ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp17 No. 5 ojú ìwé 9
  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ǹjẹ́ O Mọ̀?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • “Kò sí Ìkankan Lára Yín Tó Máa Ṣègbé”
    “Jẹ́rìí Kúnnákúnná Nípa Ìjọba Ọlọ́run”
  • Ìyọ́nú fun Awọn Ti A Npọnloju
    Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí
  • Jésù Wo Ọmọbìnrin Kan àti Adití Kan Sàn
    Jésù—Ọ̀nà, Òtítọ́ Àti Ìyè
  • “Nínú Àwọn Ewu Odò”
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1999
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2017
wp17 No. 5 ojú ìwé 9

ǸJẸ́ O MỌ̀?

Ṣé èébú ni àpèjúwe tí Jésù ṣe nípa “ajá kéékèèké” jẹ́?

Ère ọmọ kan tó gbé ọmọ ajá dání nílẹ̀ Gírí ìsì tàbí Róòmù

Ọmọ kan gbé ajá dání, ère ilẹ̀ Gíríìsì tàbí Róòmù (ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọgọ́rùn-ún ọdún kejì Sànmánì Kristẹni)

Nígbà kan tí Jésù wà ní ààlà orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ní ìlú Síríà tó jẹ́ ọ̀kan lara ẹkùn-ìpínlẹ̀ Róòmù, obìnrin ọmọ ilẹ̀ Gíríìsì kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀ fún ìrànlọ́wọ́. Jésù lo àpèjúwe kan tó dà bíi pé ó ń fi àwọn tí kì í ṣe Júù wé “ajá kéékèèké.” Bẹ́ẹ̀ sì rè é, lábẹ́ Òfin Mósè, ẹran aláìmọ́ ni wọ́n ka ajá sí. (Léfítíkù 11:27) Ṣé Jésù ń bú obìnrin Gíríìkì yìí àtàwọn míì tí kì í ṣe Júù ni?

Rárá. Ohun tí Jésù ń sọ ni pé, ojúṣe pàtàkì òun ni láti ran àwọn Júù lọ́wọ́. Ó wá fi àpèjúwe yẹn tẹ kókó yìí mọ́ obìnrin Gíríìkì yẹn lọ́kàn, ó ní: “Kò tọ́ kí a mú búrẹ́dì àwọn ọmọ, kí a sì sọ ọ́ sí àwọn ajá kéékèèké.” (Mátíù 15:​21-26; Máàkù 7:26) Àwọn Gíríìkì àtàwọn ọmọ ilẹ̀ Róòmù gbà pé ẹran ọ̀sìn tó dáa ni ajá, inú ilé wọn ló máa ń gbé, á sì máa bá àwọn ọmọ olówó rẹ̀ ṣeré. Ọ̀rọ̀ náà “ajá kéékèèké,” mú kí obìnrin yẹn rántí àjọṣe tó máa ń wà láàárín àwọn ajá àtàwọn olówó wọn. Obìnrin Gíríìkì yìí wá mú lára ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ, ó sì fèsì pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, Olúwa; ṣùgbọ́n àwọn ajá kéékèèké ní ti gidi máa ń jẹ nínú èérún tí ń jábọ́ láti orí tábìlì àwọn ọ̀gá wọn.” Jésù yin obìnrin náà torí ìgbàgbọ́ rẹ̀, ó sì wo ọmọ obìnrin náà sàn.​—Mátíù 15:​27, 28.

Ṣé àbá tó dáa ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù mú wá nígbà tó ní káwọn atukọ̀ òkun dá ìrìn àjò wọn dúró díẹ̀?

Ọkọ ojú omi tí wọ́n mọ sára ògiri

Àwòrán ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n mọ sára ògiri (ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní Sànmánì Kristẹni)

Ìjì ń da ọkọ̀ ojú omi tí wọ́n fi n gbé Pọ́ọ̀lù lọ sí orílẹ̀-èdè Ítálì láàmú. Nígbà tí wọ́n dúró díẹ̀ níbì kan, Pọ́ọ̀lù dábàá pé kí wọ́n dá ìrìn àjò náà dúró di ìgbà míì. (Ìṣe 27:​9-12) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ bẹ́ẹ̀?

Àwọn atukọ̀ ojú omi ayé ìgbà yẹn mọ̀ pé ó léwu láti tukọ̀ lórí òkun Mẹditaréníà láwọn oṣù tí òtútù máa ń mú gan-an. Wọ́n kì í tukọ̀ lórí òkun láti oṣù November 15 sí March 15, torí pé ó léwu. Àmọ́ oṣù September tàbí October ni ìrìn àjò tí Pọ́ọ̀lù sọ nípa rẹ̀ bọ́ sí. Nínú ìwé Epitome of Military Science, Ọ̀gbẹ́ni Vegetius tó jẹ́ òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Róòmù (ọgọ́rùn-ún ọdún kẹrin Sànmánì Kristẹni) sọ bí ìrìn àjò ojú òkun ṣe máa ń rí, ó ní: “Àwọn oṣù kan wà tí ìrìn àjò ojú òkun kì í léwu rárá, àwọn oṣù míì wà táwọn atukọ̀ kì í mọ̀ bóyá ó léwu, àwọn oṣù míì ò sì dáa rárá fún ìrìn àjò.” Ọ̀gbẹ́ni Vegetius tún sọ pé, kì í séwu téèyàn bá rìnrìn àjò láàárín oṣù May 27 sí September 14. Àmọ́ oṣù tí ò dá wọn lójú ni September 15 sí November 11. Oṣù tó máa ń léwu gan-an ni March 11 sí May 26. Ó dájú pé Pọ́ọ̀lù mọ èyí dáadáa, torí pé ó máa ń rìnrìn àjò orí òkun dáadáa. Ó ṣeé ṣe kí àwọn atukọ̀ àti ẹni tó ni ọkọ̀ ojú omi náà mọ̀ bẹ́ẹ̀, àmọ́ wọ́n kọtí ikún sí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù. Ọkọ̀ ojú omi náà sì rì.​—Ìṣe 27:​13-44.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́