NOVEMBER 24-30
ÀÌSÁYÀ 1-2
Orin 44 àti Àdúrà | Ọ̀rọ̀ Ìbẹ̀rẹ̀ (1 min.)
1. Ọkàn Àwọn Tí “Ẹ̀ṣẹ̀ Wọ̀ Lọ́rùn” Lè Balẹ̀
(10 min.)
[Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ Ohun Tó Wà Nínú Ìwé Àìsáyà.]
‘Ẹ̀ṣẹ̀ wọ àwọn èèyàn Ọlọ́run lọ́rùn’ (Ais 1:4-6; ip-1 14 ¶8)
Tí wọ́n bá ronú pìwà dà, Jèhófà ṣe tán láti dárí jì wọ́n (Ais 1:18; ip-1 28-29 ¶15-17)
RONÚ LÓRÍ ÌBÉÈRÈ YÌÍ: Tá a bá ronú pé Jèhófà ò lè dárí jì wá torí a ti dá ẹ̀ṣẹ̀ tó burú gan-an, báwo ni ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì ṣe lè fi wá lọ́kàn balẹ̀?
2. Àwọn Ẹ̀kọ́ Iyebíye Míì
(10 min.)
Ais 2:2—Kí ni “òkè ilé Jèhófà” dúró fún? (ip-1 39 ¶9)
Àwọn ẹ̀kọ́ iyebíye wo lo rí nínú Bíbélì kíkà ọ̀sẹ̀ yìí tí wàá fẹ́ sọ?
3. Bíbélì Kíkà
(4 min.) Ais 2:1-11 (th ẹ̀kọ́ 11)
4. Bá A Ṣe Lè Bẹ̀rẹ̀ Ọ̀rọ̀ Wa
(3 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Lo ọ̀kan nínú àwọn àkòrí tó wà ní àfikún A nínú ìwé Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Èèyàn láti bá ẹni náà sọ̀rọ̀. (lmd ẹ̀kọ́ 3 kókó 3)
5. Pa Dà Lọ
(4 min.) ÌWÀÁSÙ ILÉ-DÉ-ILÉ. Ohun tí ẹni náà nífẹ̀ẹ́ sí yàtọ̀ sí ohun tó o múra sílẹ̀ láti bá a sọ. (lmd ẹ̀kọ́ 7 kókó 4)
6. Àsọyé
(5 min.) ijwbq àpilẹ̀kọ 96—Àkòrí: Kí Ni Ẹ̀ṣẹ̀? (th ẹ̀kọ́ 20)
Orin 38
7. Di Ọ̀rẹ́ Jèhófà—Jèhófà Máa Ń Dárí Jini
(15 min.) Ìjíròrò.
Jẹ́ kí àwọn ará wo FÍDÍÒ náà. Tó bá ṣeé ṣe, pe àwọn ọmọdé mélòó kan wá sórí pèpéle, kó o bi wọ́n ní ìbéèrè nípa fídíò náà àtàwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́.
8. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ìjọ
(30 min.) lfb ẹ̀kọ́ 38, ọ̀rọ̀ ìṣáájú apá 7, àti ẹ̀kọ́ 39