MARCH 10-16
ÒWE 4
Orin 36 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
Àwọn aṣọ́bodè ń sáré ti ilẹ̀kùn nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn ọ̀tá ń bọ̀
1. “Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ”
(10 min.)
Ọ̀rọ̀ náà “ọkàn” túmọ̀ sí ẹni tá a jẹ́ nínú lọ́hùn-ún (Sm 51:6; w19.01 15 ¶4)
Ó ṣe pàtàkì gan-an pé ká dáàbò bò ó(Owe 4:23a; w19.01 17 ¶10-11; 18 ¶14; wo àwòrán)
Irú ẹni tá a bá jẹ́ nínú lọ́hùn-ún ló máa pinnu bóyá a máa rí ìyè (Owe 4:23b; w12 5/1 32 ¶2)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 4:18—Báwo la ṣe lè lo ẹsẹ Bíbélì yìí láti ṣàlàyé bí Kristẹni kan ṣe máa ń ṣe àyípadà nígbèésí ayé ẹ̀ kó lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà? (w21.08 8 ¶4)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 4:1-18 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà fẹ́ mọ̀ sí i lẹ́yìn tó o fún un níwèé tá a fi ń pe àwọn èèyàn wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹnì kan tó o mọ̀ wá sí Ìrántí Ikú Kristi. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 19—Àkòrí: Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Ṣayẹyẹ Ọdún Àjíǹde? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
Orin 16
7. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù March
(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
8. A Máa Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Pe Àwọn Èèyàn sí Ìrántí Ikú Kristi ní Saturday, March 15
(5 min.) Alábòójútó iṣẹ́ ìsìn ni kó sọ àsọyé yìí. Sọ ètò tí ìjọ ṣe láti pe àwọn èèyàn wá sí àkànṣe àsọyé àti Ìrántí Ikú Kristi, kó o sì sọ àwọn ètò míì tó wà nílẹ̀. Gba àwọn ará níyànjú láti fi kún ohun tí wọ́n ń ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lóṣù March àti April.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 23 ¶16-19, àpótí ojú ìwé 188