MAY 12-18
ÒWE 13
Orin 34 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Jẹ́ Kí “Fìtílà Àwọn Ẹni Burúkú” Tàn Ẹ́ Jẹ
(10 min.)
Àwọn èèyàn burúkú ò nírètí ọjọ́ iwájú (Owe 13:9; it-2 196 ¶2-3)
Yẹra fún àwọn tó ń fi nǹkan búburú ṣayọ̀ (Owe 13:20; w12 7/15 12 ¶3)
Jèhófà máa ń bù kún àwọn olódodo (Owe 13:25; w04 7/15 31 ¶6)
Ó máa ń dà bíi pé àwọn tó ń lépa àwọn nǹkan ayé yìí ń gbádùn ara wọn, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Àwọn tó ń sin Jèhófà ló máa ń ní ayọ̀ tòótọ́
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 13:24—Ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì yìí fún wa tó bá dọ̀rọ̀ bíbá ọmọ wí? (it-2 276 ¶2)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 13:1-17 (th ẹ̀kọ́ 10)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ohun kan tó ṣẹlẹ̀ ládùúgbò yín bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ, lẹ́yìn náà fi ohun kan hàn án nínú Bíbélì tó máa nífẹ̀ẹ́ sí. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Pe ẹni náà wá sípàdé. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) lmd àfikún A kókó 9—Àkòrí: Táwọn Ọmọ Bá Ń Bọ̀wọ̀ Fáwọn Òbí Wọn Tí Wọ́n sì Jẹ́ Onígbọràn, Nǹkan Á Máa Lọ Dáadáa fún Wọn. (th ẹ̀kọ́ 16)
Orin 77
7. “Ìmọ́lẹ̀ Àwọn Olódodo Mọ́lẹ̀ Rekete”
(8 min.) Ìjíròrò.
Ìmọ̀ àti ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kò láfiwé. Tá a bá ń fi ohun tá a kọ́ nínú ẹ̀ sílò, a máa ní ayọ̀ tòótọ́, ìgbésí ayé wa sì máa nítumọ̀. Ayé Sátánì ò lè fún wa láwọn nǹkan yìí láé.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ayé Yìí Ò Lè Fún Ẹ Ní Ohun Tí Kò Ní. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Báwo ni ìrírí Arábìnrin Gainanshina ṣe jẹ́ ká rí i pé “ìmọ́lẹ̀ àwọn olódodo” dáa ju “fìtílà àwọn ẹni burúkú” lọ?—Owe 13:9
Má ṣe máa ronú nípa àwọn nǹkan tó wà nínú ayé tàbí kó o máa kábàámọ̀ àwọn ìpinnu tó o ṣe tó jẹ́ kó o lè máa ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. (1Jo 2:15-17) Kàkà bẹ́ẹ̀, ‘ìmọ̀ tó ṣeyebíye ju ohun gbogbo lọ’ tó o ní ni kó o gbájú mọ́.—Flp 3:8.
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(7 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 26 ¶9-17