ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 July ojú ìwé 3
  • July 8-14

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 8-14
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 July ojú ìwé 3

JULY 8-14

SÁÀMÙ 60-62

Orin 2 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

Àwòrán: 1. Ọkùnrin kan sá lọ sí ilé gogoro kan. 2. Ọkùnrin kan rẹ́rìn-ín múṣẹ́, ó sì nawọ́ sí àgọ́ rẹ̀ níbi táwọn àlejò ti ń jẹun. 3. Àpáta ńlá kan.

1. Jèhófà Ń Dáàbò Bò Wá, Ó sì Ń Fẹsẹ̀ Wa Múlẹ̀

(10 min.)

Jèhófà dà bí ilé gogoro tó lágbára (Sm 61:3; it-2 1118 ¶7)

Jèhófà gbà wá lálejò nínú àgọ́ rẹ̀ (Sm 61:4; it-2 1084 ¶8)

Jèhófà dà bí àpáta ńlá kan (Sm 62:2; w02 4/15 16 ¶14)


BI ARA RẸ PÉ, ‘Torí pé mo mọ Jèhófà, tí mo sì gbẹ́kẹ̀ lé e, báwo nìyẹn ṣe mú káyé mi túbọ̀ dáa sí i?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 62:11—Kí nìdí tí onísáàmù náà fi sọ pé “agbára jẹ́ ti Ọlọ́run”? (w06 6/1 11 ¶7)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 60:1–61:8 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Lẹ́yìn tẹ́nì kan ràn ẹ́ lọ́wọ́, bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ pẹ̀lú ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Sọ fún ẹni náà nípa JW Library®, kó o sì fi bó ṣe lè wà á sórí fóònù ẹ̀ hàn án. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) w22.02 4-5 ¶7-10—Àkòrí: Fọkàn Tán Jèhófà Tí Ètò Rẹ̀ Bá Ní Ká Ṣe Ohun Kan. (th ẹ̀kọ́ 20)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 12

7. Kò Sóhun Tó Lè “Yà Wá Kúrò Nínú Ìfẹ́ Ọlọ́run”

(10 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Àwọn ọ̀nà wo ní pàtó ni Jèhófà gbà bójú tó Arákùnrin Nyirenda lásìkò tí wọ́n ṣe inúnibíni sí i?

8. Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Ohun Tó Yẹ Kó O Ṣe Kó O Tó Ṣèrìbọmi

(5 min.) Ìjíròrò. Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé mélòó kan wá sórí pèpéle kó o sì bi wọ́n pé: Tó o bá fẹ́ ṣèrìbọmi, kí ló yẹ kó o fi sọ́kàn tó ṣe pàtàkì ju ọjọ́ orí ẹ lọ? Àwọn nǹkan wo ló yẹ kó o ṣe kó o tó ṣèrìbọmi?

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 12 ¶7-13, àpótí ojú ìwé 97

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 63 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́