Indonéṣíà
ÌRÒYÌN amóríyá tá a fẹ́ sọ yìí dá lórí àwọn Kristẹni onírẹ̀lẹ̀ lọ́kùnrin àti lóbìnrin tí wọ́n lo ìgboyà tí wọ́n sì di ìgbàgbọ́ wọn mú láìka rògbòdìyàn láàárín àwọn olóṣèlú, ìjà ẹ̀sìn àti bí àwọn ẹlẹ́sìn ṣe mú kí ìjọba fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wọn fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25]. A máa kà nípa arákùnrin kan tí orúkọ rẹ̀ wà lára àwọn ti ẹgbẹ́ Kọ́múníìsì fẹ́ pa, àá sì kà nípa ọ̀gá àwọn jàǹdùkú kan tó di olùjọ́sìn Jèhófà. Àá tún rí ìtàn àwọn ọmọbìnrin méjì kan tó jẹ́ odi tí wọ́n mú ara wọn lọ́rẹ̀ẹ́ kí wọ́n tó wá mọ̀ pé ọmọ ìyá làwọn. Pabanbarì rẹ̀, a máa mọ báwọn èèyàn Jèhófà ṣe wàásù káàkiri orílẹ̀-èdè Indonéṣíà, ìyẹn orílẹ̀-èdè táwọn Mùsùlùmí pọ̀ sí jù láyé.