ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 May ojú ìwé 6-7
  • May 19-25

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • May 19-25
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 May ojú ìwé 6-7

MAY 19-25

ÒWE 14

Orin 89 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Ronú Jinlẹ̀ Kó O Tó Gbé Ìgbésẹ̀ Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀

(10 min.)

Má ṣe gba “gbogbo ọ̀rọ̀” gbọ́ (Owe 14:15; w23.02 22-23 ¶10-12)

Má ṣe gbára lé òye ara ẹ tàbí ìrírí tó o ní (Owe 14:12)

Má ṣe máa tẹ́tí sí àwọn tí kì í tẹ̀ lé ohun tí ètò Jèhófà bá sọ (Owe 14:7)

Ìdílé kan ń wo ètò tẹlifíṣọ̀n JW.

RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Ẹ̀yin alàgbà, ṣẹ́ ẹ múra tán láti ṣé ohun tí ètò Ọlọ́run bá sọ, kẹ́ ẹ sì gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀?—w24.07 5 ¶11.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 14:17—Kí ló ṣeé ṣe kó fà á táwọn èèyàn fi máa ń kórìíra “ẹni tó bá ń ro ọ̀rọ̀ wò”? (it-2 1094)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 14:1-21 (th ẹ̀kọ́ 11)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Ẹnì kan sọ fún ẹ nípa bí ọ̀rọ̀ àtijẹ-àtimu ṣe ṣòro tó, fi Bíbélì tù ú nínú. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)

5. Pa Dà Lọ

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fún ẹnì kan ní ìwé ìròyìn tó dá lórí ohun tó o kíyè sí pé ó nífẹ̀ẹ́ sí nígbà tẹ́ ẹ jọ sọ̀rọ̀ kẹ́yìn. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 4)

6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn

(5 min.) Gba ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ níyànjú pé kó máa ka Bíbélì lójoojúmọ́, kó o sì jẹ́ kó mọ bó ṣe lè ṣe é. (th ẹ̀kọ́ 19)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 126

7. Múra Sílẹ̀ fún Àjálù

(15 min.) Ìjíròrò.

Alàgbà ni kó ṣe iṣẹ́ yìí. Mẹ́nu kan àwọn ìtọ́ni tí ẹ̀ka ọ́fíìsì ti fún yín àtèyí tí ìgbìmọ̀ àwọn alàgbà fohùn ṣọ̀kan lé lórí, ìyẹn tó bá wà.

A mọ̀ pé ìṣòro á máa pọ̀ sí i ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” yìí. (2Ti 3:1; àlàyé ọ̀rọ̀ lórí Mt 24:8, nwtsty) Kí àjálù tó ṣẹlẹ̀ àti nígbà tí àjálù bá ṣẹlẹ̀, àwa èèyàn Jèhófà máa ń gba ìtọ́ni tó lè gba ẹ̀mí wa là. Torí náà, tá a bá fẹ́ là á já, ó yẹ ká máa ṣe àwọn nǹkan táá mú kí ìgbàgbọ́ wa túbọ̀ lágbára, ká sì ṣètò àwọn nǹkan tá a máa nílò tí àjálù bá ṣẹlẹ̀.—Owe 14:6, 8.

  • Mú kí ìgbàgbọ́ ẹ túbọ̀ lágbára: Jẹ́ kó mọ́ ẹ lára láti máa ka Bíbélì, kó o sì máa dá kẹ́kọ̀ọ́. Túbọ̀ já fáfá nínú oríṣiríṣi ọ̀nà tá à ń gbà wàásù. Má bẹ̀rù tó bá ṣẹlẹ̀ pé o ò mọ ibi táwọn ará tó kù nínú ìjọ wà. (Owe 14:30) Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé o ò dá wà, Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi wà pẹ̀lú ẹ.—od 176 ¶15-17

  • Ṣètò àwọn nǹkan tó o máa nílò: Yàtọ̀ sí báàgì pàjáwìrì, ó yẹ kí ìdílé kọ̀ọ̀kan ní oúnjẹ, omi, oògùn àtàwọn nǹkan míì tẹ́ ẹ máa nílò tó bá ṣẹlẹ̀ pé ẹ ò ní lè kúrò nílé fáwọn àkókò kan.—Owe 22:3; g17.5 4

Ìdílé tó wà nínú àwòrán àkọ́kọ́ ń ṣètò báàgì pàjáwìrì wọn.

Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣé O Ti Múra Sílẹ̀ De Àjálù? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Ọ̀nà wo ni Jèhófà ń gbà ràn wá lọ́wọ́ nígbà àjálù?

  • Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká ṣe ká lè múra sílẹ̀ fún àjálù?

  • Báwo la ṣe lè ran àwọn tí àjálù ṣẹlẹ̀ sí lọ́wọ́?

BI ARA RẸ PÉ:

‘Tí mo bá ronú nípa àwọn àjálù tó ń ṣẹlẹ̀ kárí ayé, kí ni mo rí kọ́ tó bá dọ̀rọ̀ kéèyàn múra sílẹ̀?’

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) bt orí 26 ¶18-22, àpótí tó wà lójú ìwé 209

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 116 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́