Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́
AUGUST 2020
ÀWỌN ÀPILẸ̀KỌ TÁ A MÁA KẸ́KỌ̀Ọ́ NÍ: SEPTEMBER 28–NOVEMBER 1, 2020
© 2020 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
Ìtẹ̀jáde yìí kì í ṣe títà. Ó jẹ́ ara iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kárí ayé tá à ń fi ọrẹ àtinúwá tì lẹ́yìn. Tó o bá fẹ́ ṣètọrẹ, jọ̀wọ́ lọ sí ìkànnì donate.jw.org.
Tá ò bá fi hàn pé ó yàtọ̀, inú Bíbélì Mímọ́ ti Ìtumọ̀ Ayé Tuntun la ti mú gbogbo ẹsẹ Bíbélì tá a lò.
ÀWÒRÁN IWÁJÚ ÌWÉ:
Àwòrán Jésù bó ṣe wà lọ́run. Àwọn kan lára àwọn tí wọ́n jọ máa ṣàkóso wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ rẹ̀, wọ́n jọ ń wo ẹgbàágbèje àwọn áńgẹ́lì. Àwọn áńgẹ́lì kan ń fò lọ sílẹ̀ ayé kí wọ́n lè jíṣẹ́ tí Jèhófà rán wọn. Gbogbo àwọn tó wà nínú àwòrán yìí ni Jèhófà gbéṣẹ́ fún (Wo àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ 32, ìpínrọ̀ 5)