Àwọn Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì JW.ORG
ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Kọ́ Ẹ̀rí Ọkàn Mi?
Ẹ̀rí ọkàn ẹ máa ń fi irú ẹni tó o jẹ́ àtohun tó o kà sí pàtàkì hàn. Kí ni ẹ̀rí ọkàn ẹ ń sọ nípa irú ẹni tó o jẹ́?
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ > ÀWỌN Ọ̀DỌ́ BÉÈRÈ PÉ.
TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN
Obìnrin olóòótọ́ ni Màríà Magidalénì, ó sì wà lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn tó kọ́kọ́ rí Jésù nígbà tó jí dìde. Òun ni Jésù tún rán pé kó lọ sọ ìròyìn ayọ̀ náà fáwọn míì.
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ > TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN.