Àwọn Ohun Tó Wà Lórí Ìkànnì JW.ORG
ÌRÍRÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ
Àkúnya Omi Mú Kí Wọ́n Gbọ́ Ìwàásù
Nígbà tí omi ya wọ àwọn abúlé kan ní Nicaragua, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ọkọ̀ ojú omi wọn gbé àwọn ará ìlú tó wá ṣèrànwọ́, wọ́n sì sọ̀rọ̀ ìtùnú látinú Bíbélì fáwọn tí àjálù náà dé bá.
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ > ÌRÍRÍ ÀWỌN ẸLẸ́RÌÍ JÈHÓFÀ > WỌ́N Ń KỌ́NI NÍ ÒTÍTỌ́ BÍBÉLÌ.
LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA
Ohun Tó Dáa Jù Ni Wọ́n Fi Ránṣẹ́
Báwo làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ran àwọn ará wọn ní Jámánì lọ́wọ́ gbàrà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí?
Lórí ìkànnì jw.org, lọ sí OHUN TÁ A NÍ > OHUN TÓ WÀ LÓRÍ ÌKÀNNÌ > LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA.