ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • wp24 No. 1 ojú ìwé 16
  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ṣé Wọ́n Máa Sin Jèhófà Tí Wọ́n Bá Dàgbà?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2020
  • Àwọn Ìpinnu Tó Ń Mú Kéèyàn Láyọ̀
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2007
  • Bó O Ṣe Lè Ṣe Ìpinnu Tó Bọ́gbọ́n Mu Nígbà Ọ̀dọ́
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2014
  • Báwo Ló Ṣe Yẹ Ká Lo Òmìnira Tá A ní Láti Sèpinnu?
    Jí!—2003
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tá À Ń Fi Sóde)—2024
wp24 No. 1 ojú ìwé 16
Ọ̀dọ́kùnrin tá a rí àwòrán ẹ̀ nínú àwọn àpilẹ̀kọ tó ṣáájú wà lójú ọ̀nà tó lọ sórí òkè kan, ó sì ń wo máàpù. Òpó kan wà níwájú ọ̀dọ́kùnrin náà tó ní àwọn pátákó tó tọ́ka sí ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, òkè ńlá kan sì wà lọ́ọ̀ọ́kán ẹ̀.

Ibo Lo Ti Lè Rí Ìmọ̀ràn Tó Ṣeé Gbára Lé Lónìí?

Láyé tá a wà yìí, àwọn èèyàn lè gbà pé ohun kan dáa lónìí, àmọ́ kí wọ́n tún sọ pé kò dáa mọ́ lọ́la. Torí náà, o lè máa bi ara ẹ pé: Kí ló máa ràn mí lọ́wọ́ láti ṣe àwọn nǹkan tó dáa, tó sì máa múnú mi dùn? Kí ló máa jẹ́ kó dá mi lójú pé ohun tí mo gbà pé ó dáa báyìí ò ní pa dà di ohun tí kò dáa tó bá yá?

Bíbélì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè ṣe àwọn nǹkan tó dáa, tó ò sì ní kábàámọ̀ tó bá yá. Kí nìdí tó o fi lè gbára lé Bíbélì? Ìdí ni pé ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó jẹ́ Ẹlẹ́dàá wa ni Bíbélì ti wá. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, Ọlọ́run mọ ohun tó lè jẹ́ ká láyọ̀ àtohun táá fi wá lọ́kàn balẹ̀.

“Ó ti sọ ohun tó dára fún ọ.”—Míkà 6:8.

Tá a bá ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì, a ò ní kábàámọ̀ láé. Ó “ṣeé gbára lé ní gbogbo ìgbà, ní báyìí àti títí láé.”—Sáàmù 111:8.

A rọ̀ ẹ́ pé kó o fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, kó o lè mọ bí Bíbélì ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ nínú ayé tó jẹ́ pé ojoojúmọ́ ni nǹkan ń yí pa dà yìí.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́