ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • mwb25 July ojú ìwé 4-5
  • July 14-20

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • July 14-20
  • Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
Ìgbésí Ayé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Kristẹni—Ìwé Ìpàdé—2025
mwb25 July ojú ìwé 4-5

JULY 14-20

ÒWE 22

Orin 79 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)

ÀWỌN ÌṢÚRA INÚ Ọ̀RỌ̀ ỌLỌ́RUN

1. Àwọn Ìlànà Táá Jẹ́ Ká Lè Tọ́ Ọmọ Yanjú

(10 min.)

Jẹ́ káwọn ọmọ ẹ mọ̀ pé wọ́n máa kojú ìṣòro nígbèésí ayé (Owe 22:3; w20.10 27 ¶7)

Bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ wọn láti kékeré (Owe 22:6; w19.12 26 ¶17-19)

Máa fìfẹ́ bá wọn wí (Owe 22:15; w06 4/1 9 ¶4)

Bàbá kan ń fi Bíbélì tọ́ ọmọbìnrin ẹ̀ sọ́nà. Àwòrán táwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ẹfolúṣọ̀n máa ń lò wà lórí fóònù ẹ̀.

2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì

(10 min.)

  • Owe 22:29—Báwo la ṣe lè fi òwe yìí sílò nínú àwọn ohun tá à ń ṣe nínú ìjọ, àǹfààní wo la sì máa rí tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀? (w21.08 22 ¶11)

  • Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?

3. Bíbélì Kíkà

(4 min.) Owe 22:1-19 (th ẹ̀kọ́ 10)

TẸRA MỌ́ IṢẸ́ ÌWÀÁSÙ

4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. (lmd ẹ̀kọ́ 5 kókó 4)

5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa

(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà mọ bó ṣe lè rí ìsọfúnni tó máa ran àwọn òbí lọ́wọ́ lórí ìkànnì jw.org. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)

6. Àsọyé

(5 min.) ijwyp àpilẹ̀kọ 100—Àkòrí: Kí Ni Mo Lè Ṣe Tí Mo Bá Ṣàìgbọràn Sáwọn Òbí Mi? (th ẹ̀kọ́ 20)

MÁA HÙWÀ TÓ YẸ KRISTẸNI

Orin 134

7. Máa Ní Sùúrù àmọ́ Má Gbàgbàkugbà

(15 min.) Ìjíròrò.

Kéèyàn tó lè tọ́mọ yanjú, ó gbọ́dọ̀ ní sùúrù gan-an. Ó yẹ káwọn òbí máa wáyè fáwọn ọmọ wọn, kí wọ́n lè mọ̀ wọ́n dáadáa, kò sì yẹ káwọn òbí máa kánjú tí wọ́n bá wà pẹ̀lú wọn. (Di 6:6, 7) Káwọn òbí lè mọ ohun tó wà lọ́kàn àwọn ọmọ wọn, wọ́n gbọ́dọ̀ máa fọgbọ́n lo ìbéèrè, kí wọ́n sì tẹ́tí sáwọn ọmọ náà dáadáa. (Owe 20:5) Bákan náà, táwọn òbí bá ní káwọn ọmọ wọn ṣe nǹkan kan, ó lè gba pé kí wọ́n sọ ọ́ lọ́pọ̀ ìgbà kó tó lè yé àwọn ọmọ náà, kí wọ́n sì ṣe ohun táwọn òbí wọn sọ.

Àmọ́ ti pé òbí kan ní sùúrù, kò túmọ̀ sí pé kó gbàgbàkugbà. Jèhófà ti fún wọn láṣẹ láti fáwọn ọmọ wọn ní òfin, kí wọ́n sì bá wọn wí bó ṣe yẹ tí wọ́n bá ṣàìgbọràn.—Owe 6:20; 23:13.

Ka Éfésù 4:31. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tí kò fi yẹ káwọn òbí fìbínú bá àwọn ọmọ wọn wí?

Ka Gálátíà 6:7. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí nìdí tó fi yẹ káwọn òbí kọ́ àwọn ọmọ wọn pé kò sí ohun téèyàn ṣe tí kì í lẹ́yìn?

Apá kan nínú fídíò “ ‘Ẹ Ní Sùúrù, Kí Ẹ sì Máa Fara Dà Á fún Ara Yín Nínú Ìfẹ́’—Àwọn Ọmọ Rẹ.” Max ń tẹ́tí sí Sue, ọmọbìnrin ẹ̀.

Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ ‘Ẹ Ní Sùúrù, Kí Ẹ sì Máa Fara Dà Á fún Ara Yín Nínú Ìfẹ́’—Àwọn Ọmọ Rẹ. Lẹ́yìn náà, béèrè pé:

  • Kí lo rí kọ́ nínú fídíò yìí?

8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ

(30 min.) lfb “Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí,” ọ̀rọ̀ ìṣáájú fún apá 1, àti ẹ̀kọ́ 1

Ọ̀rọ̀ Ìparí (3 min.) | Orin 6 àti Àdúrà

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́