JUNE 30–JULY 6
ÒWE 20
Orin 131 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Bó O Ṣe Lè Mọ̀ Bóyá Kó O Fẹ́ Ẹnì Kan Tàbí Kó O Má Fẹ́ Ẹ
(10 min.)
Máa tẹ̀ lé ìlànà Jèhófà lórí ọ̀rọ̀ ìfẹ́sọ́nà (Owe 20:24, 25; w24.05 26-27 ¶3-4)
Fara balẹ̀ kíyè sí ẹni náà kẹ́ ẹ tó bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ra yín sọ́nà (Owe 20:18; w24.05 22 ¶8)
Lo àkókò tẹ́ ẹ fi ń fẹ́ra sọ́nà láti mọ ẹni náà dáadáa (Owe 20:5; w24.05 28 ¶7-8)
RÁNTÍ PÉ: Àwọn tó ń fẹ́ra sọ́nà lè sọ pé àwọn ò fẹ́ra mọ́, ìyẹn ò sì burú torí pé ohun tí ìfẹ́sọ́nà wà fún ni pé kó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pinnu bóyá àwọn máa lè fẹ́ ẹni náà tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́.
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 20:27—Báwo ni ‘èémí èèyàn ṣe jẹ́ fìtílà Jèhófà’? (it-2 196 ¶7)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 20:1-15 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ẹni náà sọ fún ẹ pé òun ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣí wá sí orílẹ̀-èdè yìí ni. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Sọ fún ẹni náà nípa JW Library®, kó o sì bá a wà á sórí fóònù ẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(4 min.) Àṣefihàn. ijwbq àpilẹ̀kọ 159—Àkòrí: Ṣé Àwọn Ẹranko Ń Lọ sí Ọ̀run? (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 4)
Orin 78
7. Gbìyànjú Láti Máa Fi Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Lọ Àwọn Èèyàn
(5 min.) Ìjíròrò.
Apá pàtàkì kan nínú iṣẹ́ ìwàásù wa ni pé ká máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Tá ò bá kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kò sí bá a ṣe lè sọ wọ́n di ọmọ ẹ̀yìn. (Ro 10:13-15) O ò ṣe fi ṣe àfojúsùn ẹ láti máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni ní tààràtà nígbà tó o bá wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ilé-dé-ilé. Kí làwọn nǹkan tó o lè ṣe? Lákọ̀ọ́kọ́, kíyè sí ohun tẹ́ni náà nífẹ̀ẹ́ sí. Lẹ́yìn náà, fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì hàn án kó lè rí bí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà ṣe lè jẹ́ kó rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè ẹ̀, àti bó ṣe lè ràn án lọ́wọ́ nígbèésí ayé ẹ̀.
Máa lo ìlujá “Gbìyànjú Ẹ Wò” tó wà lórí jw.org láti máa fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ àwọn tó o bá pàdé.
Báwo lo ṣe lè lo ìlujá “Gbìyànjú Ẹ Wò” láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹnì kan?
Àwọn ọ̀nà wo lo ti rí i pé ó dáa jù lọ láti fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọni ládùúgbò ẹ?
8. Ohun Tí Ètò Ọlọ́run Ti Ṣe ti oṣù June
(10 min.) Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà.
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 28 ¶8-15