NOVEMBER 10-16
ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 3-5
Orin 31 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ìdí Tó Fi Yẹ Kó O Níwà Tó Dáa
(10 min.)
Àwọn ọ̀rọ̀ tí ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì máa ń sọ fi hàn pé ó níwà tó dáa (Sol 4:3, 11; w15 1/15 30 ¶8)
Ó tún sọ pé bí ọ̀dọ́bìnrin náà ṣe pa ara ẹ̀ mọ́ mú kó dà bí ọgbà tó ní ẹwà tó ṣàrà ọ̀tọ̀ (Sol 4:12; w00 11/1 11 ¶17)
Ó sàn kéèyàn níwà tó dáa ju pé kó kàn rẹwà, gbogbo wa la sì lè níwà tó dáa (g05 1/8 21 ¶1-4)
BI ARA Ẹ PÉ, ‘Àwọn ìwà wo ni mo fẹ́ràn jù lára àwọn míì?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sol 3:5—Kí nìdí tí ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì fi sọ pé kí àwọn “ọmọbìnrin Jerúsálẹ́mù . . . fi àwọn egbin àti àwọn abo àgbọ̀nrín inú pápá búra”? (w06 11/15 18 ¶4)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sol 4:1-16 (th ẹ̀kọ́ 2)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Fi ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ ẹni náà, kó o sì ṣàlàyé bá a ṣe ń ṣe é. (lmd ẹ̀kọ́ 6 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Jẹ́ kí ẹni náà rí bó ṣe lè wá àwọn nǹkan tó fẹ́ mọ̀ lórí ìkànnì jw.org lédè rẹ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 3)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwbq àpilẹ̀kọ 131—Àkòrí: Kí Ni Bíbélì Sọ Nípa Ṣíṣe Ara Lóge? (th ẹ̀kọ́ 1)
Orin 36
7. Gbéyàwó Kìkì Nínú Olúwa (Jẹ 28:2)
(8 min.)
8. Ṣé O Láwọn Ìwà Táá Mú Kó O Jẹ́ Ọkọ Tàbí Ìyàwó Rere?
(7 min.) Ìjíròrò.
Ṣé ò ń wá ẹni tó o máa fẹ́? Tí àwọn tó ń wá ẹni tí wọ́n máa fẹ́ bá rí ẹ, ṣé wọ́n máa gbà pé o níwà tó dáa? Òótọ́ ni pé ẹnì kan lè díbọ́n bí ẹni tó níwà tó dáa, àmọ́ bópẹ́ bóyá àwọn èèyàn máa mọ irú ẹni tó jẹ́ torí pé èéfín nìwà.
Àwọn ìwà tó yẹ kí Kristẹni kọ̀ọ̀kan ní la tò sísàlẹ̀ yìí, kọ àwọn ẹsẹ Bíbélì tó bá ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn mu.
Ẹni tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tó sì nígbàgbọ́ nínú ẹ̀
Bó ṣe ń lo àṣẹ tó ní tàbí bóyá ó máa ń tẹrí ba
Ẹni tí ò mọ tara ẹ̀ nìkan, tó sì máa ń fìfẹ́ hàn
Ẹni tó máa ń ṣèpinnu tó dáa, tó mọ̀wọ̀n ara ẹ̀, tó sì máa ń fòye báni lò
Ẹni tó máa ń ṣiṣẹ́ kára, tí kì í fiṣẹ́ falẹ̀
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 34-35