Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
FEBRUARY 2020
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ: APRIL 6–MAY 3, 2020
© 2019 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn. Tó o bá fẹ́ ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ lọ sí ìkànnì donate.jw.org.
Tá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, inú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun la ti mú gbogbo ẹsẹ Bíbélì tá a lò.
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ:
Ọ̀dọ́kùnrin kan tó jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì sáré lọ fẹjọ́ sun Mósè àti Jóṣúà pé àwọn ọkùnrin méjì kan ń ṣe bíi wòlíì nínú àgọ́. Jóṣúà wá ní kí Mósè bá wọn wí, àmọ́ Mósè kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ohun tó sọ fún Jóṣúà ni pé inú òun dùn bí Jèhófà ṣe fi ẹ̀mí Rẹ̀ sórí àwọn ọkùnrin méjì náà. (Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 8, ìpínrọ̀ 10)