MAY 26–JUNE 1
ÒWE 15
Orin 102 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Máa Múnú Àwọn Míì Dùn
(10 min.)
Táwọn ará wa bá láwọn ìṣòro tó le gan-an, wọ́n lè ro ara wọn pin, kó sì máa ṣe wọ́n bíi pé wọn ò lè láyọ̀ mọ́ (Owe 15:15)
Máa gba àwọn tó níṣòro lálejò, kó o sì máa fìfẹ́ hàn sí wọn (Owe 15:17; w10 11/15 31 ¶16)
“Ẹ̀rín músẹ́” àti ọ̀rọ̀ ìṣírí tá a bá sọ lè tù wọ́n nínú (Owe 15:23, 30, àlàyé ìsàlẹ̀; w18.04 23-24 ¶16-18)
BI ARA RẸ PÉ: ‘Ta ni mo kíyè sí pé ó nílò ìṣírí nínú ìjọ? Kí ni mo lè ṣe láti ran ẹni náà lọ́wọ́?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 15:22—Báwo ni ìlànà Bíbélì yìí ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ìpinnu tó dáa tó bá kan ọ̀rọ̀ ìlera wa? (ijwbq àpilẹ̀kọ 39 ¶3)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 15:1-21 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 5)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Fún ẹni tó ò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì níṣìírí torí pé àwọn tó wà nínú ìdílé ẹ̀ ń ta kò ó. (th ẹ̀kọ́ 4)
Orin 155
7. A Lè Láyọ̀ Láìka Àwọn Ìṣòro Wa Sí
(15 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ A Lè Láyọ̀ Bá A Tiẹ̀ Ń Dojú Kọ Wàhálà, Ebi àti Ìhòòhò. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí lo rí kọ́ látinú àwọn ìrírí yìí?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 27 ¶1-9