kọ́ gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì (Sm 42:8; w12 1/15 15 ¶2)

Máa tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Bíbélì nínú gbogbo ohun tó o bá ń ṣe (Sm 43:3)

Àwọn arábìnrin ń fetí sílẹ̀ ní àpéjọ agbègbè.

Ohun tí Jèhófà ń kọ́ wa máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa, ká sì dúró lórí ìpinnu tá a ṣe nígbà tá a ya ara wa sí mímọ́ fún Jèhófà.—1Pe 5:10; w16.09 5 ¶11-12.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 44:19—Kí ló ṣeé ṣe kí onísáàmù náà ní lọ́kàn nígbà tó lo ọ̀rọ̀ náà “níbi tí àwọn ajáko ń gbé”? (it-1 1242)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 44:1-26 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Pe ẹni náà wá sí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀ (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 5)

6. Àsọyé

(3 min.) lmd àfikún A kókó 4—Àkòrí: Ara Gbogbo Èèyàn Máa Jí Pépé. (th ẹ̀kọ́ 2)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 21

7. Bó O Ṣe Lè Ṣèpinnu Tó Dáa Tó Bá Dọ̀rọ̀ Iṣẹ́ àti Ilé Ẹ̀kọ́

(15 min.) Ìjíròrò.

Àwòrán: Arákùnrin kan tó jẹ́ ọ̀dọ́ ń ka Bíbélì, ó sì ń ronú lórí ohun tó máa ṣe tó bá jáde ilé ìwé. 1. Ó ń bá ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ wọn sọ̀rọ̀. 2. Ó lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Ajíhìnrere Ìjọba Ọlọ́run. 3. Ó ń wàásù ní orílẹ̀-èdè míì.

Ẹ̀yin ọ̀dọ́, ṣé ẹ ti ń ronú ohun tẹ́ ẹ máa ṣe tẹ́ ẹ bá parí ilé ìwé? Ó ṣeé ṣe kó o ti ní iṣẹ́ kan lọ́kàn tó máa jẹ́ kó o lè ráyè ṣe aṣáájú-ọ̀nà. Ó sì ṣeé ṣe kó o ti máa ronú irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti kọ́, tàbí àfikún ẹ̀kọ́ tó o lè gbà tí wọ́n á sì fún ẹ ní ìwé ẹ̀rí tó o fi máa rí irú iṣẹ́ tó wù ẹ́ láti ṣe. Ká sòótọ́, inú ẹ lè máa dùn bó o ṣe ń fojú sọ́nà fún àkókò yẹn. Àmọ́ nígbà míì, kì í rọrùn láti ṣèpinnu, àwọn èèyàn sì lè máa rọ̀ ẹ́ lọ́tùn-ún lósì pé kó o yan ohun tí wọ́n ronú pé ó dáa jù fún ẹ. Kí lá jẹ́ kó o ṣèpinnu tó dáa?

Ka Mátíù 6:32, 33. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o kọ́kọ́ pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kó o tó yan irú iṣẹ́ tó o máa ṣe tàbí tó o máa kọ́?

  • Báwo làwọn òbí ṣe lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti fi ìmọ̀ràn inú Mátíù 6:32, 33 sílò?—Sm 78:4-7

Ṣọ́ra kó má lọ jẹ́ torí àti ríṣẹ́ táá máa mówó ńlá wọlé tàbí torí àtidi gbajúmọ̀ lo fi máa pinnu ohun tó o fẹ́ ṣe. (1Jo 2:15, 17) Má gbàgbé pé, téèyàn bá lówó rẹpẹtẹ, ìyẹn lè mú kó ṣòro fún un láti fi Ìjọba Ọlọ́run sípò àkọ́kọ́. (Lk 18:24-27) Tẹ́nì kan bá ń lé bó ṣe máa di olówó, á ṣòro fún un láti pọkàn pọ̀ sórí ìjọsìn Jèhófà, kó sì tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí.—Mt 6:24; Mk 8:36.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Má Ṣe Gbọ́kàn Lé Àwọn Nǹkan Tó Máa Dópin!—Ọrọ̀. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí ni Òwe 23:4, 5 sọ táá jẹ́ kó o lè ṣèpinnu tó dáa?

ÌMỌ̀RÀN

  • Ní àwọn àfojúsùn tí ọwọ́ ẹ lè tètè tẹ̀ àti èyí tó máa ṣe díẹ̀ kọ́wọ́ ẹ tó tẹ̀

  • Rí i dájú pé ẹ̀kọ́ tó o fẹ́ gbà tàbí iṣẹ́ tó o bá yàn láti kọ́ kò ní dí ẹ lọ́wọ́ láti lé àwọn àfojúsùn rẹ bá

  • Yan ohun tó máa wúlò, kó o sì ṣe tán láti ṣe ìyípadà tó bá yẹ. Tó o bá pinnu pé o fẹ́ kọ́ iṣẹ́ kan tàbí o fẹ́ kàwé sí i, rí i dájú pé ohun tó máa wúlò táá sì jẹ́ kó o rí iṣẹ́ tó o lè fi gbọ́ bùkátà ẹ lo yàn

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 10 ¶5-12

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 47 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́