ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb24 November ojú ìwé 12-13
  • December 23-29

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • December 23-29
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2024
mwb24 November ojú ìwé 12-13

DECEMBER 23-29

SÁÀMÙ 119:121-176

Orin 31 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Má Ṣe Kó Ẹ̀dùn Ọkàn Tí Ò Pọn Dandan Bá Ara Ẹ

(10 min.)

Nífẹ̀ẹ́ àwọn òfin Ọlọ́run (Sm 119:127; w18.06 17 ¶5-6)

Kórìíra ohun búburú (Sm 119:128; w93 4/15 17 ¶12)

Fetí sí Jèhófà kó o má bàa ṣe àṣìṣe tí “àwọn aláìmọ̀kan” máa ń ṣe (Sm 119:130, 133; Owe 22:3)

Bíbélì tá a ṣí sílẹ̀ wà nítòsí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ góòlù.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Àwọn àyípadà wo ní pàtó ló yẹ kí n ṣe kí n lè túbọ̀ nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, kí n sì kórìíra ohun búburú?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Sm 119:160—Bó ṣe wà nínú ẹsẹ yìí, kí ló yẹ kó dá wa lójú? (w23.01 2 ¶2)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Sm 119:121-152 (th ẹ̀kọ́ 2)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Jẹ́ kẹ́ni náà mọ bó ṣe lè rí àwọn ohun tó máa nífẹ̀ẹ́ sí lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 8 kókó 3)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) Bá ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sọ̀rọ̀ torí pé kì í wá sípàdé déédéé. (lmd ẹ̀kọ́ 12 kókó 4)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 121

7. Má Ṣe Jẹ́ Kí Owó Kó Ẹ sí Wàhálà Tí Ò Pọn Dandan

(15 min.) Ìjíròrò.

Àwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ owó tàbí tí wọ́n pinnu láti di ọlọ́rọ̀ máa ń “fi ìrora tó pọ̀ gún gbogbo ara wọn.” (1Ti 6:9, 10) Díẹ̀ rèé lára wàhálà àti ìrora tí ò pọn dandan téèyàn máa ń fà fúnra ẹ̀ tó bá nífẹ̀ẹ́ owó, tó sì ń lépa ẹ̀ lójú méjèèjì.

  • A ò ní ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Jèhófà.—Mt 6:24

  • A ò ní ní ìtẹ́lọ́rùn.—Onw 5:10

  • Ó máa ṣòro láti ṣe ohun tó tọ́ tá a bá kojú àwọn àdánwò tó lè mú ká parọ́, ká jalè tàbí ká ṣe màgòmágó. (Owe 28:20) Tá a bá hu àwọn ìwà àìṣòótọ́ yìí, ẹ̀rí ọkàn á bẹ̀rẹ̀ sí í dá wa lẹ́bi, a ò ní lórúkọ rere, a ò sì ní rí ojúure Jèhófà

Apá kan nínú fídíò “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.” Ọ̀dọ́kùnrin kan gbé kóló dání.

Ka Hébérù 13:5, kẹ́ ẹ sì dáhùn ìbéèrè yìí:

  • Kí ló yẹ ká ní tá ò bá fẹ́ kó sí wàhálà tí ìfẹ́ owó máa ń fà, kí sì nìdí?

Tá ò bá tiẹ̀ nífẹ̀ẹ́ owó, a ṣì lè kó ara wa sí wàhálà tá ò bá mọ bí wọ́n ṣe ń ṣọ́wó ná.

Jẹ́ káwọn ara wo ERÉ OJÚ PÁTÁKÓ náà, Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

    Apá kan nínú fídíò “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.” Ọ̀dọ́kùnrin kan àti ọ̀dọ́bìnrin kan kọ ohun tí wọ́n nílò àtohun tí wọ́n fẹ́, wọ́n wá kọ iye tí ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn jẹ́. Ohun tí ọ̀dọ́kùnrin náà kọ ni, ẹ̀rọ tí wọ́n fi ń gbọ́ orin, bàtà, oúnjẹ àti tíkẹ́ẹ̀tì ọkọ̀. Ohun tí ọ̀dọ́bìnrin náà kọ ni, apò kékeré, aago, oúnjẹ àti epo.
  • Kí nìdí tó fi yẹ kó o ṣètò bó o ṣe máa ná owó tó ń wọlé fún ẹ? Báwo lo ṣe lè ṣe é?

  • Apá kan nínú fídíò “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.” Ọ̀dọ́bìnrin kan ra agbòjò méjì bí òjò ṣe ń rọ̀. Òun lo ọ̀kan, ó sì fún àbúrò ẹ̀ tó fowó tiẹ̀ ra ìpápánu ní ìkejì.
  • Kí nìdí tó fi dáa kó o máa fowó pa mọ́?

  • Apá kan nínú fídíò “Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́wó Ná.” Ṣẹkẹ́ṣẹkẹ̀ wà lọ́wọ́ ọ̀dọ́kùnrin náà àti káàdì rẹ̀ torí pé ó jẹ gbèsè àmọ́ káàdì ẹ̀gbọ́n rẹ̀ obìnrin ń rẹ́rìn-ín torí pé kò jẹ gbèsè.
  • Kí nìdí tí kò fi yẹ ká máa tọrùn bọ gbèsè?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 20 ¶1-7, àti ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 7

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 101 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́