ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 September ojú ìwé 8-9
  • September 30–October 6

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • September 30–October 6
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 September ojú ìwé 8-9

SEPTEMBER 30–OCTOBER 6

SÁÀMÙ 90-91

Orin 140 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà, Tó O Bá Fẹ́ Kí Ẹ̀mí Ẹ Gùn

(10 min.)

Kò sóhun táwa èèyàn lè ṣe láti mú kí ẹ̀mí wa gùn sí i (Sm 90:10; wp19.3 5 ¶2-4)

Jèhófà ti wà “láti ayérayé dé ayérayé” (Sm 90:2; wp19.1 5, àpótí)

Ó lágbára láti fún àwọn tó bá gbẹ́kẹ̀ lé e ní ìyè àìnípẹ̀kun, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀ (Sm 21:4; 91:16)

Dókítà kan ń fún arákùnrin kan tó wà nílé ìwòsàn ní bébà àti báírò ní òru.

Má ṣe gba ìtọ́jú tó ta ko ìlànà Bíbélì, torí ìyẹn lè ba àjọṣe ìwọ àti Jèhófà jẹ́.—w22.06 18 ¶16-17.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 91:11—Kí ló yẹ ká fi sọ́kàn nípa báwọn áńgẹ́lì ṣe ń ràn wá lọ́wọ́? (wp17.5 5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 91:1-16 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Láì kọ́kọ́ sọ̀rọ̀ nípa Bíbélì, máa bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ títí wàá fi mọ ohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, kó o lè mọ ìmọ̀ràn Bíbélì tó o lè fi ràn án lọ́wọ́. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 3)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) lmd àfikún A kókó 5—Àkòrí: Àwọn Èèyàn Á Máa Gbé Ayé Títí Láé. (th ẹ̀kọ́ 14)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 158

7. Ṣé O Mọyì Bí Sùúrù Ọlọ́run Ṣe Pọ̀ Tó?—Ojú Tí Jèhófà Fi Ń Wo Àkókò

(5 min.) Ìjíròrò.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Tá a bá ronú lórí bí Jèhófà ṣe ń fi sùúrù ṣe nǹkan lákòókò tó yẹ, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká lè máa fi sùúrù dúró títí táá fi mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ?

Àwọn kan wà lórí òkè, wọ́n sì ń wo ìràwọ̀ tó kún ojú ọ̀run.

8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù September

(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.

9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 16 ¶1-5, àpótí ojú ìwé 128

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 68 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́