Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ẹ̀yin Ẹni Ọ̀wọ́n Tá A Jọ Jẹ́ Ará Ilé:
Inú wa dùn gan-an láti kọ̀wé sí yín ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún mánigbàgbé yìí! Tó bá fi máa di ìparí ọdún 2014, ó ti máa pé ọgọ́rùn-ún ọdún tí Jésù Kristi, Ọba wa ọ̀wọ́n ti ń ṣàkóso láàárín àwọn ọ̀tá rẹ̀.—Sm. 110:1, 2.
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún iṣẹ́ ìsìn yìí, Ìgbìmọ̀ Tó Túmọ̀ Bíbélì Ayé Tuntun mú Bíbélì tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ tún ṣe lédè Gẹ̀ẹ́sì jáde níbi ìpàdé ọdọọdún àjọ Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania. Ọ̀rọ̀ inú Bíbélì yìí ṣe kedere, òun ló sì yéni jù lọ. Jèhófà lo àwọn ọmọ rẹ̀ tó fi ẹ̀mí bí láti ṣe Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun tá a kọ́kọ́ mú jáde. (Róòmù 8:15, 16) Ó dájú pé èyí nìkan ti tó láti mú kéèyàn gbà pé ìtumọ̀ Bíbélì yìí ṣàrà ọ̀tọ̀, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́?
Ọjọ́ pẹ́ tí Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé tó jẹ́ ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí kò ti kóyán iṣẹ́ ìtumọ̀ Bíbélì kéré rárá. Ní báyìí, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun ti wà lódindi tàbí lápá kan ní èdè mọ́kànlélọ́gọ́fà [121]. A rọ̀ yín pé kí ẹ máa fi hàn pé ẹ mọyì Bíbélì tí Jèhófà fún wa yìí. Ẹ máa kà á lójoojúmọ́, kí ẹ sì máa ronú lórí ohun tí ẹ bá kà. Èyí á mú kí ẹ lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ Òǹṣèwé Bíbélì.—Ják. 4:8.
Ó máa ń dùn wá gan-an tí a bá gbọ́ nípa àwọn àdánwò tó ń bá àwọn ará wa fínra. A mọ̀ pé kì í ṣe gbogbo ìgbà ni inú wọn á lè máa dùn bíi ti àwọn ará yòókù. Bí àpẹẹrẹ, nǹkan dojú rú pátápátá nínú ìdílé kan nílẹ̀ Éṣíà nígbà tí ìyàwó ilé náà ṣàdédé rọ lápá rọ lẹ́sẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí tojú sú àwọn akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dókítà, wọn kò sì rí nǹkan kan ṣe sí àìsàn rẹ̀. Áà, ó mà ṣe o! Gbogbo ìgbà ni ọkọ rẹ̀ wá ní láti máa jókòó tì í, kó lè máa ràn án lọ́wọ́. Kristẹni àwòfiṣàpẹẹrẹ ni ọmọ wọn ọkùnrin àtàwọn ọmọbìnrin wọn méjèèjì jẹ́ ní ti pé wọ́n ń ran àwọn òbí wọn lọ́wọ́. A mọ̀ pé ìdílé yìí àti gbogbo ẹ̀yin tí ẹ ti kojú ọ̀pọ̀ àdánwò, tí ẹ sì ṣàṣeyọrí ń ní ayọ̀ tó ń wá látinú fífara da àdánwò ìgbàgbọ́. (Ják. 1:2-4) Jèhófà fi dá àwọn ẹni àmì òróró rẹ̀ àtàwọn àgùntàn mìíràn lójú pé a máa láyọ̀ tí a bá ń bá a nìṣó láti fara da àdánwò, torí pé òun máa fi ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun dá wa lọ́lá!—Ják. 1:12.
Lọ́dún tó kọjá, iye àwọn tó wá síbi Ìrántí Ikú Kristi jẹ́ mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún, ẹgbẹ̀rún mọ́kànlé-ní-òjìlérúgba, igba àti méjìléláàádọ́ta [19,241,252]. Inú wa dùn gan-an láti rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá bọlá fún Jèhófà àti Jésù Kristi bí wọ́n ṣe wá sí ìpàdé tó ṣe pàtàkì jù tí àwa èèyàn Ọlọ́run máa ń ṣe lọ́dọọdún! Lásìkò Ìrántí Ikú Kristi, ìró ìyìn tó rinlẹ̀ dún jáde látẹnu ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkéde tó ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ lóṣù March àti April. Èyí wúni lórí gan-an! Ǹjẹ́ inú yín kò dùn láti mọ̀ pé àwọn tó bá ṣe aṣáájú-ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ nígbà ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká tún láǹfààní láti gbádùn ìpàdé tí alábòójútó àyíká máa ṣe pẹ̀lú àwọn aṣáájú-ọ̀nà déédéé látòkèdélẹ̀, bí ìbẹ̀wò náà kò bá tiẹ̀ bọ́ sí oṣù March tàbí April? Àwọn ọlọ́gbọ́n tó ń fọwọ́ pàtàkì mú nǹkan tẹ̀mí mọ̀ pé ó yẹ káwọn túbọ̀ tẹra mọ́ iṣẹ́ ìwàásù àtàwọn ìgbòkègbodò ìjọ. Bí a ṣe ń jẹ́ kí ọwọ́ wa dí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ń mú ká túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, ká sì lè máa mú Èṣù ní elékèé torí pé ńṣe ló fẹ́ sọ ìgbàgbọ́ wa di ahẹrẹpẹ ká lè kúrò lójú ọ̀nà ìyè.—1 Kọ́r. 15:58.
Ẹ wo bó ti mórí ẹni yá tó láti mọ̀ pé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá, ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdín-ní-ọ̀rìnlérúgba, ọ̀ọ́dúnrún àti mẹ́rìnlélógójì [277,344] èèyàn ló ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, tí wọ́n sì ṣe ìrìbọmi, wọ́n ti wá sójú ọ̀nà ìyè pẹ̀lú àwọn ará wa kárí ayé! (Mát. 7:13, 14) Àwọn ẹni tuntun yìí nílò ìrànlọ́wọ́ wa kí wọ́n lè “fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́.” (Kól. 2:7) Ẹ máa gba ara yín níyànjú láti máa fara dà á títí dé òpin. (Mát. 24:13) “Ẹ máa sọ̀rọ̀ ìtùnú fún àwọn ọkàn tí ó soríkọ́, ẹ máa ṣètìlẹyìn fún àwọn aláìlera, ẹ máa ní ìpamọ́ra fún gbogbo ènìyàn.” (1 Tẹs. 5:14) Torí náà, kí olúkúlùkù wa máa “gbàdúrà láìdabọ̀” pé: “Kí ìjọba rẹ dé.”—1 Tẹs. 5:17; Mát. 6:10.
A gbà yín níyànjú pé kẹ́ ẹ ka Ìwé Ọdọọdún yìí, kẹ́ ẹ sì máa fi sọ́kàn pé a fẹ́ràn gbogbo ẹ̀yin tẹ́ ẹ nífẹ̀ẹ́ Jèhófà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan!
Àwa arákùnrin yín,
Ìgbìmọ̀ Olùdarí Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà