ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 March ojú ìwé 2-16
  • March 3-9

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • March 3-9
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 March ojú ìwé 2-16

MARCH 3-9

ÒWE 3

Orin 8 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Fi Hàn Pé O Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà

(10 min.)

Jèhófà ni kó o gbẹ́kẹ̀ lé dípò ara rẹ (Owe 3:5; w11 11/15 6 ¶2-3)

Tó o bá ń wá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, tó o sì ń tẹ̀ lé e, ìyẹn á fi hàn pé o gbẹ́kẹ̀ lé e (Owe 3:6; w03 9/1 13 ¶22-23)

Má ṣe dá ara ẹ lójú jù (Owe 3:7; be 76 ¶4)

Ọ̀dọ́bìnrin kan ń fi fóònù ẹ̀ ṣèwádìí nípa ohun tó máa fi ayé ẹ̀ ṣe lọ́jọ́ iwájú. Àwọn ìwé tó sọ̀rọ̀ nípa ilé ẹ̀kọ́ yunifásítì wà lápá òsì, fọ́ọ̀mù tó fi lè ṣe púpọ̀ sí i lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Jèhófà àti ìsọfúnni nípa Bẹ́tẹ́lì wà lápá ọ̀tún rẹ̀.

BI ARA RẸ PÉ, ‘Ṣé mo máa ń jẹ́ kí Jèhófà tọ́ mi sọ́nà ní gbogbo apá ìgbésí ayé mi?’

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 3:3—Kí ló túmọ̀ sí láti so ìfẹ́ tí kì í yẹ̀ àti ìṣòtítọ́ mọ́ ọrùn wa, ká sì kọ wọ́n sí wàláà ọkàn wa? (w06 9/15 17 ¶7)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 3:1-18 (th ẹ̀kọ́ 12)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Wàásù fún ẹnì kan tó sọ ohun táwọn èèyàn sábà máa ń sọ tí wọn ò bá fẹ́ gbọ́ ìwàásù. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Sọ fún ẹni náà nípa ìkànnì wa, kó o sì fún un ní káàdì ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

6. Àsọyé

(5 min.) w11 3/15 14 ¶7-10—Àkòrí: Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà Táwọn Èèyàn Ò Bá Fẹ́ Gbọ́rọ̀ Ẹ. (th ẹ̀kọ́ 20)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 124

7. Fi Hàn Pé O Fọkàn Tán Ètò Ọlọ́run

(15 min.) Ìjíròrò.

Ó máa ń rọrùn láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tá a bá rí nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àmọ́, ó lè ṣòro láti tẹ̀ lé ìtọ́sọ́nà tó bá wá látọ̀dọ̀ àwọn èèyàn aláìpé tí Jèhófà ń lò láti bójú tó ètò rẹ̀, pàápàá tí ohun tí wọ́n bá ní ká ṣe ò bá yé wa tàbí kò tẹ́ wa lọ́rùn.

Ka Málákì 2:7. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tí kò fi yà wá lẹ́nu pé Jèhófà máa ń lo àwọn èèyàn aláìpé láti bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀?

Ka Mátíù 24:45. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká fọkàn tán ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ?

Ka Hébérù 13:17. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ ká máa ṣègbọràn sí àwọn tí Jèhófà yàn láti máa bójú tó wa?

Arákùnrin kan gbé oúnjẹ lọ fún ìdílé kan. Gbogbo wọn lo ìbòmú, wọ́n sì ń juwọ́ látọ̀ọ́kán.
Arábìnrin kan ń dáhùn nípàdé. Arákùnrin kan gbé makirofóònù sí i lẹ́nu. Gbogbo àwọn tó wà nípàdé náà lo ìbòmú.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ìròyìn Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí ti Ọdún 2021 #9—Àyọlò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Báwo làwọn ohun tí wọ́n ní ká ṣe lásìkò àjàkálẹ̀ àrùn Kòrónà ṣe mú kó o túbọ̀ fọkàn tán ètò Ọlọ́run?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 23 ¶9-15, àwọn àpótí ojú ìwé 184 àti 186

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 57 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́