ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • yb15 ojú ìwé 122-ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 7
  • “Mi O Ni Yee Je Elerii Jehofa”

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • “Mi O Ni Yee Je Elerii Jehofa”
  • Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ọpẹ́ Mi Pọ̀ Láìka Àwọn Àjálù Tó Bá Mi Sí—Bí Bíbélì Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2009
  • Ohun Tí Ó Lé Ní 50 Ọdún ‘Ríré Kọjá Wá’
    Ilé-Ìṣọ́nà Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1996
  • Yíyááfì Ohun Púpọ̀ Nítorí Ohun Tí Ó Tóbi Jù ú lọ
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—1997
  • Bíbélì Máa Ń yí Ìgbésí Ayé Àwọn Èèyàn Pa Dà
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2011
Ìwé Ọdọọdún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà—2015
yb15 ojú ìwé 122-ojú ìwé 123 ìpínrọ̀ 7

ORÍLẸ̀-ÈDÈ DOMINICAN

Mi Ò Ní Yéé Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Ana María (Mary) Glass

  • WỌ́N BÍ I NÍ 1935

  • Ó ṢÈRÌBỌMI NÍ 1956

  • ÌSỌFÚNNI ṢÓKÍ Ọ̀dọ́ tó ń fìtara ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì tẹ́lẹ̀ kó tó kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, tó sì fìgboyà fara da inúnibíni tí ìdílé rẹ̀, ṣọ́ọ̀ṣì àti ìjọba ṣe sí i.

Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 122

ỌWỌ́ pàtàkì ni mo fi mú ìjọsìn, mo sì ń fìtara ṣe ẹ̀sìn Kátólíìkì. Mo wà nínú ẹgbẹ́ akọrin, mo sì máa ń tẹ̀ lé àwọn aṣáájú ẹ̀sìn lọ síbi ààtò gbígba ara Olúwa tí wọ́n máa ń ṣe láwọn àrọko. Àmọ́ lọ́dún 1955, ẹ̀gbọ́n mi sọ fún mi nípa Párádísè tó ń bọ̀. Ó fún mi ní Bíbélì kan àti ìwé “Ihinrere Ijọba Yi” pẹ̀lú ìwé “Jeki Ọlọrun Jẹ Olõtọ.” Ohun tí mo gbọ́ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, torí náà mo lọ bi olórí ẹ̀sìn wa bóyá mo lè ka Bíbélì. Ó sọ fún mi pé “orí mi máa dà rú” tí n bá ka Bíbélì, àmọ́ mo kà á.

Nígbà tí mo kó lọ sọ́dọ̀ àwọn òbí mi àgbà nílùú Boca Chica, olórí ẹ̀sìn wa bi mí pé kí ló dé tí mi ò wá sí ṣọ́ọ̀ṣì. Mo ṣàlàyé ohun tí mo rí fún un pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ni kò bá Bíbélì mu. Ó gbaná jẹ. Ló bá pariwo mọ́ mi, ó ní: “Tẹ́tí kó o gbọ́ mi, ìwọ ọmọbìnrin yìí, o wà lára àwọn àgùntàn tó ti yapa kúrò nínú agbo mi.”

Mo fún un lésì pé: “Rárá o, ẹ̀yin lẹ yapa kúrò nínú agbo Jèhófà, torí Jèhófà ló ni agbo àgùntàn, kì í ṣe èèyàn kankan.”

Mi ò tún fẹsẹ̀ kan ṣọ́ọ̀ṣì mọ́ látìgbà yẹn. Mo bá kó lọ sọ́dọ̀ ẹ̀gbọ́n mi, mo sì ṣèrìbọmi lẹ́yìn oṣù mẹ́fà péré tí mo kọ́kọ́ gbọ́ ẹ̀kọ́ òtítọ́. Kété lẹ́yìn náà, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé. Ọdún kan lẹ́yìn ìyẹn ni mo fẹ́ Enrique Glass tó jẹ́ alábòójútó àyíká. Lọ́jọ́ kan tá à ń wàásù ní ọgbà ìtura kan nílùú La Romana, àwọn ọlọ́pàá mú Enrique. Nígbà tí wọ́n ń mú un lọ, mo sáré tẹ̀ lé wọn, mo sì sọ fún wọn pé: “Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà, mo sì ń wàásù. Ẹ ò ṣe mú èmi náà?” Àmọ́ wọn ò fẹ́ mú mi.

Àròpọ̀ gbogbo ọdún tí Enrique ti lò lẹ́wọ̀n ṣáájú ìgbà yẹn jẹ́ ọdún méje ààbọ̀. Lọ́tẹ̀ yìí wọ́n fi í sẹ́wọ̀n ọdún kan àti oṣù mẹ́jọ. Mo máa ń lọ wo Enrique lọ́jọọjọ́ Sunday. Lọ́jọ́ kan tí mo lọ síbẹ̀, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n náà bi mí pé, “Kí lo wá ṣe níbí?”

Mo sọ fún un pé, “Wọ́n fi ọkọ mi sẹ́wọ̀n torí pé ó jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.”

Ó fèsì pé, “Ọ̀dọ́ ni ẹ́, o ṣì lè gbé nǹkan rere ṣe láyé ẹ. Kí ló dé tó ò ń fàkókò ẹ ṣòfò lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà?”

Mo bá sọ fún un pé, “Ẹlẹ́rìí Jèhófà lèmi náà. Bẹ́ ẹ bá tiẹ̀ pa mí lẹ́ẹ̀méje, tẹ́ ẹ sì jí mi dìde lẹ́ẹ̀méje, mi ò ní yéé jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Ìgbà tọ́rọ̀ mi sú u ló bá ní kí n kúrò níwájú òun.

Lẹ́yìn tí wọ́n mú ìfòfindè yẹn kúrò, ọ̀pọ̀ ọdún lèmi àti Enrique fi wà lẹ́nu iṣẹ́ alábòójútó àyíká àti ti àgbègbè. Enrique sùn ní March 8, 2008. Mo ṣì ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà déédéé.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́