SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
1915 sí 1947 Ìgbà tí A Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ (Apá Kejì)
Bá A Ṣe Ko Àwọn Oníjà Ẹ̀sìn Lójú
Nígbà tí àwọn olórí ẹ̀sìn ìlú Freetown rí i pé àwọn ọmọ ìjọ wọn ń gbádùn àwọn àsọyé Arákùnrin Brown, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í jowú, inú sì bí wọn gan-an. Ilé Ìṣọ́ December 15, 1923 sọ pé: “Ṣe ni àwọn olórí ẹ̀sìn ń lo àwọn ìwé ìròyìn bíi kóńdó láti fi gbéjà ko ẹ̀kọ́ òtítọ́. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Arákùnrin Brown máa ń fún wọn lésì, àwọn ìwé ìròyìn kan náà ló sì ń gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ jáde.” Nígbà tó yá, kẹ́kẹ́ pa mọ́ àwọn olórí ẹ̀sìn lẹ́nu. Torí pé Arákùnrin Brown tú wọn fó pé èrò òdì ni wọ́n ń tàn kálẹ̀. Ẹ̀kọ́ òtítọ́ wá gbilẹ̀, èyí sì mú kí àwọn tó ń ka àwọn ìwé ìròyìn fẹ́ láti gba àwọn ìwé wa tó dá lórí Bíbélì. Àwọn olórí ẹ̀sìn yìí hùmọ̀ láti pa àwọn èèyàn Ọlọ́run lẹ́nu mọ́, àmọ́ Jèhófà “yí ọṣẹ́ wọn dà sí wọn lórí.”—Sm. 94:21-23.
Ẹgbẹ́ àwọn ọ̀dọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kan tí wọ́n pe ara wọn ní Oníjà Ẹ̀sìn wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbèjà àwọn àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n pe àwọn èèyàn síbi àwọn ìpàdé kan tí wọ́n fẹ́ fi rẹ́yìn “àwọn ọmọlẹ́yìn Russel,” bí wọ́n ṣe ń pe àwọn tó ń kéde Ìjọba Ọlọ́run nígbà yẹn. Arákùnrin Brown fún wọn lésì pé kí wọ́n jẹ́ kí àwọn jọ fèròwérò ní gbangba. Àwọn Oníjà Ẹ̀sìn yìí kọ̀ jálẹ̀, wọn ò gba ọ̀rọ̀ Arákùnrin Brown wọlé, wọ́n sì bẹnu àtẹ́ lu olóòtú ìwé ìròyìn tó tẹ èsì Arákùnrin Brown jáde. Wọ́n tún sọ pé Arákùnrin Brown kò gbọ́dọ̀ wá sí ìpàdé àwọn mọ́, torí náà Arákùnrin Alfred Joseph ló lọ ṣojú rẹ̀.
Ilé ìjọsìn Mẹ́tọ́díìsì kan tó gbajúmọ̀, ìyẹn Buxton Memorial Chapel ní ìlú Freetown ni wọ́n ti ṣe àwọn ìpàdé náà. Arákùnrin Alfred sọ ohun tó ṣẹlẹ̀, ó ní: “Nígbà tí àsìkò tó fún ìbéèrè àti ìdáhùn, mo bi wọ́n léèrè nípa àwọn ẹ̀kọ́ ìsìn Áńgílíkà, ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan àtàwọn ẹ̀kọ́ míì tí kò bá Bíbélì mu. Nígbà tó yá, alága ètò náà kò gbà kí n tún bi wọ́n ní ìbéèrè kankan mọ́.”
Ọ̀kan lára àwọn Oníjà Ẹ̀sìn tó wà níbẹ̀ lálẹ́ ọjọ́ yẹn ni Melbourne Garber, ọkùnrin yìí ti gbọ́ àwọn àsọyé Arákùnrin Bible Brown tẹ́lẹ̀. Kódà òun ni ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ tó sọ láàárín èrò pé “Ọ̀gbẹ́ni Brown mọ Bíbélì rẹ̀ dunjú!” Lẹ́yìn tí Garber fara balẹ̀ ronú lórí ohun tó gbọ́, ó dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Torí náà, ó ní kí Arákùnrin Brown wá máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Arákùnrin Brown ní kó máa wá sí ìkẹ́kọ̀ọ́ Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n ń ṣe ní ilé òun lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé Garber kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ó túbọ̀ tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, kò sì pẹ́ tí òun àtàwọn míì fi ṣèrìbọmi.
Gbogbo ipá tí Sátánì sà láti tẹ iṣẹ́ ìwàásù rì láti ìbẹ̀rẹ̀ ló já sí pàbó. Ńṣe ló dà bí ìgbà tí aláṣẹ ìlú Freetown sọ fún àwọn Oníjà Ẹ̀sìn wọ̀nyẹn pé: “Bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ ènìyàn ni iṣẹ́ yìí ti wá, ẹ ó fòpin sí i. Ṣùgbọ́n bí ó bá jẹ́ pé láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run ni, ẹ kò ní lè dá a dúró.”—Ìṣe 5:38, 39.
Àwọn Ẹlẹ́sìn Brown
Ní ìbẹ̀rẹ̀ oṣù May, ọdún 1923, Arákùnrin Brown tẹ wáyà ránṣẹ́ sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ìlú London pé kí wọ́n fi ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i ránṣẹ́. Kò pẹ́ tí wọ́n fi kó ẹgbẹ̀rún márùn-ún [5,000] ìwé ránṣẹ́, àwọn ìwé mìíràn sì tún dé lẹ́yìn náà. Arákùnrin Brown kò ṣíwọ́ sísọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn, èyí sì fa ọ̀pọ̀ àwọn tó fẹ́ràn ẹ̀kọ́ Bíbélì mọ́ra.
Nígbà tí ọdún yẹn ń parí lọ, ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ sọ pé: “Iṣẹ́ náà [ní Sierra Leone] yára gbòòrò gan-an débi pé Arákùnrin Brown sọ pé òun nílò ìrànlọ́wọ́; Arákùnrin Claude Brown láti ìlú Winnipeg tó wà ní erékùṣù West Indies tẹ́lẹ̀ sì ti wà lọ́nà báyìí kó lè wá kún un lọ́wọ́ lẹ́nu iṣẹ́ náà.”
Ọjọ́ pẹ́ tí Arákùnrin Claude Brown ti ń polongo ìhìn rere. Nígbà Ogun Àgbáyé Kìíní, ó fara da ìyà nígbà tí wọ́n jù ú sí ẹ̀wọ̀n ní ilẹ̀ Kánádà àti ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì torí pé ó kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ogun. Ó lo ọdún mẹ́rin ní orílẹ̀-èdè Sierra Leone, ó sì ṣiṣẹ́ kára láti fún àwọn ará tó wà níbẹ̀ lókun.
Arábìnrin kan tó ń jẹ́ Pauline Cole sọ ohun kan tó ṣẹlẹ̀ nígbà yẹn, ó ní: “Kí n tó ṣèrìbọmi lọ́dún 1925, Arákùnrin Claude fara balẹ̀ bi mí ní ìbéèrè kan.”
“Ó bi mí pé: ‘Arábìnrin Cole, ṣé ohun tó o kọ́ nínú ìwé Studies in the Scriptures yé ẹ? A ò fẹ́ kí o kúrò nínú òtítọ́ torí pé o ò lóye àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì o!’”
Arábìnrin náà fèsì pé “Arákùnrin Claude, mo ti ka àwọn ohun tí mo kọ́ ní àkàtúnkà. Mo sì ti pinnu ohun tí mo fẹ́ ṣe!”
Arábìnrin Pauline Cole
Ó lé ní ọgọ́ta [60] ọdún tí Arábìnrin Cole fi sin Jèhófà, èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò náà ló sì fi ṣe aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe. Ó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé lọ́dún 1988.
Arákùnrin William Bible Brown tún ṣe bẹbẹ bó ṣe ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè túbọ̀ jára mọ́ ìjọsìn Ọlọ́run. Alfred Joseph sọ pé: “Tí èmi àti Arákùnrin Brown bá pàdé láàárọ̀ kùtù, ohun tó sábà máa ń bi mí ni pé: ‘Arákùnrin Joe, báwo ni? Ṣé ara le? Kí ni ẹsẹ ojúmọ́ tòní?’ Tí mi ò bá ti lè dáhùn, ó máa jẹ́ kí n mọ bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí n máa ka ẹsẹ ojúmọ́ nínú ìwé Daily Manna. [Ìwé yìí la wá ń pè ní Ṣíṣàyẹ̀wò Ìwé Mímọ́ Lójoojúmọ́.] Tó bá di àárọ̀ ọjọ́ kejì, màá rí i pé mo yára ka ẹsẹ ojúmọ́ kí ìbéèrè yẹn má bàa tún bá mi lábo. Mi ò tètè mọ àǹfààní tí ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí máa ṣe fún mi, ṣùgbọ́n mo wá mọ̀ ọ́n nígbà tó yá.”
Gbogbo ìdálẹ́kọ̀ọ́ yìí ló so èso rere. Lọ́dún 1923, wọ́n dá ìjọ kan sílẹ̀ ní ìlú Freetown, ẹni mẹ́rìnlá [14] ló sì ṣe ìrìbọmi. Ọ̀kan lára àwọn tó ṣèrìbọmi lọ́dún yẹn ni Arákùnrin George Brown, òun ló jẹ́ kí ìdílé àwọn tó ń jẹ́ Brown nínú ìjọ di mẹ́ta. Bí àwọn ìdílé mẹ́ta yìí ṣe fi ìtara wàásù mú kí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní ìlú Freetown máa pe àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní àwọn ẹlẹ́sìn Brown.