NOVEMBER 17-23
ORIN SÓLÓMỌ́NÌ 6-8
Orin 34 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Má Ṣe Lọ́wọ́ sí Ìṣekúṣe
(10 min.)
Àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì kò fẹ́ kó ní ìbálòpọ̀ kó tó ṣègbéyàwó (Sol 8:8, 9; w15 1/15 32 ¶15-16)
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì nífẹ̀ẹ́ ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà gan-an, kò ṣèṣekúṣe, èyí sì mú kí ọkàn ẹ̀ balẹ̀ (Sol 8:10; yp 188 ¶2)
Àpẹẹrẹ tó dáa ni ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì jẹ́ fáwọn ọ̀dọ́ (yp2 33)
BI ARA RẸ PÉ, ‘Tí àwọn tí kò tíì ṣègbéyàwó bá wà nínú ìjọ mi, kí ni mo lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè jẹ́ ògiri bíi ti ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì?’
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Sol 8:6—Kí nìdí tí Bíbélì fi pe ìfẹ́ tòótọ́ ní “ọwọ́ iná Jáà”? (w15 1/15 29 ¶3)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Sol 7:1-13 (th ẹ̀kọ́ 12)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo káàdì ìkànnì jw.org láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 4 kókó 4)
5. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ NÍBI TÍ ÈRÒ PỌ̀ SÍ. Lo ìwé ìléwọ́ láti bá ẹnì kan sọ̀rọ̀ níbi táwọn èèyàn ti ń tajà. (lmd ẹ̀kọ́ 1 kókó 4)
6. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(2 min.) ÌWÀÁSÙ ÀÌJẸ́-BÍ-ÀṢÀ. Ò ń bá ẹnì kan sọ̀rọ̀, àmọ́ o ò ráyè wàásù títí tẹ́ ẹ fi pínyà. (lmd ẹ̀kọ́ 2 kókó 4)
7. Ṣàlàyé Ohun Tó O Gbà Gbọ́
(5 min.) Àṣefihàn. ijwfq àpilẹ̀kọ 43—Àkòrí: Ṣé Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Òfin tí Wọ́n Máa Ń Tẹ̀ Lé tí Wọ́n Bá Ń Fẹ́ra Sọ́nà? (th ẹ̀kọ́ 7)
Orin 121
8. Sá fún Ìṣekúṣe
(15 min.) Ìjíròrò.
Nínú ìwé Orin Sólómọ́nì, ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olólùfẹ́ ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì sọ fún un pé káwọn jọ jáde. (Sol 2:10-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ èrò tó dáa ni ọ̀dọ́kùnrin olùṣọ́ àgùntàn náà ní, àwọn ẹ̀gbọ́n ọ̀dọ́bìnrin Ṣúlámáítì gbé iṣẹ́ fún un kó má bàa ráyè lọ. (Sol 2:15) Wọ́n mọ̀ pé tí àbúrò wọn bá dá wà pẹ̀lú olùṣọ́ àgùntàn tó jẹ́ olólùfẹ́ ẹ̀, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ṣèṣekúṣe.
Bíbélì rọ̀ wá pé ká “sá fún ìṣekúṣe.” (1Kọ 6:18) Kò yẹ ká ṣe ohunkóhun tó lè mú ká ṣe ìṣekúṣe. Ẹni tó kọ ìwé Orin Sólómọ́nì sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n rí ewu, ó sì fara pa mọ́, àmọ́ aláìmọ̀kan kọrí síbẹ̀, ó sì jìyà rẹ̀.”—Owe 22:3
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ọlọ́run “Mọ Àwọn Àṣírí Ọkàn Àyà.” Lẹ́yìn náà, béèrè pé:
Ẹ̀kọ́ wo lo rí kọ́ nínú fídíò yìí?
9. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 36-37