ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 November ojú ìwé 10-11
  • December 16-22

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December 16-22
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 November ojú ìwé 10-11

DECEMBER 16-22

SÁÀMÙ 119:57-120

Orin 129 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ohun Táá Jẹ́ Kó O Lè Fara Da Ìṣòro Ẹ

(10 min.)

Máa ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run déédéé, kó o sì máa kẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ (Sm 119:61; w06 6/15 20 ¶2; w00 12/1 14 ¶3)

Kẹ́kọ̀ọ́ látinú ìṣòro tó o ní (Sm 119:71; w06 9/1 14 ¶4)

Jẹ́ kí Jèhófà tù ẹ́ nínú (Sm 119:76; w17.07 13 ¶3, 5)

Arákùnrin kan tí ara ẹ̀ ò yá ń gbàdúrà pẹ̀lú ìyàwó ẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn ọ̀nà pàtó wo ni Jèhófà ti gbà ràn mí lọ́wọ́ kí n lè fara da ìṣòro mi?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 119:96—Kí ló ṣeé ṣe kí ẹsẹ Bíbélì yìí túmọ̀ sí? (w06 9/1 14 ¶5)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 119:57-80 (th ẹ̀kọ́ 12)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkànnì wa han ẹni náà, kó o sì fún un ní káàdì ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sí àsọyé fún gbogbo èèyàn tẹ́ ẹ máa gbọ́ lọ́sẹ̀ yẹn. Fi fídíò Kí Ló Máa Ń Ṣẹlẹ̀ Nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba? hàn án, kẹ́ ẹ sì jíròrò ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́

(5 min.) Àṣefihàn. ijwbq 157—Àkòrí: Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Àwọn Àjálù Tó Ń Ṣẹlẹ̀? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 128

7. Jèhófà Máa Ń Ràn Wá Lọ́wọ́ Ká Lè Fara Da Ìṣòro Wa

(15 min.) Ìjíròrò.

Ìfaradà túmọ̀ sí kéèyàn forí ti ìṣòro kan, kó sì là á já láì bọ́hùn. Ó gba pé kéèyàn jẹ́ olóòótọ́ sí Jèhófà nígbà ìṣòro, kó ní èrò tó tọ́, kó sì nírètí pé nǹkan ń bọ̀ wá dáa. Tá a bá ní ìfaradà, a ò ní “fà sẹ́yìn” tàbí dẹwọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn wa tí ìṣòro bá dé. (Heb 10:36-39) Ó ń wu Jèhófà láti ràn wá lọ́wọ́ ká lè fara da àwọn ìṣòro wa.—Heb 13:6.

Kọ bí Jèhófà ṣe máa ń ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro sí àlàfo tó wà lábẹ́ àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí.

  • Lk 11:13

  • Ro 8:25

  • 1Tẹ 5:11

  • Jem 1:5

Àwọn apá kan nínú fídíò “Máa Gbàdúrà Tọkàntọkàn Fáwọn Tó Wà Nínú Ìṣòro.” 1. Ìdílé Wilson ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú eré “Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà​—Máa Gbàdúrà fún Àwọn Ẹlòmí ì.” 2. Glynis ń gbàdúrà.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Máa Gbàdúrà Tọkàntọkàn Fáwọn Tó Wà Nínú Ìṣòro. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo ni ìkànnì jw.org ṣe lè jẹ́ ká mọ̀ nípa àwọn ará wa tó ń kojú ìṣòro?

  • Kí làwọn òbí lè ṣe kí wọ́n lè kọ́ àwọn ọmọ wọn láti máa gbàdúrà fáwọn míì, kí sì nìdí tó fi dáa kí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀?

  • Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká bẹ Jèhófà pé kó ran àwọn ará wa lọ́wọ́ láti fara dà á?

  • Tá a bá ń gbàdúrà fáwọn míì, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ ká lè fara da ìṣòro wa?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 19 ¶14-20, àpótí ojú ìwé 152

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 32 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́