ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 July ojú ìwé 6-7
  • July 22-28

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 22-28
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 July ojú ìwé 6-7

JULY 22-28

SÁÀMÙ 66-68

Orin 7 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Jèhófà Ń Bá Wa Gbé Ẹrù Wa Lójoojúmọ́

(10 min.)

Jèhófà máa ń tẹ́tí sí àdúrà wa, ó sì máa ń dáhùn rẹ̀ (Sm 66:19; w23.05 12 ¶15)

Jèhófà ò fọ̀rọ̀ àwọn tí nǹkan ò rọrùn fún ṣeré, ó sì ṣe tán láti pèsè ohun tí wọ́n nílò (Sm 68:5; w10 12/1 23 ¶6; w09 4/1 31 ¶1)

Ojoojúmọ́ ni Jèhófà ń ràn wá lọ́wọ́ (Sm 68:19; w23.01 19 ¶17)

Àwòrán: Arábìnrin kan gbàdúrà jálẹ̀ ọjọ́ kan. 1. Tó bá jí láàárọ̀. 2. Kó tó kó àwọn ọmọ ẹ̀ lọ sílé ìwé. 3. Níbi iṣẹ́.

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Báwo ni Jèhófà ṣe ń bá wa gbé ẹrù wa?

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 68:18—Ní Ísírẹ́lì àtijọ́, àwọn wo ni “ẹ̀bùn tí ó jẹ́ èèyàn”? (w06 6/1 10 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 66:1-20 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Àṣà ìbílẹ̀ ẹni náà yàtọ̀ sí tìẹ. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Máa bá ìjíròrò rẹ lọ nínú ìwé ìléwọ́ tó o fún ẹni náà nígbà tó o kọ́kọ́ wàásù fún un. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 3)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) lff ẹ̀kọ́ 15 ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ àti kókó 1-3 (th ẹ̀kọ́ 8)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 102

7. Ṣé O Lè Mú Kí Ẹrù Ẹnì Kan Fúyẹ́?

(15 min.) Ìjíròrò.

Kò yẹ kí ìránṣẹ́ Jèhófà èyíkéyìí dá fàyà rán ìṣòro ẹ̀. (2Kr 20:15; Sm 127:1) Ìdí ni pé Jèhófà ni Olùrànlọ́wọ́ wa. (Ais 41:10) Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà máa ń gbà ràn wá lọ́wọ́? Ó máa ń fi Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ètò rẹ̀ tọ́ wa sọ́nà. (Ais 48:17) Ó máa ń fún wa ní ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀. (Lk 11:13) Ó tún máa ń lo àwọn ará wa láti ràn wá lọ́wọ́ kí wọ́n sì fún wa níṣìírí. (2Kọ 7:6) Èyí fi hàn pé Jèhófà lè lo ẹnikẹ́ni nínú wa láti mú kí ẹrù àwọn ará wa fúyẹ́.

Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn​—Àgbàlagbà.” Arábìnrin Paulina Sántiz Gómez ń rẹ́rìn-ín bó ṣe dúró síta ilé rẹ̀.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Àgbàlagbà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn Kristẹni tó jẹ́ àgbàlagbà lè fúyẹ́?

Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn​—Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún.” Joseph àti Anita DeVito jọ ń ṣiṣẹ́ lóde ìwàásù.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Òjíṣẹ́ Alákòókò Kíkún. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún lè fúyẹ́?

Apá kan nínú fídíò “Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn​—Àjèjì.” Bill àti Maggie Zeng ń rẹ́rìn-ín músẹ́ bí wọ́n ṣe ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Fi Ìfẹ́ Tí Kì Í Yẹ̀ Hàn Sáwọn—Àjèjì. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo lè ṣe kí ẹrù àwọn tó ń kojú ìṣòro tó lágbára lè fúyẹ́?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 13 ¶1-7, ọ̀rọ̀ ìbẹ̀rẹ̀ apá 5 àti àpótí ojú ìwé 103

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 88 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́