Àwọn Ìtẹ̀jáde Tá A Tọ́ka sí Nínú Ìwé Ìpàdé Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni
© 2024 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
MAY 6-12
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 36-37
“Má Banú Jẹ́ Nítorí Àwọn Ẹni Burúkú”
Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?
4 Kí làwọn èèyàn burúkú ń ṣe fún wa báyìí? Lẹ́yìn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé ọjọ́ ìkẹyìn yìí máa jẹ́ “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò,” ó tún sọ pé: “Àwọn ènìyàn burúkú àti àwọn afàwọ̀rajà yóò máa tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù.” (2 Tím. 3:1-5, 13) Ǹjẹ́ o mọ̀ pé àwọn nǹkan yìí ti ń ṣẹlẹ̀? Ọ̀pọ̀ lára wa làwọn ìpáǹle, àwọn alákatakítí, àtàwọn jàǹdùkú ti hàn léèmọ̀. Àwọn kan ò fi tiwọn bò, afàwọ̀rajà sì làwọn míì, wọ́n á máa ṣe bí ẹni pé èèyàn rere làwọn, síbẹ̀ ìwà ibi ló kún ọwọ́ wọn. Ká tiẹ̀ ní wọn ò hàn wá léèmọ̀ rí, ìwà ibi wọn ṣì kàn wá. Kò sẹ́ni tínú rẹ̀ kì í bà jẹ́ tó bá gbọ́ nípa ìwà ibi táwọn èèyàn náà ń hù. Ṣé bí wọ́n ṣe ń fojú pọ́n àwọn ọmọdé ni ká sọ ni, tàbí bí wọ́n ṣe ń fojú àwọn àgbàlagbà gbolẹ̀ àtàwọn tí kò ní olùgbèjà? Ìwà táwọn èèyàn burúkú yẹn ń hù kò jọ tèèyàn, ṣe ló dà bíi ti ẹranko àti tàwọn ẹ̀mí èṣù. (Ják. 3:15) Àmọ́, inú wa dùn pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé nǹkan máa tó yí pa dà.
Jèhófà Máa Ń Bù Kún Àwọn Tó Bá Ń Dárí Jini
10 Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó máa pa wá lára. Tá a bá di ẹnì kan sínú, ṣe ló dà bí ìgbà tá a di ẹrù kan tó wúwo lé ara wa lórí. Jèhófà ò sì fẹ́ kírú ẹ̀ ṣẹlẹ̀ sí wa. (Ka Éfésù 4:31, 32.) Ó gbà wá níyànjú pé ká “fi ìbínú sílẹ̀, kí [a] sì pa ìrunú tì.” (Sm. 37:8) Tá a bá tẹ̀ lé ìmọ̀ràn yìí, ó máa fi hàn pé ọlọ́gbọ́n ni wá. Tá a bá ń di àwọn èèyàn sínú, ó lè ṣàkóbá fún ìlera wa. (Òwe 14:30) Bí àpẹẹrẹ, tá a bá mu omi tó ní májèlé, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹlòmíì. Bẹ́ẹ̀ náà ló ṣe jẹ́ pé tá a bá di ẹnì kan sínú, àwa ló máa pa lára kì í ṣe ẹni tó múnú bí wa. Torí náà, tá a bá dárí ji ẹni tó ṣẹ̀ wá, ara wa là ń ṣe láǹfààní. (Òwe 11:17) Ọkàn wa máa balẹ̀, á sì rọrùn fún wa láti máa jọ́sìn Jèhófà nìṣó.
“Máa Ní Inú Dídùn Kíkọyọyọ Nínú Jèhófà”
20 Nígbà náà, “ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé.” (Sáàmù 37:11a) Ṣùgbọ́n àwọn wo làwọn “ọlọ́kàn tútù” yìí? Nínú èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀ tá a fi kọ Bíbélì, ọ̀rọ̀ tí a tú sí “ọkàn tútù,” wá látinú ọ̀rọ̀ kan tó túmọ̀ sí “pọ́n lójú, láti rẹ̀ sílẹ̀, láti tẹ́ lógo.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn “ọlọ́kàn tútù” ni àwọn tó fi ìrẹ̀lẹ̀ dúró de Jèhófà kí ó wá rí sí gbogbo ìwà ìrẹ́jẹ táráyé hù sí wọn. “Ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:11b) Nísinsìnyí pàápàá, à ń rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà nínú párádísè tẹ̀mí tó wà nínú ìjọ Kristẹni tòótọ́.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 445
Òkè
Ó dúró sán-ún, ó fìdí múlẹ̀, tàbí ó ga fíofío. Ohun tá a mọ̀ nípa àwọn òkè ńlá ni pé, wọ́n máa ń dúró sán-ún, wọ́n sì máa ń fìdí múlẹ̀. (Ais 54:10; Hab 3:6; fi wé Sm 46:2.) Torí náà, nígbà tí onísáàmù náà sọ pé òdodo Jèhófà dà bí “àwọn òkè ńlá Ọlọ́run” (Sm 36:6) ohun tó ṣeé ṣe kó ní lọ́kàn ni pé òdodo Jèhófà dúró sán-ún, kò sì ní yí pa dà láé. Tàbí kó jẹ́ pé ó ń fi òdodo Jèhófà wé òkè tó ga fíofío, ní ti pé bí òkè ṣe máa ń ga, bẹ́ẹ̀ náà ni òdodo Jèhófà ga fíìfíì ju tèèyàn lọ. (Fi wé Ais 55:8, 9.) Nígbà tí Ìfihàn 16:20 ń sọ nípa abọ́ kéje ti ìbínú Ọlọ́run tí wọ́n dà sórí ayé, ó sọ pé: “A ò sì rí àwọn òkè.” Èyí fi hàn pé kò sí ohunkóhun títí kan àwọn ohun tó ga bí òkè tó máa bọ́ lọ́wọ́ ìbínú Jèhófà.—Fi wé Jer 4:23-26.
MAY 13-19
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 38-39
Má Ṣe Máa Dá Ara Ẹ Lẹ́bi Ju Bó Ṣe Yẹ Lọ
Ọjọ́ Iwájú Ni Kó O Tẹjú Mọ́
12 Ka 1 Jòhánù 3:19, 20. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, gbogbo wa la máa ń dá ara wa lẹ́bi. Bí àpẹẹrẹ, àwọn kan lè máa dá ara wọn lẹ́bi nítorí àwọn nǹkan tí wọ́n ṣe kí wọ́n tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn míì sì máa ń dá ara wọn lẹ́bi nítorí àṣìṣe tí wọ́n ṣe lẹ́yìn ìrìbọmi. (Róòmù 3:23) Òótọ́ ni pé a máa ń fẹ́ ṣe ohun tó tọ́, àmọ́ “gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà.” (Jém. 3:2; Róòmù 7:21-23) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa kì í dùn tá a bá ń dára wa lẹ́bi, ó láǹfààní tiẹ̀. Kí nìdí? Ìdí ni pé tí ọkàn wa bá ń dá wa lẹ́bi, ó lè mú ká ṣàtúnṣe sí ìwà kan tá a hù, á sì mú ká pinnu pé a ò ní ṣe irú ẹ̀ mọ́.—Héb. 12:12, 13.
13 Lọ́wọ́ kejì, ẹnì kan lè máa dára ẹ̀ lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ, lédè míì kó máa dára ẹ̀ lẹ́bi lẹ́yìn tó ti ronú pìwà dà, tí Jèhófà sì ti jẹ́ kó dá a lójú pé òun dárí jì í. Irú èrò bẹ́ẹ̀ léwu gan-an. (Sm. 31:10; 38:3, 4) Kí nìdí? Ẹ jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ arábìnrin kan tó ń dára ẹ̀ lẹ́bi ṣáá nítorí ẹ̀ṣẹ̀ tó ti dá sẹ́yìn. Ó sọ pé: “Mo ronú pé kò sídìí tó fi yẹ kí n máa lo ara mi dé góńgó lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Ó ṣe tán, kò sí bí mo ṣe ṣe tó, tí màá rí ojúure Jèhófà.” Ọ̀pọ̀ wa náà ti lè ronú bẹ́ẹ̀ rí. Àmọ́ kò yẹ ká máa dá ara wa lẹ́bi ju bó ṣe yẹ lọ. Kí nìdí? Ìdí ni pé inú Sátánì máa dùn tá a bá rẹ̀wẹ̀sì tá a sì dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà ṣì nífẹ̀ẹ́ wa, ó sì ti dárí jì wá!—Fi wé 2 Kọ́ríńtì 2:5-7, 11.
Báwo La Ṣe Lè Lo Ìgbésí Ayé Wa Lọ́nà Tí Inú Jèhófà Dùn Sí?
Ó DÀ bíi pé ọjọ́ ayé wa kò tó nǹkan, ká sì tó pajú pẹ́ ó ti kọjá lọ. Onísáàmù náà Dáfídì ronú nípa bí ìgbésí ayé èèyàn ṣe kúrú tó, ó sì gbàdúrà pé: “Jèhófà, jẹ́ kí n mọ òpin mi, àti ìwọ̀n ọjọ́ mi—ohun tí ó jẹ́, kí n lè mọ bí mo ti jẹ́ aláìwàpẹ́ tó. Wò ó! Ìwọ ti ṣe ọjọ́ mi ní kìkì ìwọ̀nba díẹ̀; gbogbo ọjọ́ ayé mi sì dà bí èyí tí kò tó nǹkan ní iwájú rẹ.” Ohun tó wà lórí ẹ̀mí Dáfídì ni pé kó gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tá á múnú Ọlọ́run dùn, yálà nípa ọ̀rọ̀ sísọ tàbí ìṣe rẹ̀. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bó ṣe gbára lé Ọlọ́run, ó ní: “Ìfojúsọ́nà mi ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ.” (Sáàmù 39:4, 5, 7) Jèhófà gbọ́ àdúrà rẹ̀. Ó yẹ gbogbo ìgbòkègbodò Dáfídì wò lóòótọ́, ó sì pín in lérè níbàámu pẹ̀lú iṣẹ́ rẹ̀.
Ó rọrùn kí ọwọ́ èèyàn dí láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ kí ìgbésí ayé olúwarẹ̀ sì di ti kòókòó jàn-ánjàn-án pẹ̀lú ìgbòkègbodò tó pọ̀ rẹpẹtẹ. Èyí lè mú ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn, àgàgà bí ohun tá a fẹ́ ṣe bá pọ̀ tí àkókò wa ò sì tó nǹkan. Ṣé ohun tó jẹ Dáfídì lógún náà jẹ wá lógún, ìyẹn láti gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó ṣètẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run? Ó dájú pé Jèhófà ń kíyè sí kálukú wa ó sì ń yẹ̀ wá wò. Jóòbù tó bẹ̀rù Ọlọ́run sọ ní nǹkan bí egbèjìdínlógún [3,600] ọdún sẹ́yìn pé Jèhófà rí gbogbo ọ̀nà òun ó sì ń ka gbogbo ìṣísẹ̀ òun. Jóòbù béèrè lọ́wọ́ ara rẹ̀ pé: “Nígbà tí ó bá sì béèrè fún ìjíhìn, kí ni mo lè fi dá a lóhùn?” (Jóòbù 31:4-6, 14) A lè lo ìgbésí ayé wa lọ́nà táá múnú Ọlọ́run dùn tá a bá ṣètò bá ó ṣe máa fi àwọn ohun tẹ̀mí ṣáájú, ká máa pa àṣẹ Ọlọ́run mọ́ ká sì máa lo àkókò wa lọ́nà tó bọ́gbọ́n mu. Ẹ jẹ́ ká túbọ̀ túṣu ọ̀ràn yìí désàlẹ̀ ìkòkò.
Jẹ́ Kí Àjọṣe Ìwọ àti Jèhófà Pa Dà Gún Régé
Máa gbàdúrà sí Jèhófà déédéé. Bàbá rẹ ọ̀run mọ̀ pé bí ẹ̀rí ọkàn ẹ ṣe ń dá ẹ lẹ́bi lè mú kó má rọrùn fún ẹ láti gbàdúrà sí òun. (Róòmù 8:26) Síbẹ̀, “máa tẹra mọ́ àdúrà gbígbà,” kó o sì jẹ́ kí Jèhófà mọ̀ pé o fẹ́ kí àjọṣe ìwọ àti òun pa dà gún régé. (Róòmù 12:12) Bí àpẹẹrẹ, Arákùnrin Andrej rántí bọ́rọ̀ ṣe rí lára òun. Ó ní: “Ojú tì mí gan-an, mo sì ń dá ara mi lẹ́bi ṣáá. Àmọ́ gbogbo ìgbà tí mo bá ti gbàdúrà lọkàn mi máa ń balẹ̀, tára sì máa ń tù mí pẹ̀sẹ̀.” Tó ò bá mọ ohun tó o máa sọ nínú àdúrà, wo àdúrà ìrònúpìwàdà tí Ọba Dáfídì gbà nínú Sáàmù 51 àti 65.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Máa Ṣohun Táá Jẹ́ Káwọn Èèyàn Fọkàn Tán Ẹ
16 Máa kó ara ẹ níjàánu. Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu. Tá a bá fi kókó yìí sọ́kàn, á jẹ́ ká lè máa pa ọ̀rọ̀ àṣírí tẹ́nì kan sọ fún wa mọ́. (Ka Òwe 10:19.) Ó lè ṣòro fún wa láti kó ara wa níjàánu nígbà tá a bá ń lo ìkànnì àjọlò. Tá ò bá ṣọ́ra, a lè sọ̀rọ̀ àṣírí kan fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ èèyàn lórí ìkànnì láì mọ̀ọ́mọ̀. Táwọn èèyàn bá sì ti mọ ọ̀rọ̀ àṣírí náà, a ò mọ ohun tí wọ́n lè fi ṣe àti jàǹbá tó lè fà. Bákan náà, táwọn alátakò bá ń dọ́gbọ́n tó máa mú ká sọ̀rọ̀ àṣírí tó máa ṣàkóbá fáwọn ará, ó yẹ ká kó ara wa níjàánu, ká má sì sọ nǹkan kan. Bí àpẹẹrẹ, irú nǹkan bẹ́ẹ̀ lè ṣẹlẹ̀ táwọn ọlọ́pàá bá ń fọ̀rọ̀ wá wa lẹ́nu wò láwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ wa tàbí tí wọ́n ti ń dí iṣẹ́ wa lọ́wọ́. Tá a bá bá ara wa nírú ipò yìí àti láwọn ipò míì, a lè lo ìlànà Bíbélì tó sọ pé ká “fi ìbonu bo ẹnu” wa. (Sm. 39:1) Ó yẹ ká máa ṣe ohun táá jẹ́ kí gbogbo èèyàn fọkàn tán wa, títí kan àwọn ìdílé wa, àwọn ọ̀rẹ́ wa, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa tàbí àwọn ẹlòmíì. Torí náà, tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn fọkàn tán wa, a gbọ́dọ̀ máa kó ara wa níjàánu.
MAY 20-26
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 40-41
Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́?
A Máa Láyọ̀ Tá A Bá Jẹ́ Ọ̀làwọ́
16 Ohun kan ni pé àwọn tó bá lawọ́ kì í fúnni torí ohun tí wọ́n máa rí gbà pa dà. Ohun tí Jésù ní lọ́kàn nìyẹn nígbà tó sọ pé: “Nígbà tí ìwọ bá se àsè, ké sí àwọn òtòṣì, amúkùn-ún, arọ, afọ́jú; ìwọ yóò sì láyọ̀, nítorí tí wọn kò ní nǹkan kan láti fi san án padà fún ọ.” (Lúùkù 14:13, 14) Òǹkọ̀wé Bíbélì kan sọ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olójú àánú [tàbí ọ̀làwọ́] ni a ó bù kún.” Òmíràn sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀.” (Òwe 22:9; Sm. 41:1) Ó dájú pé, a máa láyọ̀ tá a bá ń fún àwọn míì ní nǹkan.
17 Kì í ṣe àwọn nǹkan tara nìkan ni Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nígbà tó fa ọ̀rọ̀ Jésù yọ pé “ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” Àwọn nǹkan míì tún wà tá a lè fún àwọn èèyàn. Bí àpẹẹrẹ, a lè fún àwọn míì ní ìṣírí àti ìtọ́sọ́nà, ká sì ràn wọ́n lọ́wọ́. (Ìṣe 20:31-35) Pọ́ọ̀lù fi àpẹẹrẹ tó dáa lélẹ̀ lórí kókó yìí. Ohun tó sọ àti ohun tó ṣe jẹ́ ká rí i pé ó yẹ ká máa lo àkókò wa àti okun wa fáwọn míì, ká máa fìfẹ́ hàn sí wọn, ká sì máa tẹ́tí gbọ́ wọn.
18 Àwọn kan tó máa ń ṣèwádìí nípa ìwà ẹ̀dá sọ pé àwọn tó bá ń fúnni máa láyọ̀. Àpilẹ̀kọ kan sọ pé àwọn èèyàn máa ń láyọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n bá ṣe ohun tó dáa fún àwọn míì. Kódà, àwọn olùṣèwádìí sọ pé téèyàn bá ń ran àwọn míì lọ́wọ́, ìgbésí ayé rẹ̀ á nítumọ̀. Ìdí nìyẹn táwọn ọ̀jọ̀gbọ́n kan fi sọ pé ó dáa kéèyàn máa yọ̀ǹda ara rẹ̀ fún iṣẹ́ ìlú. Wọ́n sọ pé téèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, á láyọ̀, ìlera ẹ̀ á sì túbọ̀ dáa sí i. Ohun tí wọ́n sọ yìí ò yà wá lẹ́nu torí pé ọjọ́ pẹ́ tí Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa ti sọ nínú Bíbélì pé fífúnni máa ń jẹ́ kéèyàn láyọ̀.—2 Tím. 3:16, 17.
Jèhófà Yóò Gbé Ọ Ró
7 Síbẹ̀ tá a bá ń ṣàìsàn, a lè bẹ Ọlọ́run pé kó tù wá nínú, kó fún wa lọ́gbọ́n kó sì ràn wá lọ́wọ́ bó ṣe ṣe fáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ láyé àtijọ́. Dáfídì Ọba sọ pé: “Aláyọ̀ ni ẹnikẹ́ni tí ń fi ìgbatẹnirò hùwà sí ẹni rírẹlẹ̀; Ní ọjọ́ ìyọnu àjálù, Jèhófà yóò pèsè àsálà fún un. Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò máa ṣọ́ ọ, yóò sì pa á mọ́ láàyè.” (Sm. 41:1, 2) A mọ̀ pé, nígbà ayé Dáfídì kò sẹ́nì kankan tí kò kú torí pé ó ń ṣàánú àwọn ẹni rírẹlẹ̀. Torí náà, kò dájú pé ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé kí Jèhófà dá ẹni náà sí lọ́nà ìyanu, kó má bàa kú mọ́. Ohun tí Dáfídì ń sọ ni pé Ọlọ́run máa ran irú ẹni bẹ́ẹ̀ lọ́wọ́. Àmọ́, báwo ló ṣe máa ṣe é? Dáfídì sọ pé: “Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò gbé e ró lórí àga ìnàyìn ti àmódi; gbogbo ibùsùn rẹ̀ ni ìwọ yóò yí padà dájúdájú nígbà àìsàn rẹ̀.” (Sm. 41:3) Ó yẹ kó dá ẹni tó bá ń ṣojú àánú sí ẹni rírẹlẹ̀ lójú pé Ọlọ́run rí gbogbo ìwà rere rẹ̀, kò sì ní gbàgbé láé. Ara rẹ̀ sì lè yá torí Ọlọ́run ti dá wa lọ́nà tí ara wa fi lè gbógun ti àìsàn.
Máa Fàánú Hàn Bíi Ti Jèhófà
17 Kì í ṣe torí ká lè rí àánú gbà nìkan la ṣe ń fàánú hàn sáwọn èèyàn. Ìdí pàtàkì tá a fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé a fẹ́ fara wé Jèhófà, Ọlọ́run àánú àti ìfẹ́, a sì fẹ́ máa bọlá fún un. (Òwe 14:31) Òun ló fi àpẹẹrẹ pípé lélẹ̀ fún wa. Torí náà, ẹ jẹ́ ká sa gbogbo ipá wa láti fara wé e, ká máa fìfẹ́ bá àwọn ará wa lò lọ́kùnrin àti lóbìnrin, ká sì máa fàánú hàn sáwọn aládùúgbò wa.—Gál. 6:10; 1 Jòh. 4:16.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 16
Jèhófà
Ohun tí gbogbo Bíbélì látòkèdélẹ̀ dá lé ni bí Jèhófà ṣe máa fi hàn pé òun ni Ọba Aláṣẹ Ayé Àtọ̀run àti bó ṣe máa dá orúkọ rẹ̀ láre. Èyí sì jẹ́ ká mọ ohun tó wu Jèhófà jù lọ láti ṣe, ìyẹn sì ni bó ṣe máa sọ orúkọ rẹ̀ di mímọ́. Tí orúkọ Ọlọ́run bá máa di mímọ́, á jẹ́ pé gbogbo ẹ̀gàn tó ti bá orúkọ náà gbọ́dọ̀ kúrò. Àmọ́ èyí tó ṣe pàtàkì jù ni pé, kí gbogbo ẹ̀dá olóye láyé àtọ̀run bọ̀wọ̀ fún orúkọ yẹn, kí wọ́n sì gbà pé ó jẹ́ mímọ́. Torí náà, wọ́n gbọ́dọ̀ gbà pé Jèhófà ni Ọba Aláṣẹ, kí wọ́n sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Wọ́n sì gbọ́dọ̀ ṣe bẹ́ẹ̀ tinútinú, kí wọ́n ṣe tán láti jọ́sìn rẹ̀, kí inú wọn sì máa dùn láti ṣe ohun tó fẹ́ torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀ dénú. Ìfẹ́ àtọkànwá yìí hàn nínú àdúrà tí Dáfídì gbà ní Sáàmù 40:5-10, bákan náà àdúrà yẹn fi hàn pé Dáfídì fẹ́ kí orúkọ Jèhófà di mímọ́. (Ní Heb 10:5-10, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù jẹ́ ká rí i pé àwọn apá kan nínú Sáàmù náà ṣẹ sí Jésù lára.)
MAY 27–JUNE 2
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 42-44
Máa Fi Ohun Tí Jèhófà Ń Kọ́ Wa Sílò
Àwọn Kókó Pàtàkì Látinú Ìwé Kejì Sáàmù
42:4, 5, 11; 43:3-5. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé a ò ráyè bá ìjọ Kristẹni pé jọ fún ìgbà díẹ̀, bóyá nítorí àwọn ìdí kan tó kọjá agbára wa, bá a ṣe ń rántí ayọ̀ tí irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ máa ń fún wa tẹ́lẹ̀ rí lè mẹ́sẹ̀ wa dúró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé èyí lè kọ́kọ́ mú ká máa ronú pé a dá nìkan wà, àmọ́ yóò tún máa rán wa létí pé Ọlọ́run ni ibi ìsádi wa àti pé a ní láti dúró dìgbà tó máa ṣọ̀nà àbáyọ.
Bó O Ṣe Lè Mú Kí Ìkẹ́kọ̀ọ́ Gbádùn Mọ́ Ẹ Kó sì Ṣe Ẹ́ Láǹfààní
1 GBÀDÚRÀ: Ohun tó yẹ kó o kọ́kọ́ ṣe ni pé kó o gbàdúrà. (Sm. 42:8) Kí nìdí? Ìdí ni pé apá kan ìjọsìn wa ló yẹ ká máa ka kíkẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sí. Torí náà, ó yẹ ká máa bẹ Jèhófà pé kó jẹ́ kí ohun tá à ń kà máa wọ̀ wá lọ́kàn, kó sì fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lúùkù 11:13) Barbara, tó ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì sọ pé: “Mi ò lè ṣe kí n má gbàdúrà kí n tó ka Bíbélì tàbí kí n tó kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn, ọkàn mi máa ń balẹ̀ pé Jèhófà wà pẹ̀lú mi àti pé ó fara mọ́ ohun tí mò ń ṣe.” Béèyàn bá gbàdúrà kó tó kẹ́kọ̀ọ́, ó máa lóye ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tó fẹ́ jẹ, ohun tó kọ́ á sì wọ̀ ọ́ lọ́kàn.
“Má Ṣe Jẹ́ Kí Ọwọ́ Rẹ Rọ Jọwọrọ”
11 Ohun míì tó ń fún wa lókun ni ẹ̀kọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tá à ń kọ́ láwọn ìpàdé wa, àwọn àpéjọ àtàwọn ilé ẹ̀kọ́ ètò Ọlọ́run. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ tá à ń gbà yìí ń mú kó máa wù wá láti ṣe ohun tó tọ́, ó mú ká ní àfojúsùn nínú ìjọsìn Ọlọ́run, ó sì máa ń jẹ́ ká bójú tó àwọn ojúṣe wa nínú ìjọsìn Ọlọ́run. (Sm. 119:32) Ṣó máa ń wù ẹ́ láti wà láwọn ibi tá a ti ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí kó o lè máa rókun gbà?
12 Jèhófà ran àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọmọ Ámálékì àtàwọn ará Etiópíà, ó sì tún fún Nehemáyà àtàwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ lágbára láti parí ògiri Jerúsálẹ́mù. Á fún àwa náà lókun láti borí àníyàn, á sì tún ràn wá lọ́wọ́ nígbà táwọn èèyàn bá ta kò wá tàbí nígbà tí wọ́n bá kọtí ikún sí iṣẹ́ ìwàásù wa. Ìrànwọ́ yìí á mú ká lè ṣe iṣẹ́ náà láṣeyọrí. (1 Pét. 5:10) A ò retí pé kí Jèhófà ṣe iṣẹ́ ìyanu fún wa, àwa náà lóhun tá a gbọ́dọ̀ ṣe. Lára ẹ̀ ni pé ká máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́, ká máa múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ ká sì máa pésẹ̀ síbẹ̀ déédéé, ká máa dá kẹ́kọ̀ọ́, ká sì máa ṣe Ìjọsìn Ìdílé déédéé. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká má fọ̀rọ̀ àdúrà ṣeré. Ẹ má ṣe jẹ́ ká gba àwọn nǹkan míì láyè láti dí wa lọ́wọ́ ṣíṣe àwọn nǹkan tá a sọ tán yìí, torí pé àwọn nǹkan yẹn ni Jèhófà ń lò láti fún wa lókun àti ìṣírí. Tó o bá kíyè sí i pé o ti ń dẹwọ́ nínú èyíkéyìí lára àwọn ohun tá a sọ yìí, bẹ Jèhófà pé kó ràn ẹ́ lọ́wọ́. Wàá rí i pé ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà á jẹ́ kó máa wù ẹ́ láti ṣe ohun tó tọ́, á sì mú kó o ṣe bẹ́ẹ̀. (Fílí. 2:13) Àmọ́, báwo nìwọ náà ṣe lè fáwọn míì lókun?
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 1242
Ajáko
Bíbélì sábà máa ń lo ajáko lọ́nà ìṣàpẹẹrẹ. Nígbà tí Jóòbù ń sọ bí nǹkan ṣe burú tó fún un, ó sọ pé òun ti di “arákùnrin àwọn ajáko.” (Job 30:29) Nígbà tí onísáàmù náà ń sọ nípa bí àwọn ọ̀tá ṣe ṣẹ́gun àwọn èèyàn Ọlọ́run, níbi tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ibi táwọn ajáko ti máa ń jẹ òkú àwọn tí wọ́n pa lójú ogun (fi wé Sm 68:23), ó kédàárò pé: “O ti tẹ̀ wá rẹ́ níbi tí àwọn ajáko ń gbé.” (Sm 44:19) Nígbà táwọn ọmọ ogun Bábílónì yí Jerúsálẹ́mù ká lọ́dún 607 Ṣ.S.K., ebi pa àwọn èèyàn débi pé àwọn ìyá bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ ọmọ wọn. Torí náà, nígbà tí Jeremáyà ń sọ̀rọ̀ nípa ìwà ìkà tí “àwọn èèyàn” rẹ̀ ń hù, ó sọ pé àwọn ajáko pàápàá máa ń tọ́jú ọmọ wọn.—Ida 4:3, 10.
JUNE 3-9
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 45-47
Orin Ìgbéyàwó Ọba Kan
Ẹ Yọ̀ Nítorí Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn!
8 Ka Sáàmù 45:13, 14a. Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí fi hàn pé a ti múra ìyàwó tó “kún fún ògo látòkè délẹ̀” náà sílẹ̀ fún ìgbéyàwó tó wáyé ní ìdílé ọba yìí. Nínú Ìṣípayá 21:2, a fi ìyàwó náà wé ìlú kan, ìyẹn Jerúsálẹ́mù Tuntun, a sì ṣe é “lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọkọ rẹ̀.” Ìlú tó wà lọ́run yìí “ní ògo Ọlọ́run,” ó sì ń tàn yinrin “bí òkúta ṣíṣeyebíye jù lọ, bí òkúta jásípérì tí ń dán bí kírísítálì tí ó mọ́ kedere.” (Ìṣí. 21:10, 11) Ìwé Ìṣípayá ṣàlàyé bí Jerúsálẹ́mù Tuntun yìí ṣe ń dán gbinrin ní ọ̀nà kan tó fani mọ́ra. (Ìṣí. 21:18-21) Abájọ tí onísáàmù náà fi sọ pé ìyàwó náà “kún fún ògo látòkè délẹ̀”! Ó ṣe tán, ọ̀run ni wọ́n ti máa ṣe ìgbéyàwó tó jẹ́ ti ìdílé ọba yìí.
9 Ẹni tí wọ́n mú ìyàwó náà wá bá ni Ọkọ Ìyàwó, ìyẹn Mèsáyà Ọba. Ó ti ń múra ìyàwó rẹ̀ yìí sílẹ̀ nípa “wíwẹ̀ ẹ́ mọ́ pẹ̀lú ìwẹ̀ omi nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ náà.” Ó wà ní “mímọ́ àti láìsí àbààwọ́n.” (Éfé. 5:26, 27) Ìyàwó náà alára gbọ́dọ̀ múra lọ́nà tó bá ayẹyẹ ìgbéyàwó wọn mu. Bó sì ṣe rí gan-an nìyẹn! Kódà, “aṣọ rẹ̀ ní àwọn ibi tí [wọ́n] lẹ wúrà mọ́,” wọ́n á sì ‘mú un tọ ọba wá nínú aṣọ ọ̀ṣọ́ híhun.’ Nígbà ìgbéyàwó rẹ̀ pẹ̀lú Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà, Bíbélì sọ pé, “a ti yọ̀ǹda fún un kí a fi aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, tí ó mọ́ ṣe é ní ọ̀ṣọ́, nítorí pé aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà náà dúró fún àwọn ìṣe òdodo àwọn ẹni mímọ́.”—Ìṣí. 19:8.
Ohun Tí Ìwé Ìfihàn Sọ Nípa Ọjọ́ Iwájú
10 Kí ni Jèhófà máa ṣe tí wọ́n bá gbéjà ko àwọn èèyàn rẹ̀? Ó sọ pé: “Inú á bí mi gidigidi.” (Ìsík. 38:18, 21-23) Ìfihàn orí 19 sọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ìyẹn. Jèhófà máa rán Ọmọ rẹ̀ láti gbèjà àwọn èèyàn rẹ̀, kó sì ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá wọn. Bíbélì sọ pé “àwọn ọmọ ogun ọ̀run,” ìyẹn àwọn áńgẹ́lì olóòótọ́ àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì (144,000) máa dara pọ̀ mọ́ Jésù láti ja ogun náà. (Ìfi. 17:14; 19:11-15) Kí ni ogun náà máa yọrí sí? Gbogbo àwọn tó ń ta ko Jèhófà máa pa run pátápátá!—Ka Ìfihàn 19:19-21.
11 Ẹ wo bó ṣe máa rí lára àwọn olóòótọ́ tó máa là á já nígbà tí gbogbo àwọn ọ̀tá Ọlọ́run bá pa run! Àkókò ayọ̀ nìyẹn máa jẹ́! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ariwo ayọ̀ má sọ lọ́run nígbà tí Bábílónì Ńlá bá pa run, ohun míì máa ṣẹlẹ̀ tó máa mú ayọ̀ tó ju ìyẹn lọ wá. (Ìfi. 19:1-3) Nǹkan náà ni “ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà,” ó sì wà lára àwọn nǹkan tó ṣe pàtàkì jù nínú ìwé Ìfihàn.—Ìfi. 19:6-9.
12 Ìgbà wo ni ìgbéyàwó náà máa wáyé? Gbogbo àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì máa ti wà lọ́run kí ogun Amágẹ́dọ́nì tó bẹ̀rẹ̀. Àmọ́ kì í ṣe ìgbà yẹn ni Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa ṣègbéyàwó. (Ka Ìfihàn 21:1, 2.) Ìgbéyàwó Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà máa wáyé lẹ́yìn tí ogun Amágẹ́dọ́nì bá ti parí, tí Ọlọ́run sì ti pa gbogbo àwọn ọ̀tá ẹ̀ run.—Sm. 45:3, 4, 13-17.
it-2 1169
Ogun
Tí ogun yìí bá parí, aráyé máa ní àlàáfíà fún ẹgbẹ̀rún ọdún. Sáàmù tó sọ pé “[Jèhófà] ń fòpin sí ogun kárí ayé, ó ṣẹ́ ọrun, ó sì kán ọ̀kọ̀ sí wẹ́wẹ́, ó sun àwọn kẹ̀kẹ́ ogun nínú iná,” kọ́kọ́ ní ìmúṣẹ nígbà tí Jèhófà fọ́ ohun ìjà ọ̀tá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sí wẹ́wẹ́, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí àlàáfíà wà nílẹ̀ wọn. Lẹ́yìn tí Kristi bá pa àwọn ọ̀tá rẹ̀ run nígbà ogun Amágẹ́dọ́nì, àlàáfíà máa wà ní gbogbo ayé. (Sm 46:8-10) Àwọn tó bá ‘fi idà wọn rọ ohun ìtúlẹ̀, tí wọ́n fi ọ̀kọ̀ wọn rọ ohun ìrẹ́wọ́ ọ̀gbìn’ tí wọ́n ‘ò sì kọ́ṣẹ́ ogun mọ́’ ló máa jogún ìyè àìnípẹ̀kun. “Torí Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun ló fi ẹnu ara rẹ̀ sọ ọ́.”—Ais 2:4; Mik 4:3, 4.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
Àwọn Nǹkan Wo Ló Máa Lọ tí Ìjọba Ọlọ́run Bá Dé?
9 Kí ló máa rọ́pò àwọn ètò búburú ayé yìí? Ṣé ètò míì máa wà láyé yìí lẹ́yìn ogun Amágẹ́dọ́nì? Bíbélì sọ pé: “Ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun wà tí a ń dúró dè ní ìbámu pẹ̀lú ìlérí rẹ̀, nínú ìwọ̀nyí ni òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pét. 3:13) Ọ̀run àti ayé ògbólógbòó yìí kò ní sí mọ́, ìyẹn àwọn ìjọba búburú àtàwọn èèyàn burúkú abẹ́ wọn. Kí ló máa wá rọ́pò wọn? Gbólóhùn náà, “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” túmọ̀ sí ìjọba tuntun tó máa ṣàkóso ayé àti àwọn èèyàn tuntun tó máa ṣàkóso lé lórí. Jésù Kristi tó jẹ́ ọba Ìjọba náà máa ṣàgbéyọ àwọn ànímọ́ Jèhófà tó jẹ́ Ọlọ́run ètò. (1 Kọ́r. 14:33) Torí náà, àwọn nǹkan máa wà létòlétò nínú “ayé tuntun.” Àwọn ọkùnrin rere láá máa bójú tó àwọn nǹkan. (Sm. 45:16) Kristi àtàwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] tí wọ́n á jọ ṣàkóso láá máa darí àwọn ọkùnrin yẹn. Ẹ wo bí ayé ṣe máa rí nígbà tí ètò kan ṣoṣo, tó jẹ́ mímọ́, tó sì wà níṣọ̀kan bá rọ́pò àwọn ètò búburú ayé yìí!
JUNE 10-16
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 48-50
Ẹ̀yin Òbí, Ẹ ran Àwọn Ọmọ Yín Lọ́wọ́ Kí Wọ́n Lè Fọkàn Tán Ètò Jèhófà
Ìjọsìn Tòótọ́ Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Láyọ̀
11 Tá a bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tá a sì ń kọ́ àwọn ọmọ wa nípa Jèhófà, à ń jọ́sìn ẹ̀ nìyẹn. Lọ́jọ́ Sábáàtì, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kì í ṣiṣẹ́ kankan, ṣe ni wọ́n máa ń lo ọjọ́ náà láti jẹ́ kí àjọṣe àwọn àti Jèhófà túbọ̀ lágbára. (Ẹ́kís. 31:16, 17) Àwọn tó ń pa Sábáàtì yẹn mọ́ láàárín wọn máa ń lo àkókò náà láti kọ́ àwọn ọmọ wọn nípa Jèhófà àtàwọn nǹkan rere tó ti ṣe fún wọn. Bákan náà lónìí, ó yẹ ká máa wáyè ka Bíbélì, ká sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Ọ̀kan lára ọ̀nà tá à ń gbà jọ́sìn nìyẹn, ó sì ń jẹ́ ká túbọ̀ sún mọ́ ọn. (Sm. 73:28) Yàtọ̀ síyẹn, tí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pa pọ̀, àwọn òbí máa lè ran àwọn ọmọ wọn lọ́wọ́ láti ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Baba wa ọ̀run.—Ka Sáàmù 48:13.
Ẹ Ní Ìdí fún Ayọ̀ Yíyọ̀
“Ẹ rìn yí Síónì ká, kí ẹ sì lọ káàkiri nínú rẹ̀, ẹ ka àwọn ilé gogoro rẹ̀. Ẹ jẹ́ kí ọkàn-àyà yín ṣàníyàn nípa ohun àfiṣe-odi rẹ̀. Ẹ bẹ àwọn ilé gogoro ibùgbé rẹ̀ wò, kí ẹ lè ròyìn rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la.” (Sm. 48:12, 13) Nínú ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí, onísáàmù náà rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé kí wọ́n wo Jerúsálẹ́mù kínníkínní. Ǹjẹ́ o lè ronú nípa ìrírí mánigbàgbé tí àwọn ìdílé ní Ísírẹ́lì máa ń ní bí wọ́n bá rìnrìn àjò lọ sí ìlú mímọ́ náà fún àwọn àjọyọ̀ ọdọọdún tí wọ́n sì rí tẹ́ńpìlì àgbàyanu tó wà níbẹ̀? Èyí ti ní láti mú kí wọ́n “ròyìn rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ fún ìran ẹ̀yìn ọ̀la.”
Ronú nípa ayaba Ṣébà, ẹni tó kọ́kọ́ ń ṣiyè méjì nípa àwọn ìròyìn tó gbọ́ nípa ìṣàkóso gíga lọ́la Sólómọ́nì àti ọgbọ́n jíjinlẹ̀ tó ní. Kí ló mú kó dá a lójú pé òótọ́ ni àwọn nǹkan tó gbọ́? Ó sọ pé: “Èmi kò sì ní ìgbàgbọ́ nínú àwọn ọ̀rọ̀ wọn títí mo fi wá kí ojú èmi fúnra mi lè rí i.” (2 Kíró. 9:6) Ó dájú pé ohun tá a bá fi ‘ojú tiwa’ fúnra wa rí lè nípa tó jinlẹ̀ lórí wa.
Báwo lo ṣe lè ran àwọn ọmọ rẹ lọ́wọ́ kí wọ́n lè fi ‘ojú tiwọn’ fúnra wọn rí àwọn ohun àgbàyanu tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ètò Jèhófà? Bí ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá wà nítòsí ilé rẹ, sapá láti ṣèbẹ̀wò síbẹ̀. Bí àpẹẹrẹ, ibi tí Mandy àti Bethany gbé dàgbà fi nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] kìlómítà, ìyẹn ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn-án ibùsọ̀, jìn sí Bẹ́tẹ́lì tó wà lórílẹ̀-èdè wọn. Síbẹ̀, àwọn òbí wọn ṣètò kí wọ́n lè máa rìnrìn àjò lọ síbẹ̀ lemọ́lemọ́, pàápàá jù lọ nígbà táwọn ọmọ wọn obìnrin ti bẹ̀rẹ̀ sí í dàgbà. Wọ́n ṣàlàyé pé: “A kò kọ́kọ́ rò pé ó yẹ ká máa lọ sí Bẹ́tẹ́lì, torí a rò pé àwọn arúgbó nìkan ni ibẹ̀ wà fún. Ṣùgbọ́n a rí àwọn ọ̀dọ́ tí wọ́n ń ṣiṣẹ́ kára fún Jèhófà tí wọ́n sì ń gbádùn iṣẹ́ wọn! A wá rí i pé ètò Jèhófà gbòòrò ré kọjá agbègbè kékeré tí à ń gbé, ńṣe ni gbogbo ìbẹ̀wò tá à ń ṣe sí Bẹ́tẹ́lì ń mú ká túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà, ó sì ń mú ká túbọ̀ fẹ́ láti máa sìn ín.” Bí Mandy àti Bethany ṣe wo ètò Ọlọ́run kínníkínní yìí mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà, wọ́n sì rí ìkésíni gbà láti lọ ṣe iṣẹ́ olùyọ̀ǹda ara ẹni ní Bẹ́tẹ́lì fún àkókò díẹ̀.
Ẹ Máa Bá A Nìṣó Gẹ́gẹ́ Bí Ọmọ Ìjọba Ọlọ́run!
5 Kọ́ ìtàn. Bí ẹnì kan bá fẹ́ di ọmọ orílẹ̀-èdè kan, ó lè gba pé kó mọ̀ nípa ìtàn ìjọba orílẹ̀-èdè náà. Bákan náà, ó dára kí àwọn tó bá fẹ́ di ọmọ Ìjọba Ọlọ́run mọ gbogbo ohun tí wọ́n bá lè mọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. A lè ronú nípa àwọn ọmọ Kórà, tí wọ́n sin Jèhófà ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì ìgbàanì. Wọ́n fẹ́ràn Jerúsálẹ́mù àti ibi ìjọsìn tó wà níbẹ̀ gan-an ni, ó sì máa ń wù wọ́n láti sọ ìtàn ìlú náà. Kì í ṣe àwọn òkúta tí wọ́n fi mọ ògiri ìlú yẹn ló gbà wọ́n lọ́kàn jù lọ bí kò ṣe ohun tí ìlú náà àti ibi ìjọsìn tó wà níbẹ̀ dúró fún. Jerúsálẹ́mù ni “ìlú Ọba títóbi lọ́lá” náà, Jèhófà, torí pé ibẹ̀ ni ojúkò ìjọsìn tòótọ́. Ibẹ̀ ni wọ́n ti ń kọ́ àwọn èèyàn ní Òfin Jèhófà. Àwọn èèyàn tí Ọba Jerúsálẹ́mù ṣàkóso lé lórí ni Jèhófà fi inú rere onífẹ̀ẹ́ hàn sí. (Ka Sáàmù 48:1, 2, 9, 12, 13.) Ṣó wu ìwọ náà láti kọ́ ìtàn nípa apá tó jẹ́ ti ilẹ̀ ayé lára ètò Jèhófà, kó o sì máa sọ ìtàn náà fáwọn èèyàn? Bó o bá ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa ètò Ọlọ́run àti bí Jèhófà ṣe ń ti àwọn èèyàn rẹ̀ lẹ́yìn, bẹ́ẹ̀ náà ni Ìjọba Ọlọ́run á ṣe túbọ̀ máa jẹ́ ohun gidi lójú rẹ. Á sì túbọ̀ máa wù ẹ́ látọkànwá pé kó o máa wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Jer. 9:24; Lúùkù 4:43.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-2 805
Ọrọ̀
Nǹkan rọ̀ṣọ̀mù ní ilẹ̀ Ísírẹ́lì, torí náà àwọn èèyàn náà rí jẹ, wọ́n sì rí mu. (1Ọb 4:20; Onw 5:18, 19) Kódà, ọrọ̀ tí wọ́n ní ò jẹ́ kí wọ́n ṣaláìní àwọn ohun tí wọ́n nílò. (Owe 10:15; Onw 7:12) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣiṣẹ́ kára lóòótọ́, Jèhófà ló bù kún wọn tó sì jẹ́ kí wọ́n lọ́rọ̀. (Fi wé Owe 6:6-11; 20:13; 24:33, 34) Abájọ tó fi kìlọ̀ fún wọn pé wọn ò gbọ́dọ̀ gbẹ́kẹ̀ lé ọrọ̀ tí wọ́n ní débi tí wọ́n á fi gbàgbé òun. (Di 8:7-17; Sm 49:6-9; Owe 11:4; 18:10, 11; Jer 9:23, 24) Jèhófà rán wọn létí pé, ọrọ̀ kì í tọ́jọ́ (Owe 23:4, 5) wọn ò sì lè fi san ìràpadà fún Ọlọ́run kó lè gbà wọ́n lọ́wọ́ ikú (Sm 49:6, 7), kò sì wúlò fún ẹni tó ti kú (Sm 49:16, 17; Onw 5:15). Tó bá jẹ́ pé bí wọ́n á ṣe kó ọrọ̀ jọ ni wọ́n gbájú mọ́, ìyẹn lè jẹ́ kí wọ́n lọ́wọ́ sí ìwà tí kò tọ́, kí wọ́n má sì rí ojú rere Jèhófà. (Owe 28:20; fi wé Jer 5:26-28; 17:9-11.) Jèhófà sì tún gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n “fi àwọn ohun ìní [wọn] tó níye lórí bọlá fún” òun.—Owe 3:9.
JUNE 17-23
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 51-53
Ohun Tó O Lè Ṣe Tó Ò Fi Ní Dẹ́ṣẹ̀ Tó Burú Jáì
Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?
4 Nínú Òwe 4:23, Bíbélì lo ọ̀rọ̀ náà ọkàn nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa ẹni tá a jẹ́ nínú. (Ka Sáàmù 51:6.) Lédè míì, ọkàn ń tọ́ka sí èrò wa, bí nǹkan ṣe máa ń rí lára wa, ohun tó ń sún wa ṣe nǹkan àti ìfẹ́ ọkàn wa. Ó ṣe kedere pé ẹni tá a jẹ́ nínú ni ọkàn ń tọ́ka sí, kì í ṣe ohun tá a jẹ́ lóde tàbí ohun táwọn èèyàn gbà pé a jẹ́.
5 Ẹ jẹ́ ká fi ọ̀rọ̀ ìlera ṣàkàwé bó ṣe yẹ kára èèyàn le nípa tẹ̀mí. Àkọ́kọ́, kára èèyàn lè jí pépé, ó ṣe pàtàkì kéèyàn máa jẹ oúnjẹ aṣaralóore, kó sì máa ṣe eré ìmárale déédéé. Lọ́nà kan náà, ó ṣe pàtàkì ká máa jẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé tá a bá fẹ́ dúró sán-ún nípa tẹ̀mí, a sì gbọ́dọ̀ máa ṣe ohun tó fi hàn pé lóòótọ́ la nígbàgbọ́ nínú Jèhófà. Èyí gba pé ká máa fi ohun tá à ń kọ́ sílò, ká sì máa sọ ohun tá a gbà gbọ́ fún àwọn míì. (Róòmù 10:8-10; Ják. 2:26) Ìkejì, ẹnì kan lè máa ta kébékébé, kó sì rò pé koko lara òun le, síbẹ̀ kó jẹ́ pé onírúurú àrùn ló ti kọ́lé sí i lára. Lọ́nà kan náà, ẹnì kan lè máa ṣe tibí ṣe tọ̀hún lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kó sì gbà pé ìgbàgbọ́ òun lágbára, síbẹ̀ kó jẹ́ pé ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ti gbà á lọ́kàn. (1 Kọ́r. 10:12; Ják. 1:14, 15) Ká máa fi sọ́kàn pé gbogbo ọ̀nà ni Sátánì ń wá láti sọ èrò ọkàn wa dìbàjẹ́. Àwọn ọgbọ́nkọ́gbọ́n wo ló máa ń dá gan-an? Báwo la ṣe lè dáàbò bo ara wa?
A Lè Jẹ́ Oníwà Mímọ́
5 Ọ̀nà pàtàkì kan tó máa fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá ni pé, ká bẹ̀ ẹ́ pé kó jẹ́ ká lè borí èrò tí kò tọ́. Tá a bá sún mọ́ Jèhófà nípasẹ̀ àdúrà, òun náà á sún mọ́ wa. Jèhófà máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ní fàlàlà ká lè túbọ̀ dúró lórí ìpinnu wa láti sá fún èrò ìṣekúṣe, ká sì jẹ́ oníwà mímọ́. Torí náà, ẹ jẹ́ kí àṣàrò ọkàn wa jẹ́ kí Ọlọ́run mọ̀ pé a máa sa gbogbo ipá wa láti ṣe ìfẹ́ rẹ̀. (Sm. 19:14) Ǹjẹ́ à ń fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé kó yẹ̀ wá wò, bóyá “ọ̀nà èyíkéyìí tí ń roni lára,” ìyẹn èròkerò tàbí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́, wà lọ́kàn wa tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀? (Sm. 139:23, 24) Ǹjẹ́ à ń bẹ Jèhófà lóòrèkóòrè pé kó ràn wá lọ́wọ́, ká lè jẹ́ olóòótọ́ sí i nígbà tá a bá dojú kọ àdánwò?—Mát. 6:13.
6 Ó ṣeé ṣe kí ìwà tá à ń hù tẹ́lẹ̀ tàbí bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà ti mú ká máa hu àwọn ìwà tí Jèhófà kà léèwọ̀. Síbẹ̀, Ọlọ́run lè ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣe àwọn àtúnṣe táá jẹ́ ká lè máa sìn ín lọ́nà tó tẹ́wọ́ gbà. Èyí dá Dáfídì Ọba lójú, kódà lẹ́yìn tó bá Bátí-ṣébà ṣe panṣágà, ó bẹ Jèhófà pé: “Dá ọkàn-àyà mímọ́ gaara sínú mi, . . . Kí o sì fi ẹ̀mí tuntun sínú mi, ọ̀kan tí ó fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin.” (Sm. 51:10, 12) Torí pé aláìpé ni wá, ó lè wù wá gan-an ká lọ́wọ́ nínú ìwà tó lè yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀, àmọ́ Jèhófà lè mú kó máa wù wá látọkàn wá láti máa ṣègbọràn sí i. Kódà tí èròkerò bá gbilẹ̀ lọ́kàn wa, tó sì ń darí ìrònú wa láti hu ìwà àìmọ́, Jèhófà lè tọ́ wa sọ́nà ká lè máa pa àwọn àṣẹ rẹ̀ mọ́, kó sì hàn bẹ́ẹ̀ nínú bá a ṣe ń gbé ìgbé ayé wa. Ó lè dáàbò bò wá kúrò lọ́wọ́ ewu èyíkéyìí tó lè fẹ́ borí wa.—Sm. 119:133.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 644
Dóẹ́gì
Ipò tó ṣe pàtàkì ni Dóẹ́gì ọmọ Édómù wà, torí pé òun ni olórí àwọn olùṣọ́ àgùntàn Ọba Sọ́ọ̀lù. (1Sa 21:7; 22:9) Ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ aláwọ̀ṣe Júù. Ó lè jẹ́ torí ẹ̀jẹ́, àìmọ́, tàbí ẹ̀tẹ̀ kan tí ò tíì hàn síta ló mú kí wọ́n dá a “dúró níwájú Jèhófà” ní Nóbù, ìyẹn ló sì jẹ́ kó rí Àlùfáà Àgbà Áhímélékì nígbà tó fún Dáfídì ní búrẹ́dì àfihàn àti idà Gòláyátì. Nígbà tó yá, Sọ́ọ̀lù fẹ̀sùn kan àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ pé wọ́n dìtẹ̀ mọ́ òun, ni Dóẹ́gì bá sọ gbogbo ohun tó rí ní Nóbù. Sọ́ọ̀lù wá ránṣẹ́ pé àlùfáà àgbà àtàwọn àlùfáà yòókù, ó sì ń da ìbéèrè bò Áhímélékì. Lójú ẹsẹ̀, Sọ́ọ̀lù ní kí àwọn ẹ̀ṣọ́ tó yí i ká pa gbogbo wọn. Nígbà táwọn ẹ̀ṣọ́ náà kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀, Sọ́ọ̀lù pàṣẹ fún Dóẹ́gì pé kó pa wọ́n, láìjáfara Dóẹ́gì pa àwọn àlùfáà márùnlélọ́gọ́rin (85). Dóẹ́gì ò fi ìwà burúkú yìí mọ síbẹ̀, ó tún pa gbogbo àwọn ará ìlú Nóbù lọ́mọdé, lágbà títí kan àwọn ẹran ọ̀sìn wọn.—1Sa 22:6-20.
Bó ṣe wà nínú ọ̀rọ̀ àkọlé Sáàmù 52, Dáfídì sọ nípa Dóẹ́gì pé: “Ahọ́n rẹ mú bí abẹ fẹ́lẹ́, ó ń pète ibi, ó sì ń ṣiṣẹ́ ẹ̀tàn. Ìwọ nífẹ̀ẹ́ ohun búburú ju ohun rere lọ, o sì nífẹ̀ẹ́ pípa irọ́ ju sísọ ohun tí ó tọ́. O nífẹ̀ẹ́ gbogbo ọ̀rọ̀ tó ń pani run, ìwọ ahọ́n ẹ̀tàn.”—Sm 52:2-4.
JUNE 24-30
ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN SÁÀMÙ 54-56
Ọlọ́run Ò Ní Fi Ẹ́ Sílẹ̀
Jẹ́ Ọlọgbọ́n, Kó O sì Ní Ìbẹ̀rù Ọlọ́run!
10 Ìgbà kan wà tí Dáfídì lọ sá sọ́dọ̀ Ákíṣì, ọba ìlú àwọn ará Filísínì kan tó ń jẹ́ Gátì, ìyẹn ìlú Gòláyátì. (1 Sámúẹ́lì 21:10-15) Àwọn ìránṣẹ́ ọba náà sọ pé ọ̀tá orílẹ̀-èdè àwọn ni Dáfídì. Kí ni Dáfídì wá ṣe nígbà tó bá ara rẹ̀ nínú irú ipò eléwu bẹ́ẹ̀? Ó fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbàdúrà sí Jèhófà. (Sáàmù 56:1-4, 11-13) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Dáfídì dá ọgbọ́n kan, tó ṣe bíi pé òun ya wèrè kó bàa lè bọ́ lọ́wọ́ wọn, síbẹ̀ ó mọ̀ dájú pé Jèhófà ló dìídì gba òun sílẹ̀ nípa bíbùkún ìsapá òun. Bí Dáfídì ṣe fi gbogbo ọkàn rẹ̀ gbára lé Jèhófà tó sì gbẹ́kẹ̀ lé e fi hàn pé lóòótọ́ ni Dáfídì bẹ̀rù Ọlọ́run.—Sáàmù 34:4-6, 9-11.
11 Bíi ti Dáfídì, àwa náà lè fi hàn pé a bẹ̀rù Ọlọ́run nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú ìlérí tó ṣe fún wa pé òun á ràn wá lọ́wọ́ láti borí àwọn ìṣòro wa. Dáfídì sọ pé: “Yí ọ̀nà rẹ lọ sọ́dọ̀ Jèhófà, kí o sì gbójú lé e, òun yóò sì gbé ìgbésẹ̀.” (Sáàmù 37:5) Èyí ò túmọ̀ sí pé ká kàn kó gbogbo ìṣòro wa lé Jèhófà lọ́wọ́ láìṣe ohun tó yẹ ká ṣe o, ká wá máa retí pé Jèhófà yóò bá wa yanjú àwọn ìṣòro náà. Kì í ṣe pé Dáfídì kàn gbàdúrà sí Ọlọ́run fún ìrànwọ́ lásán tó sì wá fi ọ̀ràn náà sílẹ̀ bẹ́ẹ̀ láìṣe ohunkóhun. Ó lo ọpọlọ tí Jèhófà fún un láti borí ìṣòro rẹ̀ lákòókò yẹn. Síbẹ̀, Dáfídì mọ̀ pé ìsapá èèyàn nìkan kò lè mú àṣeyọrí wá. Ohun tó yẹ káwa náà mọ̀ nìyẹn. Lẹ́yìn tá a bá ti ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe, a gbọ́dọ̀ fi èyí tó kù sílẹ̀ fún Jèhófà. Kódà, ọ̀pọ̀ ìgbà ní kì í sí ohunkóhun tá a lè ṣe ju pé ká gbára lé Jèhófà. Irú àkókò yìí gan-an la máa ń fi hàn pé lóòótọ́ la bẹ̀rù Ọlọ́run. A lè rí ìtùnú látinú ọ̀rọ̀ tí Dáfídì sọ látọkànwá pé: “Ìbárẹ́ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà jẹ́ ti àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀.”—Sáàmù 25:14.
Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”
9 Jèhófà tún mọrírì ìfaradà wa pẹ̀lú. (Mátíù 24:13) Rántí o, ńṣe ni Sátánì ń fẹ́ kó o kẹ̀yìn sí Jèhófà. Ọjọ́ kọ̀ọ̀kan tó o bá jẹ́ adúróṣinṣin lójú Jèhófà, ṣe lò ń jẹ́ kó túbọ̀ ṣeé ṣe láti fún Sátánì lésì gbogbo ìṣáátá rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn. (Òwe 27:11) Nígbà mìíràn, ìfaradà kì í rọrùn. Àìlera, àìrówó-gbọ́-bùkátà, másùnmáwo àtàwọn òkè ìṣòro mìíràn lè mú kí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan má rọgbọ rárá. Ìrẹ̀wẹ̀sì tún lè dé, bí ọ̀nà ò bá gba ibi téèyàn fojú sí. (Òwe 13:12) Ìfaradà wa lójú gbogbo irú ìṣòro wọ̀nyẹn ṣeyebíye lójú Jèhófà. Ìdí nìyẹn tí Dáfídì Ọba fi sọ pé kí Jèhófà fi omijé òun sínú “ìgò awọ” kan, tó sì fi kún un pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Wọn kò ha sí nínú ìwé rẹ?” (Sáàmù 56:8) Bẹ́ẹ̀ ni o, Jèhófà kò jẹ́ gbàgbé, kò sì jẹ́ fojú kékeré wo gbogbo omijé àti ìyà tó ń jẹ wá bá a ṣe ń pa ìwà títọ́ mọ́ sí i. Gbogbo rẹ̀ ló ṣe iyebíye lójú rẹ̀ pẹ̀lú.
Bí Ìfẹ́ Ṣe Lè Jẹ́ Ká Borí Ìbẹ̀rù
16 Sátánì mọ̀ pé a ò fẹ́ kú. Ó sọ pé tá ò bá fẹ́ kú, gbogbo nǹkan la máa yááfì títí kan àjọṣe tá a ní pẹ̀lú Jèhófà. (Jóòbù 2:4, 5) Ẹ ò rí i pé onírọ́ ni Sátánì! Síbẹ̀, torí pé Sátánì ni “ẹni tó lè fa ikú,” ó máa ń fìyẹn dẹ́rù bà wá ká lè fi Jèhófà sílẹ̀. (Héb. 2:14, 15) Nígbà míì, àwọn tí Sátánì ń lò máa ń halẹ̀ mọ́ wa pé ká sọ pé a ò sin Jèhófà mọ́, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, àwọn máa pa wá. Láwọn ìgbà míì sì rèé, Sátánì máa ń lo àìsàn tó lè la ikú lọ láti mú ká ṣe ohun tí inú Jèhófà ò dùn sí. Àwọn dókítà tàbí àwọn mọ̀lẹ́bí tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè fúngun mọ́ wa pé ká gba ẹ̀jẹ̀, ìyẹn sì máa ta ko òfin Ọlọ́run. Yàtọ̀ síyẹn, ẹnì kan lè sọ fún wa pé ká gba ìtọ́jú tó lòdì sí ohun tí Bíbélì sọ.
17 Òótọ́ ni pé a ò fẹ́ kú, ṣùgbọ́n a mọ̀ pé Jèhófà á ṣì máa nífẹ̀ẹ́ wa tá a bá tiẹ̀ kú. (Ka Róòmù 8:37-39.) Táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà bá kú, ó ṣì máa ń rántí wọn bíi pé wọ́n wà láàyè. (Lúùkù 20:37, 38) Ó ń fojú sọ́nà fún ìgbà tó máa jí wọn dìde. (Jóòbù 14:15) Nǹkan ńlá ni Jèhófà san ká “lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòh. 3:16) A mọ̀ pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa gan-an, ó sì ń bójú tó wa. Torí náà, dípò ká pa òfin Jèhófà tì nígbà tá a bá ṣàìsàn tó lè gbẹ̀mí wa tàbí nígbà táwọn kan bá halẹ̀ mọ́ wa pé àwọn máa pa wá, ẹ jẹ́ ká bẹ Jèhófà pé kó tù wá nínú, kó sì fún wa lọ́gbọ́n àti okun tá a nílò. Ohun tí Valérie àti ọkọ ẹ̀ ṣe gan-an nìyẹn.—Sm. 41:3.
Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
it-1 857-858
Mímọ Ọjọ́ Ọ̀la, Kádàrá
Bí Júdásì Ìsìkáríọ́tù ṣe da Jésù mú àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ṣẹ, ó sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà àti Jésù ọmọ ẹ̀ lágbára láti mọ ohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú. (Sm 41:9; 55:12, 13; 109:8; Iṣe 1:16-20) Àmọ́ ìyẹn ò túmọ̀ sí pé Ọlọ́run ti kádàrá tàbí pinnu pé Júdásì gan-an ni nǹkan náà máa ṣẹlẹ̀ sí. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ẹni tó bá sún mọ́ Jésù pẹ́kípẹ́kí ló máa dà á, àmọ́ kò sọ ẹni náà ní pàtó. Àwọn ìlànà tó wà nínú Bíbélì jẹ́ ká rí i pé, Ọlọ́run kọ́ ló pinnu ìwà tí Júdásì máa hù. Ìlànà tí Ọlọ́run mí sí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù láti kọ ni pé: “Má fi ìkánjú gbé ọwọ́ lé ọkùnrin èyíkéyìí láé; má sì pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ àwọn ẹlòmíì; jẹ́ oníwà mímọ́.” (1Ti 5:22; fi wé 3:6.) Gbogbo òru ni Jésù fi gbàdúrà sí Bàbá rẹ̀ kó tó yan àwọn àpọ́sítélì méjìlá (12), ìdí tó fi ṣe bẹ́ẹ̀ ni pé kò fẹ́ ṣàṣìṣe nínú àwọn tó fẹ́ yàn. (Lk 6:12-16) Tó bá wá jẹ́ pé Jèhófà ti kádàrá pé Júdásì ló máa da Jésù, ìyẹn á fi hàn pé ìtọ́sọ́nà tó fún Jésù kò péye. Bákan náà, bó ṣe wà nínú ìlànà tó mí sí Pọ́ọ̀lù láti kọ, òun náà ti pín nínú ẹ̀ṣẹ̀ Júdásì nìyẹn.
Nígbà tí Jésù yan Júdásì, kò sí ẹ̀rí kankan tó fi hàn pé òun ló máa da Jésù. Àmọ́, nígbà tó yá ó jẹ́ kí ‘gbòǹgbò tó ní májèlé rú yọ’ kó sì sọ ọ́ di ẹlẹ́gbin. Kò tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà, kàkà bẹ́ẹ̀ ṣe ló fàyè gba èṣù, ìyẹn mú kó máa jalè, nígbẹ̀yìngbẹ́yín ó da lẹ̀ Jésù. (Heb 12:14, 15; Jo 13:2; Iṣe 1:24, 25; Jem 1:14, 15; wo JÚDÁSÌ No. 4.) Nígbà tí Jésù kíyè sí i pé ọwọ́ Júdásì ò mọ́, ìgbà yẹn ni Jésù wá mọ̀ pé Júdásì ló máa da òun, ó sì sọ tẹ́lẹ̀ nípa ẹ̀.—Jo 13:10, 11.