JUNE 17-23
SÁÀMÙ 51-53
Orin 89 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Fi Ní Dẹ́ṣẹ̀ Tó Burú Jáì
(10 min.)
Má ṣe dá ara rẹ lójú jù torí kò sẹ́ni tí ò lè ṣàṣìṣe (Sm 51:5; 2Kọ 11:3)
Máa ṣe ohun táá mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà (Sm 51:6; w19.01 15 ¶4-5)
Má ṣe fàyè gba èròkerò àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ lọ́kàn rẹ (Sm 51:10-12; w15 6/15 14 ¶5-6)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sm 51:1-19 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
6. Pa Dà Lọ
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ orúkọ Ọlọ́run. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
7. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
Orin 115
8. Ohun Tó O Lè Ṣe Tó O Bá Ṣàṣìṣe
(15 min.) Ìjíròrò.
Kò sí bá a ṣe lè ṣe é tá ò fi ní ṣàṣìṣe, ó ṣe tán wọ́n máa ń sọ pé a kì í mọ̀-ọ́n-rìn, kí orí má mì. (1Jo 1:8) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a ò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìtìjú tàbí ìbẹ̀rù ohun tó lè ṣẹlẹ̀ mú ká fà sẹ́yìn láti ṣe ohun tó tọ́. Ó yẹ ká bẹ Jèhófà pé kó dárí jì wá kó sì ràn wá lọ́wọ́. (1Jo 1:9) Ohun àkọ́kọ́ tó yẹ ká ṣe nígbàkigbà tá a bá ṣàṣìṣe ni pé ká gbàdúrà sí Jèhófà.
Ka Sáàmù 51:1, 2, 17. Lẹ́yìn náà béèrè pé:
Báwo lohun tí Dáfídì sọ yìí ṣe jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà ló yẹ ká yíjú sí tá a bá ṣàṣìṣe tó lágbára?
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ìgbà Ọ̀dọ́ Mi—Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàtúnṣe? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Àwọn nǹkan wo ló mú kí Thalila àti José ṣàṣìṣe?
Àwọn nǹkan wo ni wọ́n ṣe kí wọ́n lè ṣàtúnṣe?
Àǹfààní wo ni wọ́n rí nígbà tí wọ́n ṣe ohun tó yẹ?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 11 ¶5-10, àpótí ojú ìwé 89