ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • w24 February ojú ìwé 28-29
  • Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
  • Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Ẹ̀dà Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2019
  • Kí Là Ń Pè Ní Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?
    Àwọn Ìbéèrè Táwọn Èèyàn Sábà Máa Ń Béèrè Nípa Ẹlẹ́rìí Jèhófà
  • Àwọn Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2000
  • Èyí Ha Lè Jẹ́ Iṣẹ́ Tó Dára Jù Lọ fún Ọ Bí?
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2001
Àwọn Míì
Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa (Tó Wà fún Ìkẹ́kọ̀ọ́)—2024
w24 February ojú ìwé 28-29

Àwọn Arákùnrin Méjì Tó Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí

NÍ WEDNESDAY, January 18, 2023, wọ́n gbé ìfilọ̀ pàtàkì kan sórí jw.org pé Arákùnrin Gage Fleegle àti Arákùnrin Jeffrey Winder ti di ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó ti pẹ́ gan-an táwọn arákùnrin méjèèjì yìí ti ń sin Jèhófà tọkàntọkàn.

Gage Fleegle àti Nadia ìyàwó ẹ̀

Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó bẹ̀rù Ọlọ́run làwọn òbí Arákùnrin Fleegle, apá ìwọ̀ oòrùn agbègbè Pennsylvania lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni wọ́n sì ń gbé. Nígbà tó wà lọ́dọ̀ọ́, wọ́n kó lọ sí ìlú kékeré kan tí ò lajú torí pé wọ́n nílò àwọn oníwàásù púpọ̀ sí i níbẹ̀. Kò pẹ́ sígbà yẹn, ó ṣèrìbọmi ní November 20, 1988.

Gbogbo ìgbà làwọn òbí Arákùnrin Fleegle máa ń sọ fún un pé iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún ni kó fayé ẹ̀ ṣe. Wọ́n sábà máa ń gba àwọn alábòójútó àyíká àtàwọn tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lálejò, Arákùnrin Fleegle sì máa ń rí i pé inú àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin yìí máa ń dùn gan-an. Kò pẹ́ lẹ́yìn tó ṣèrìbọmi, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà ní September 1, 1989. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, ọwọ́ ẹ̀ tẹ iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì tó ti ní lọ́kàn pé òun máa fayé òun ṣe láti ọmọ ọdún méjìlá (12). Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Brooklyn ló ti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní October 1991.

Nígbà tí Arákùnrin Fleegle dé Bẹ́tẹ́lì, ọdún mẹ́jọ ló fi ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń dìwé pọ̀, lẹ́yìn náà wọ́n ní kó lọ máa ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn. Àsìkò yẹn kan náà ló sìn fún ọdún mélòó kan níjọ tí wọ́n ti ń sọ èdè Rọ́ṣíà. Lọ́dún 2006, òun àti Nadia ṣègbéyàwó, wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Àwọn méjèèjì jọ sìn níjọ tó ń sọ èdè Potogí, ó sì ju ọdún mẹ́wàá lọ tí wọ́n fi sìn níjọ tó ń sọ èdè Sípáníìṣì. Lẹ́yìn tí Arákùnrin Fleegle ti ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn fún ọ̀pọ̀ ọdún, wọ́n ní kó lọ máa ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìgbìmọ̀ Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́, nígbà tó yá, wọ́n ní kó lọ máa ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn. Ní March 2022, wọ́n fọwọ́ sí i pé kó di ọ̀kan lára àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Jeffrey Winder àti Angela ìyàwó ẹ̀

Ìlú Murrieta, ní California, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ni Arákùnrin Winder dàgbà sí. Ẹlẹ́rìí Jèhófà làwọn òbí ẹ̀, ó sì ṣèrìbọmi ní March 29, 1986. Nígbà tó di oṣù tó tẹ̀ lé e, ó ṣiṣẹ́ asáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́. Ó gbádùn iṣẹ́ náà débi pé ó wù ú kó máa bá a lọ. Lẹ́yìn tó ṣiṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù mélòó kan, ó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ asáájú-ọ̀nà déédéé ní October 1, 1986.

Nígbà tí Arákùnrin Winder wà lọ́dọ̀ọ́, ó lọ kí àwọn ẹ̀gbọ́n ẹ̀ ọkùnrin méjì tó ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì lásìkò yẹn. Ìbẹ̀wò tó ṣe yẹn jẹ́ kí iṣẹ́ ìsìn Bẹ́tẹ́lì wù ú, ó sì pinnu pé òun máa ṣiṣẹ́ níbẹ̀ tóun bá dàgbà sí i. Torí náà ní May 1990, ètò Ọlọ́run sọ pé kó wá máa ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Wallkill.

Nígbà tí Arákùnrin Winder dé Bẹ́tẹ́lì, oríṣiríṣi ẹ̀ka ló ti ṣiṣẹ́. Lára àwọn ẹ̀ka náà ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìmọ́tótó, Ẹ̀ka Iṣẹ́ Àgbẹ̀ àti Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Nígbà tó di 1997, ó ṣègbéyàwó pẹ̀lú Angela, wọ́n sì jọ ń ṣiṣẹ́ ní Bẹ́tẹ́lì. Lọ́dún 2014, ètò Ọlọ́run ní kí wọ́n máa lọ sí Warwick, Arákùnrin Winder sì wà lára àwọn tó ṣèrànwọ́ láti kọ́ oríléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà níbẹ̀. Nígbà tó di 2016, wọ́n ní kí wọ́n máa lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Watchtower tó wà ní Patterson, Arákùnrin Winder sì ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Tó Ń Gbé Ohùn àti Àwòrán sáfẹ́fẹ́. Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin, wọ́n pa dà sí Warwick, wọ́n sì ní kí Arákùnrin Winder máa ṣiṣẹ́ ní Ọ́fíìsì Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni. Ní March 2022, wọ́n fọwọ́ sí i pé kó di ọ̀kan lára àwọn olùrànlọ́wọ́ fún Ìgbìmọ̀ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Olùyọ̀ǹda Ara Ẹni ti Ìgbìmọ̀ Olùdarí.

Àdúrà wa ni pé kí Jèhófà máa bù kún ‘àwọn arákùnrin tó jẹ́ ẹ̀bùn’ yìí, bí wọ́n ṣe ń ṣiṣẹ́ kára nítorí ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run.—Éfé. 4:8.

Àwọn arákùnrin ẹni àmì òróró mẹ́sàn-án tó wà nínú Ìgbìmọ̀ Olùdarí báyìí ni: Kenneth Cook, Jr.; Gage Fleegle; Samuel Herd; Geoffrey Jackson; Stephen Lett; Gerrit Lösch; Mark Sanderson; David Splane àti Jeffrey Winder.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́