JULY 21-27
ÒWE 23
Orin 97 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Àwọn Ìlànà Tó Kan Ọ̀rọ̀ Ọtí Mímu
(10 min.)
Tó o bá pinnu láti mu ọtí, ṣọ́ra fún àmujù (Owe 23:20, 21; w04 12/1 19 ¶5-6)
Máa rántí ohun tí ọtí àmujù lè fà (Owe 23:29, 30, 33-35; w23.12 14 ¶4)
Má ṣe máa ronú pé ọtí ò lè ṣe ẹ́ ní nǹkan kan (Owe 23:31, 32)
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Owe 23:21—Kí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹni tó jẹ́ alájẹkì àti ẹni tó sanra jọ̀kọ̀tọ̀? (w04 11/1 31 ¶2)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Owe 23:1-24 (th ẹ̀kọ́ 5)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 5)
5. Pa Dà Lọ
(5 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi bá a ṣe ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì han ẹni náà. (lmd ẹ̀kọ́ 9 kókó 5)
6. Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn
(5 min.) Fún akẹ́kọ̀ọ́ ẹ níṣìírí bó ṣe ń sapá láti borí ìwà kan tí kò dáa. (lmd ẹ̀kọ́ 12 kókó 4)
Orin 35
7. Ṣé Kí N Pín Ọtí Tàbí Kí N Má Ṣe Bẹ́ẹ̀?
(8 min.) Ìjíròrò.
Ṣé ó yẹ kí ọtí wà níbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu irú bí ìgbéyàwó? Kálukú ló máa pinnu. Àmọ́ kẹ́nì kan tó ṣèpinnu, ó yẹ kó fara balẹ̀ ronú dáadáa nípa àwọn ìlànà Bíbélì kan àtàwọn nǹkan míì tó ṣe pàtàkì.
Jẹ́ káwọn ará wo FÍDÍÒ Ṣó Yẹ Kí N Fún Àwọn Èèyàn Ní Ọtí Níbi Ìgbéyàwó Mi? Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Tí ẹni tó pe àwọn èèyàn síbi àwẹ̀jẹ-àwẹ̀mu bá ronú lórí àwọn ìlànà Bíbélì yìí, báwo nìyẹn ṣe máa jẹ́ kó lè pinnu bóyá kóun pín ọtí tàbí kóun má ṣe bẹ́ẹ̀?
Jo 2:9—Jésù sọ omi di ọtí wáìnì níbi àsè ìgbéyàwó.
1Kọ 6:10—“Àwọn ọ̀mùtípara . . . kò ní jogún Ìjọba Ọlọ́run.”
1Kọ 10:31, 32—“Bóyá ẹ̀ ń jẹ tàbí ẹ̀ ń mu . . . , ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run. Ẹ máa ṣọ́ra kí ẹ má bàa di ohun ìkọ̀sẹ̀.”
Àwọn nǹkan wo ló tún yẹ kó o gbé yẹ̀ wò?
Tá a bá fẹ́ ṣe ìpinnu tó dáa, kí nìdí tó fi yẹ ká lo “agbára ìrònú” wa tá a bá ń gbé àwọn ìlànà Bíbélì ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yẹ̀ wò?—Ro 12:1; Onw 7:16-18
8. Ohun Tó Ń Fẹ́ Àbójútó Nínú Ìjọ
(7 min.)
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 2, ọ̀rọ̀ ìṣáájú fún apá 2, àti ẹ̀kọ́ 3