JUNE 24-30
SÁÀMÙ 54-56
Orin 48 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ọlọ́run Ò Ní Fi Ẹ́ Sílẹ̀
(10 min.)
Gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà bíi ti Dáfídì tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́ (Sm 56:1-4; w06 8/1 22 ¶10-11)
Jèhófà mọyì bó o ṣe ń fara dà á, ó sì máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ (Sm 56:8; cl 243 ¶9)
Jèhófà ò ní fi ẹ́ sílẹ̀. Kò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun ba àjọṣe tó o ní pẹ̀lú rẹ̀ jẹ́ (Sm 56:9-13; Ro 8:36-39; w22.06 18 ¶16-17)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sm 55:12, 13—Ṣé Jèhófà ló kádàrá Júdásì pé kó da Jésù? (it-1 857-858)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 55:1-23 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ṣàlàyé bá a ṣe máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o sì fún ẹni náà ní káàdì ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. (th ẹ̀kọ́ 11)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
6. Àsọyé
(5 min.) w23.01 29-30 ¶12-14—Àkòrí: Ìfẹ́ Tá A Ní fún Kristi Ń Mú Ká Nígboyà. Wo àwòrán. (th ẹ̀kọ́ 9)
Orin “Jẹ́ Kí N Ní Ìgboyà” (èyí tó lọ́rọ̀ orin)
7. A Lè Láyọ̀ Bá A Tiẹ̀ Ń Dojú Kọ . . . Idà
(5 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí lo rí kọ́ nínú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Arákùnrin Dugbe tó lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ tí ẹ̀rù bá ń bà ẹ́?
8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù June
(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 11 ¶11-19