JUNE 3-9
SÁÀMÙ 45-47
Orin 27 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
Jésù Kristi àti ìyàwó ẹ̀, ìyẹn àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì
1. Orin Ìgbéyàwó Ọba Kan
(10 min.)
Ìgbéyàwó Mèsáyà Ọba ni Sáàmù 45 dá lé (Sm 45:1, 13, 14; w14 2/15 9-10 ¶8-9)
Ìgbéyàwó Ọba náà máa wáyé lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì (Sm 45:3, 4; w22.05 17 ¶10-12; wo àwòrán iwájú ìwé)
Gbogbo èèyàn pátá ni ìgbéyàwó yìí máa ṣe láǹfààní (Sm 46:8-11; it-2 1169)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé ó máa ń wù mí láti wàásù ìhìn rere nípa Jésù Kristi Ọba wa?’—Sm 45:1.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 45:16—Báwo ni ẹsẹ Bíbélì yìí ṣe jẹ́ ká mọ bí ìgbésí ayé ṣe máa rí nínú Párádísè? (w17.04 11 ¶9)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 45:1-17 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)
5. Àsọyé
(5 min.) ijwbv 26—Àkòrí: Kí Ni Ìtumọ̀ Sáàmù 46:10? (th ẹ̀kọ́ 18)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(4 min.) Àṣefihàn. g 1/11 22-23—Àkòrí: Kí Lèrò Ẹ Nípa Ìbẹ́yà-Kan-Náà-Lòpọ̀? (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 5)
Orin 131
7. Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín
(10 min.) Ìjíròrò.
Ọjọ́ ayọ̀ lọjọ́ ìgbéyàwó máa ń jẹ́. (Sm 45:13-15) Ṣe ni inú ọkọ àti ìyàwó máa ń dùn ṣìnkìn lọ́jọ́ yẹn. Àmọ́, kí ni tọkọtaya lè ṣe tí ayọ̀ náà á fi bá wọn kalẹ́?—Onw 9:9.
Wọ́n máa láyọ̀ tí wọ́n bá ń fìfẹ́ hàn síra wọn. Àwọn tọkọtaya lè fara wé àpẹẹrẹ Ísákì àti Rèbékà. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé, kódà lẹ́yìn ọgbọ̀n (30) ọdún tí wọ́n ti ṣègbéyàwó, wọ́n ṣì ń fìfẹ́ tó dénú hàn síra wọn. (Jẹ 26:8) Kí làwọn tọkọtaya lè ṣe káwọn náà lè máa fìfẹ́ hàn síra wọn?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Tọkọtaya Aláyọ̀: Ẹ Máa Fìfẹ́ Hàn Síra Yín. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí ló lè mú kí tọkọtaya má nífẹ̀ẹ́ ara wọn bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́?
Kí ni tọkọtaya lè máa ṣe táá fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn, wọ́n sì ń bọ̀wọ̀ fúnra wọn?—Iṣe 20:35
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(5 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 10 ¶13-21