SIERRA LEONE ÀTI GUINEA
1945 sí 1990 ‘Mímú Ọ̀pọ̀lọpọ̀ Wá sí Òdodo.’—Dán. 12:3. (Apá Kẹta)
Àwọn Poro Gbógun Dìde
Abúlé kan tó wà nítòsí ìlú Koindu níbi tí a ti ń kọ́ àwọn ọkùnrin kan tí wọ́n ti ń lọ sípàdé déédéé lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ni wọ́n ti kọ́kọ́ gbógun tì wá. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn ọkùnrin tó jẹ́ Kisi, àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yìí wà nínú ẹgbẹ́ awo kan tó ti jingiri sínú ìbẹ́mìílò, ìyẹn ẹgbẹ́ Poro. Míṣọ́nnárì kan tó ń jẹ́ James Mensah, tó ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó sì wá sìn ní Sierra Leone sọ pé: “Inú bí olórí ẹgbẹ́ Poro nígbà tó rí i pé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò bá wọn lọ́wọ́ sí ẹgbẹ́ awo wọn. Olórí ẹgbẹ́ awo yìí àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ dáwọ́ jọ lu àwọn ọkùnrin tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yìí, wọ́n jí ẹrù wọn, wọ́n dáná sun àwọn ilé wọn, wọ́n dè wọ́n, wọ́n sì lọ jù wọ́n sínú igbó kí ebi lè pa wọ́n kú síbẹ̀. Baálẹ̀ abúlé náà ló ń ki àwọn ọmọ ẹgbẹ́ náà láyà, àmọ́ àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò yẹhùn.”
Nígbà tí àwọn ará ní ìlú Koindu lọ fi ẹjọ́ sun àwọn ọlọ́pàá, àwọn ọlọ́pàá mú olórí ẹgbẹ́ awo Poro àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ títí kan baálẹ̀ abúlé náà. Wọ́n kó wọn lọ sí ilé ẹjọ́, wọ́n sì bá wọn wí gidigidi, kódà ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún kan gbáko tí wọ́n fi rọ baálẹ̀ abúlé náà lóyè. Òkìkí kàn káàkiri nípa bí ilé ẹjọ́ ṣe dá wa láre, ó sì fún àwọn ẹni tuntun púpọ̀ sí i nígboyà láti bẹ̀rẹ̀ sí í wá sí ìpàdé. Nígbà tó yá, baálẹ̀ abúlé náà yí pa dà, òun náà sì fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Ó tiẹ̀ gba àwọn tó wá sí àpéjọ àyíká tá a ṣe ní àgbègbè náà sílé, ó sì tún fún àwọn ará ní màlúù ńlá kan.
Àwọn míì tó tún jẹ́ aṣáájú nínú ẹgbẹ́ awo Poro tún wá ọ̀nà míì láti gbógun tì wá, wọ́n dọ́gbọ́n ‘fi òfin dáná ìjàngbọ̀n.’ (Sm. 94:20) Àwọn olóṣèlú tó jẹ́ ọmọ ẹgbẹ́ Poro fẹ̀sùn kàn wá ní Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin kí wọ́n lè fòfin de àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́, Arákùnrin Charles Chappell sọ pé: “Baálẹ̀ abúlé náà gbèjà wa, ó sọ fún ìgbìmọ̀ náà pé ó ti tó ọdún méjì tí òun ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa. Pé a kì í dá sí òṣèlú, àmọ́ a máa ń kọ́ àwọn èèyàn ní àwọn ohun tó lè ṣe wọ́n láǹfààní, èyí sì ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn máa hùwà ọmọlúwàbí. Kódà, ó sọ fún wọn pé ó wu òun kí òun dara pọ̀ mọ́ wa tó bá yá. Nígbà tí ẹlòmíì lára wọn, tó ti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ wa, tún kín ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn, Ilé Ìgbìmọ̀ náà wọ́gi lé ẹ̀sùn yẹn.”
Ojú àwọn tó kúrò nínú ẹgbẹ́ awo rí màbo lọ́dọ̀ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn. Iṣẹ́ babaláwo ni wọ́n ń ṣe ní ìrandíran ọ̀dọ́ kan tó ń jẹ́ Jonathan Sellu, tó ń gbé ní ìlú Koindu. Wọ́n sì ti ń fi iṣẹ́ ọ̀hún lé e lọ́wọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó jáwọ́ nínú iṣẹ́ awo àti ẹbọ rírú. Ohun tó ṣe yìí bí àwọn ará ilé rẹ̀ nínú gan-an, wọn ò jẹ́ kó lọ sí ilé ìwé mọ́, wọn kì í sì í fún un ní oúnjẹ tó bá lọ sí ìpàdé. Ohun tí wọ́n máa ń sọ fún un ni pé: “Ní kí Ọlọ́run fún ẹ lóúnjẹ!” Síbẹ̀, Jonathan kò yẹsẹ̀. Ó ń rí oúnjẹ jẹ. Ó sì kọ́ bó ṣe lè mọ̀wé kà àti bó ṣe lè kọ̀wé. Nígbà tó yá, ó di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Inú rẹ̀ dùn gan-an pé ìyá rẹ̀ wá kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́.
Ìtẹ̀síwájú Láwọn Ibòmíì Lórílẹ̀-Èdè Náà
Lọ́dún 1960, a dá àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó wà ní àdádó sílẹ̀ ní ìlú Bo, Freetown, Kissy, Koindu, Lunsar, Magburaka, Makeni, Moyamba, Port Loko àti Waterloo títí lọ dé ìlú Kabala lápá àríwá. Iye àwọn akéde fò fẹ̀rẹ̀ lọ́dún yẹn látorí méjìlélọ́gọ́sàn-án [182] sí ọ̀rìnlénígba lé méjì [282]. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wá láti orílẹ̀-èdè Gánà àti Nàìjíríà kí wọ́n lè túbọ̀ ran àwọn ìjọ tó ń gbèrú lọ́wọ́.
Inú àwùjọ méjì ni èyí tó pọ̀ jù lára àwọn ẹni tuntun yìí ti wá, àwọn ni, àwọn Krio tó ń gbé inú ìlú Freetown àti àgbègbè rẹ̀ àti àwọn Kisi tó ń gbé ní Eastern Province. Àmọ́ bí ìwàásù ìhìn rere ṣe túbọ̀ ń gbilẹ̀, àwọn ẹ̀yà míì bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́. Àwọn ni ẹ̀yà Kuranko, Limba, ẹ̀yà Temne lápá àríwá, ẹ̀yà Mende lápá gúúsù àti àwọn ẹ̀yà míì.
Lọ́dún 1961, Ìjọ Freetown East ya Gbọ̀ngàn Ìjọba wọn sí mímọ́. Lẹ́yìn náà, Ìjọ Koindu ya Gbọ̀ngàn Ìjọba tí wọ́n fi bíríkì alámọ̀ kọ́ sí mímọ́. Ó gba ọ̀ọ́dúnrún [300] èèyàn, wọ́n sì tún máa ń fi ṣe Gbọ̀ngàn Àpéjọ. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni wọ́n ṣe Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà nígbà àkọ́kọ́ nílẹ̀ Sierra Leone. Ogójì [40] alàgbà ló pésẹ̀ síbẹ̀. Ohun àrà ọ̀tọ̀ míì tó tún wáyé lọ́dún mánigbàgbé yẹn ni pé a fi Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun sóde lákànṣe, iṣẹ́ náà sì méso jáde.
Ilé Ẹ̀kọ́ Àwọn Alàgbà ní Sierra Leone, lọ́dún 1961. William Nushy (Ìlà ẹ̀yìn, ní àárín), Charles Chappell (ìlà àárín, ẹnì kejì láti apá ọ̀tún), àti Reva Chappell (ìlà iwájú, ẹnì kẹta láti apá ọ̀tún)
Ó ṣe kedere pé Jèhófà ń bù kún àwọn èèyàn rẹ̀. Ní July 28, 1962, a fi orúkọ àjọ tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń lò ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè sílẹ̀ lábẹ́ òfin lọ́dọ̀ ìjọba ilẹ̀ Sierra Leone, ìyẹn International Bible Students Association.
Iṣẹ́ Ìwàásù Dé Orílẹ̀-èdè Guinea
Wàyí o, ẹ jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa orílẹ̀-èdè tó pààlà pẹ̀lú ilẹ̀ Sierra Leone, ìyẹn Guinea (tí wọ́n ń pè ní French Guinea tẹ́lẹ̀). Ṣáájú ọdún 1958, àwọn arákùnrin mélòó kan ti wàásù níbẹ̀ fúngbà díẹ̀ nígbà tí wọ́n gba orílẹ̀-èdè náà kọjá. Àmọ́ ìjọba ilẹ̀ Faransé tó ń gbókèèrè ṣàkóso kò gba iṣẹ́ ìwàásù wa láyè níbẹ̀. Ṣùgbọ́n lọ́dún 1958, àǹfààní ṣí sílẹ̀ láti bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ní pẹrẹu nígbà tí ilẹ̀ Guinea gba òmìnira lábẹ́ ìjọba ilẹ̀ Faransé.
Lọ́dún yẹn kan náà, Arákùnrin Manuel Diogo tó ń sọ èdè Faransé wá láti ilẹ̀ Dahomey (tí wọ́n ń pè ní Benin báyìí), ó lé díẹ̀ ní ẹni ọgbọ̀n [30] ọdún. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ níbi tí wọ́n ti ń wa kùsà ayọ́ ní ìlú Fria, ọgọ́rin [80] kìlómítà ni ibẹ̀ fi jìnnà lápá àríwá sí ìlú Conakry tó jẹ́ olú ìlú ilẹ̀ Dahomey. Ó wù ú gan-an pé kó máa wàásù ní àgbègbè tí iṣẹ́ ìwàásù kò tíì dé yìí, torí náà ó kọ̀wé sí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Faransé pé kí wọ́n kó ìwé ránṣẹ́, kí wọ́n sì rán àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe wá láti ran òun lọ́wọ́. Bó ṣe parí lẹ́tà rẹ̀ nìyí: “Àdúrà mi ni pé kí Jèhófà bù kún iṣẹ́ yìí torí pé ọ̀pọ̀ èèyàn ló fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́.”
Ẹ̀ka ọ́fíìsì wa ní ilẹ̀ Faransé kọ̀wé sí Arákùnrin Manuel láti gbà á níyànjú, wọ́n sì rọ̀ ọ́ pé kó dúró sí ilẹ̀ Guinea bó bá ti lè ṣeé ṣe fún un tó. Wọ́n tún ṣètò pé kí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe kan lọ bẹ̀ ẹ́ wò, kó sì dá a lẹ́kọ̀ọ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀rọ̀ ìyànjú àti ìdálẹ́kọ̀ọ́ yẹn mú kí Manuel túbọ̀ fi ìtara wàásù ní ìlú Fria títí tó fi kú lọ́dún 1968.
Nígbà tí Arákùnrin Wilfred Gooch tó jẹ́ alábòójútó láti ilẹ̀ òkèèrè wá sí ìlú Conakry lọ́dún 1960, ó rí arákùnrin méjì míì tí wọ́n jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Áfíríkà tí wọ́n ń wàásù níbẹ̀. Gooch dábàá pé kí ẹ̀ka ọ́fíìsì wa nílẹ̀ Sierra Leone máa bójú tó iṣẹ́ wa lórílẹ̀-èdè Guinea dípò ẹ̀ka ọ́fíìsì ilẹ̀ Faransé. Ìyípadà yìí wáyé ní March 1, 1961. Oṣù kan lẹ́yìn náà, wọ́n dá ìjọ àkọ́kọ́ sílẹ̀ ní ìlú Conakry lórílẹ̀-èdè Guinea.
Ìmọ́lẹ̀ Òtítọ́ Dé Àgbègbè Gúúsù Orílẹ̀-Èdè Guinea
Ìhìn rere tún gbilẹ̀ ní àgbègbè gúúsù orílẹ̀-èdè Guinea. Ọkùnrin kan lára àwọn ẹ̀yà Kisi tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Falla Gbondo, tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Làìbéríà pa dà sí abúlé Fodédou tó ti wá, ibẹ̀ jẹ́ nǹkan bí ìrìn kìlómítà mẹ́tàlá sí apá ìwọ̀ oòrùn ìlú Guékédou. Ó mú ìwé Lati Paradise T’a Sọnu Si Paradise T’a Jere-Pada dání. Falla kò mọ̀wé kà, àmọ́ ó máa ń ṣàlàyé àwọn àwòrán inú ìwé náà fún àwọn ará abúlé rẹ̀. Ó ní: “Ìwé náà máa ń jẹ́ kí n lè túbọ̀ bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀. Ìwé Ádámù àti Éfà ni wọ́n máa ń pè é.”
Nígbà tí Falla pa dà sí Làìbéríà, ó ṣèrìbọmi, ó sì di aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe nígbà tó yá. Lẹ́ẹ̀mejì lóṣù, ó máa ń pa dà lọ sí abúlé Fodédou láti lọ kọ́ àwùjọ nǹkan bí ọgbọ̀n [30] èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Kò pẹ́ sígbà yẹn tí Borbor Seysey, aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe míì tó jẹ́ ẹ̀yà Kisi wá kún un lọ́wọ́ láti Làìbéríà. Àwọn méjèèjì jọ dá àwùjọ míì sílẹ̀ ní ìlú Guékédou. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwùjọ méjèèjì sì di ìjọ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.
Bí púpọ̀ sí i lára àwọn ẹ̀yà Kisi ṣe ń di Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn baálẹ̀ wọn kíyè sí ìwà rere tí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í hù. Àwọn Ẹlẹ́rìí yìí ń ṣiṣẹ́ kára, wọ́n jẹ́ olóòótọ́, wọn kì í fa wàhálà ní gbogbo abúlé tí wọ́n wà. Torí náà, nígbà tí àwọn ará sọ pé àwọn fẹ́ kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba sí abúlé Fodédou, kíákíá ni àwọn olóyè ibẹ̀ fún wọn ní ilẹ̀ éékà mẹ́jọ. Gbọ̀ngàn Ìjọba yìí ni àkọ́kọ́ lórílẹ̀-èdè Guinea, wọ́n parí rẹ̀ ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1964.
Wàhálà Ṣẹlẹ̀ ní Ìlú Conakry
Àmọ́, wàhálà ń ru gùdù ní ìlú Conakry. Rògbòdìyàn òṣèlú mú kí ìjọba bẹ̀rẹ̀ sí í fura sí àwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè. Ìjọba kò fún àwọn míṣọ́nnárì mẹ́rin tó wá láti Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ní ìwé àṣẹ tí wọ́n á fi lè dúró pẹ́ nílùú, torí náà wọ́n dá wọn pa dà. Wọ́n tún fẹ̀sùn èké kan àwọn arákùnrin méjì tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè Gánà, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n fún nǹkan bí oṣù méjì.
Lẹ́yìn tí wọ́n tú wọn sílẹ̀, wọ́n tún pa dà mú ọ̀kan lára wọn, ìyẹn Arákùnrin Emmanuel Awusu-Ansah, wọ́n sì fi í sí ibi tó dọ̀tí gan-an tó sì burú jáì nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Nígbà tó wà níbẹ̀, ó ní: “Ara mi le nípa tẹ̀mí, àmọ́ ibà máa ń ṣe mí léraléra. Síbẹ̀, mo máa ń wàásù. Lóṣù tó kọjá, mo lo wákàtí mẹ́tàdínláàádọ́rin [67] lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù, àwọn méjì lára àwọn tí mò ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sì bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi lọ sóde ìwàásù.” Ọ̀kan lára wọn di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Lẹ́yìn oṣù márùn-ún, wọ́n tú Arákùnrin Awusu-Ansah sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, wọ́n sì dá a pa dà sí orílẹ̀-èdè Sierra Leone. Ó wá ku ẹyọ akéde kan péré ní ìlú Conakry.
Nígbà tó fi máa di ọdún 1969, rògbòdìyàn òṣèlú rọlẹ̀, torí náà àwọn aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe dé sí ìlú Conakry. Wọ́n gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba láti kọ́ Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, wọ́n sì gbé àkọlé sí i lára. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, iye àwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tí wọ́n sì ń wá sí ìpàdé di nǹkan bí ọgbọ̀n [30].
Wọ́n kọ́kọ́ ń wàásù tìṣọ́ra-tìṣọ́ra torí wọ́n ń bẹ̀rù pé wọ́n lè wá mú wọn. Ṣùgbọ́n bí ọkàn wọn ṣe túbọ̀ ń balẹ̀, wọ́n ń fi kún ìsapá wọn. Lọ́dún 1973, ìjọ kékeré yìí pín ẹgbẹ̀rún mẹ́fà [6,000] ìwé àṣàrò kúkúrú! Nígbà tó yá, àwọn akéde yìí bẹ̀rẹ̀ sí í pín ìwé ìròyìn ní àwọn ọ́fíìsì àtàwọn ibi ìtajà. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, àwọn òṣìṣẹ́ ìjọba àtàwọn aráàlú bẹ̀rẹ̀ sí í lóye iṣẹ́ wa, wọ́n sì wá mọyì rẹ̀. Ní December 15, 1993, bí a ṣe ní sùúrù tí a kò sì jẹ́ kí nǹkan sú wa mú ká lè forúkọ ẹ̀sìn wa sílẹ̀ lábẹ́ òfin, ìyẹn Christian Association of Jehovah’s Witnesses of Guinea.
Wọ́n máa ń sọ fún un pé: “Ní kí Ọlọ́run fún ẹ lóúnjẹ!”