JULY 7-13
ÒWE 21
Orin 98 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Kí Tọkọtaya Láyọ̀
(10 min.)
Má ṣe kánjú ṣègbéyàwó (Owe 21:5; w03 10/15 4 ¶5)
Máa fìrẹ̀lẹ̀ yanjú èdèkòyédè tó bá wáyé (Owe 21:2, 4; g 7/08 7 ¶2)
Ẹ máa ní sùúrù fúnra yín, kẹ́ ẹ sì jẹ́ onínúure (Owe 21:19; w06 9/15 28 ¶13)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 21:31—Báwo ni ẹsẹ yìí ṣe jẹ́ kí àsọtẹ́lẹ̀ tó wà ní Ìfihàn 6:2 túbọ̀ yé wa? (w05 1/15 17 ¶9)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 21:1-18 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 3)
6. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 54—Àkòrí: Ojú Wo Làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Fi Ń Wo Ìkọ̀sílẹ̀? (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
Orin 132
7. Ẹ̀yin Tọkọtaya, Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ Fúnra Yín
(15 min.) Ìjíròrò.
Téèyàn bá ṣègbéyàwó, onítọ̀hún ti jẹ́jẹ̀ẹ́ níwájú Jèhófà pé òun á máa nífẹ̀ẹ́ ẹnì kejì òun, òun á sì máa bọ̀wọ̀ fún un. Torí náà, inú Jèhófà máa dùn tá a bá mú ẹ̀jẹ́ yìí ṣẹ, àmọ́ inú ẹ̀ ò ní dùn tá ò bá ṣe bẹ́ẹ̀.—Owe 20:25; 1Pe 3:7.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Tọkọtaya Aláyọ̀: Ẹ Máa Bọ̀wọ̀ Fúnra Yín. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Kí nìdí tó fi yẹ káwọn tọkọtaya máa bọ̀wọ̀ fún ara wọn?
Àwọn àyípadà wo ló lè pọn dandan pé ká ṣe ká lè túbọ̀ máa bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì wa?
Àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn wá lọ́wọ́?
Àwọn ọ̀nà pàtó wo la lè gbà fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún ẹnì kejì wa?
Àwọn nǹkan wo ló yẹ ká máa wò lára ẹnì kejì wa, kí sì nìdí?
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) bt orí 28 ¶16-22