ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w22 April ojú ìwé 15
  • Wọ́n Fún Àwọn Ajá Mi Ní Bisikíìtì

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Wọ́n Fún Àwọn Ajá Mi Ní Bisikíìtì
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ohun Tí Jíjẹ́ Opó Sọ Àwọn Obìnrin Méjì Kan Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
  • Àtẹ Ìwé Tó Ń Jẹ́rìí “fún Gbogbo Orílẹ̀-Èdè”
    Bá A Ṣe Ń Ná Owó Tẹ́ Ẹ Fi Ń Ṣètọrẹ
  • Bí Ìwọ àti Àfẹ́sọ́nà Rẹ Bá Fi Ara Yín Sílẹ̀
    Jí!—2015
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2022
w22 April ojú ìwé 15
Ọkùnrin kan ń mú àwọn ajá ẹ̀ méjèèjì rìn. Wọ́n ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tọkọtaya tó wà nídìí àtẹ ìwé.

Wọ́n Fún Àwọn Ajá Mi Ní Bisikíìtì

ÌLÚ Oregon lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Nick ń gbé. Ó sọ pé: “Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 2014, mo mú àwọn ajá mi kékeré méjì lọ ṣeré nígboro. Mo kíyè sí i pé àárín ìgboro làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sábà máa ń wà tí wọ́n bá ń wàásù níbi àtẹ ìwé wọn. Wọ́n máa ń múra dáadáa, wọ́n sì máa ń kí gbogbo èèyàn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́.

“Kì í ṣe èèyàn nìkan làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣòre fún, wọ́n tún ṣe àwọn ajá mi lóore. Lọ́jọ́ kan, obìnrin kan tó ń jẹ́ Elaine tó ń wàásù níbi àtẹ ìwé fún àwọn ajá mi ní bisikíìtì. Lẹ́yìn ìgbà yẹn, tá a bá ti ń kọjá, àwọn ajá mi máa ń fà mí lọ síbi àtẹ ìwé náà kí wọ́n lè rí bisikíìtì jẹ.

“Lẹ́yìn oṣù mélòó kan, àwọn ajá mi gbádùn bisikíìtì tí wọ́n ń fún wọn, èmi náà sì gbádùn ọ̀rọ̀ táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá mi sọ. Àmọ́ mi ò fẹ́ bá wọn sọ̀rọ̀ púpọ̀ jù. Mo ti lé lẹ́ni àádọ́rin (70) ọdún, mi ò sì mọ ohun táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gbà gbọ́. Torí pé ọ̀rọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ti sú mi, mo rò pé á dáa kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fúnra mi.

“Lásìkò yẹn, mo máa ń rí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà míì táwọn náà máa ń dúró síbi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ láàárín ìlú níbi àtẹ ìwé wọn. Ara àwọn náà yá mọ́ọ̀yàn. Wọ́n máa ń fi Bíbélì dáhùn àwọn ìbéèrè tí mo bá bi wọ́n. Torí náà, mo bẹ̀rẹ̀ sí í gbà wọ́n gbọ́.

“Lọ́jọ́ kan, Elaine bi mí pé: ‘Ṣé o gbà pé Ọlọ́run ló fún wa láwọn ẹranko?’ Mo wá sọ fún un pé: ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo gbà bẹ́ẹ̀!’ Elaine wá ka Àìsáyà 11:6-9 fún mi. Àtìgbà yẹn ló ti ń wù mí pé kí n kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, àmọ́ mi ò tíì fẹ́ gba ìwé lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

“Lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo máa ń gbádùn ọ̀rọ̀ tí Elaine àti Brent ọkọ ẹ̀ máa ń bá mi sọ látinú Bíbélì. Wọ́n ní kí n ka Bíbélì láti ìwé Mátíù títí dé ìwé Ìṣe kí n lè túbọ̀ fìwà jọ Kristi, mo sì ṣe ohun tí wọ́n sọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ní nǹkan bí oṣù June 2016, mo gbà kí Brent àti Elaine máa kọ́ mi lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

“Mo máa ń gbádùn ohun tí wọ́n ń kọ́ mi lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ àtàwọn ìpàdé tá a máa ń ṣe ní Gbọ̀ngàn Ìjọba. Inú mi dùn gan-an pé ohun tí Bíbélì sọ ni wọ́n ń kọ́ mi. Ọdún kan ó lé díẹ̀ lẹ́yìn ìgbà yẹn, mo ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gọ́rin (79) ni mí, inú mi sì dùn pé mo ti rí ẹ̀sìn tòótọ́. Jèhófà ti bù kún mi gan-an torí ó jẹ́ kí n wà lára àwọn tó ti ya ara wọn sí mímọ́ fún un.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́