INDONÉṢÍÀ
Àlàyé Ṣókí Nípa Indonéṣíà
Ilẹ̀ Indonéṣíà wà láàárín ilẹ̀ Éṣíà àti orílẹ̀-èdè Ọsirélíà, òun sì ni orílẹ̀-èdè tó ní àwọn erékùṣù tó fẹ̀ jù láyé. Wọ́n ṣírò pé àwọn erékùṣù yìí lé ní 17,500, téèyàn bá sì débẹ̀ á rí àwọn igbó kìjikìji àtàwọn òkè gàgàrà. Yàtọ̀ síyẹn, àwọn òkè ayọnáyèéfín tó wà lórílẹ̀-èdè yìí lé ni ọgọ́rùn-ún [100]. Nínú gbogbo òkè ayọnáyèéfín tó wà láyé, tiwọn ló máa ń yọ iná àti èéfín jù lọ.
Àwọn Èèyàn Nínú àwọn ilẹ̀ téèyàn pọ̀ sí jù lọ láyé, Indonéṣíà ni ìkẹrin, yàtọ̀ sí Ṣáínà, Íńdíà àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó le ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ẹ̀yà tó wà níbẹ̀. Àwọn ẹ̀yà Javanese àti Sundanese ló pọ̀ jù, wọ́n ju ìdá méjì àwọn èèyàn tó wà lórílẹ̀-èdè náà.
Ẹ̀sìn Tá a bá kó ẹni mẹ́wàá jọ lórílẹ̀-èdè Indonéṣíà, Mùsùlùmí ni mẹ́sàn-án lára wọn, nígbà táwọn yòókù ń ṣe ẹ̀sìn Híńdù, Búdà tàbí Kristẹni. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn náà ló tún ń ṣe ẹ̀sìn ìbílẹ̀.
Èdè Ó lé ní ọgọ́rùn-ún méje [700] èdè tí wọ́n ń sọ ní àwọn erékùṣù yìí. Àmọ́, Indonesian ni èdè àjùmọ̀lò tí wọ́n ń sọ, inú èdè Malay lèdè náà sì ti wá. Ọ̀pọ̀ àwọn èèyàn náà ló sì tún ní èdè àbínibí tí wọ́n ń sọ nílé.
Iṣẹ́ Oúnjẹ Òòjọ́ Àgbẹ̀ alárojẹ lọ̀pọ̀ àwọn èèyàn náà, oníṣòwò sì làwọn míì. Orílẹ̀-èdè yìí ní ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ohun àmúṣọrọ̀ inú ilẹ̀ àtàwọn nǹkan míì bí igi gẹdú, epo rọ̀bì àti gáàsì abẹ́ ilẹ̀, ibẹ̀ sì ni ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè ti máa ń ra epo pupa àti rọ́bà.
Oúnjẹ Ìrẹsì ni oúnjẹ táwọn èèyàn náà máa ń jẹ jù. Àwọn oúnjẹ míì tó tún wọ́pọ̀ ni nasi goréng (ìyẹn ìrẹsì tí à ń pè ní fried rice, tí wọ́n wá fi ẹyin àti ẹ̀fọ́ jẹ), satay (ìyẹn àsun), àti gado-gado (ìyẹn sàláàdì àti ẹ̀pà tí wọ́n ti lọ).
Ojú Ọjọ́ Oòrùn máa ń mú gan-an, ó sì máa ń móoru. Wọ́n sábà máa ń ní ìgbà òjò àti ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ ìgbà ni àrá máa ń sán.