Wọ́n ń wàásù níbi tí àwọn ọkọ̀ tó máa ń rìn lórí okùn ti máa ń dúró gbérò nílùú Khulo
JỌ́JÍÀ
“Èyí Ni Ohun Ìní Àjogúnbá Àwọn Ìránṣẹ́ Jèhófà.”—Aísá. 54:17.
ÀWỌN ìránṣẹ́ Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Jọ́jíà ń ṣe gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba Ọlọ́run, Jèhófà sì ń bù kún iṣẹ́ àṣekára wọn. Torí èyí, a lè sọ pé kò síbi tí wọn ò tíì wàásù dé lórílẹ̀-èdè náà.
Òkè: Àwọn akéde fẹ́ lọ wàásù ní abulé Ushguli, nǹkan bí ẹsẹ̀ bàtà 7,200 ni ilẹ̀ ibẹ̀ fi ga sókè
Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àwọn tó ń gbé ní ìpínlẹ̀ ìwàásù tí a kì í ṣe déédéé ni àwọn akéde tó nítara àtàwọn aṣáájú-ọ̀nà túbọ̀ fún láfiyèsí. Láwọn àgbègbè olókè, ọkọ̀ tí ẹsẹ̀ rẹ̀ mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ń ṣiṣẹ́ pa pọ̀ tàbí ọkọ̀ tó máa ń rìn lórí okùn lèèyàn lè fi dé àwọn abúlé àtàwọn abà kan tó wà níbẹ̀.
Àwọn akéde wà ní àgbègbè Svaneti
Àtọdún 2009 ni ẹ̀ka ọ́fíìsì tó wà ní Jọ́jíà ti ń fún gbogbo ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè náà ní orúkọ àwọn ìpínlẹ̀ tí a kò pín fúnni, wọ́n sì ń ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́dọọdún. Wọ́n máa ń rọ àwọn akéde pé kí wọ́n lọ ṣe iṣẹ́ ìwàásù láwọn ìpínlẹ̀ náà. Ọ̀pọ̀ ló yááfì nǹkan ńlá kí wọ́n lè lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ náà.
Ana àti Temuri Bliadze
Temuri àti Ana Bliadze ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣègbéyàwó ni, kò sì pẹ́ tí wọ́n ra ilẹ̀ tí wọ́n máa kọ́ ilé sí tí wọ́n fi gbọ́ pé àwọn tó wà ní àgbègbè olókè Ajaria nílò àwọn oníwàásù gan-an. Àǹfààní bí wọ́n ṣe lè fi kún iṣẹ́ ìwàásù wọn ló yọjú wẹ́rẹ́ yìí.
Wọ́n kọ́kọ́ lo ọ̀sẹ̀ kan gbáko ní àgbègbè Ajaria. Temuri rántí ohun tó kọ́kọ́ wá sí i lọ́kan, ó sọ pé: “Ìrìn ọ̀nà jíjìn ni àwọn akéde tó wà níbẹ̀ máa ń rìn kí wọ́n tó lè dé àwọn abúlé kéékèèké. A ní ọkọ̀ akẹ́rù kan, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni mo sì ti ń wò ó pé ó máa ríṣẹ́ ṣe gan-an níbẹ̀.”
Ana ìyàwó rẹ̀ fi kún un pé: “Kò rọrùn rárá láti kó lọ, torí àwa àtàwọn ará ìjọ wa ti dìkan, a ò sì fẹ́ fi àwọn mọ̀lẹ́bí wa sílẹ̀. Àmọ́ a rọ́wọ́ Jèhófà láyé wa.” Ó ti lé lọ́dún mẹ́ta tí Temuri àti Ana ti ń ran àwùjọ kan lọ́wọ́ ní Keda, ìyẹn ìlú kan tó wà ní àgbègbè Ajaria.
Àwọn Aṣáájú-ọ̀nà tí Kì Í Ṣọ̀lẹ
Àǹfààní ńlá láwọn tó jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà àkànṣé fúngbà díẹ̀ ń ṣe fáwọn èèyàn lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù ní àwọn àgbègbè tó wà ní àdádó. Lẹ́yìn tí iṣẹ́ wọn bá parí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn aṣáájú-ọ̀nà yìí máa ń pínnú láti dúró síbi tí wọ́n yàn wọ́n sí, kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Wọ́n yan àwọn arábìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ aṣáájú-ọ̀nà sí ìlú Manglisi, ìlú kan tó rẹwà gan-an. Khatuna ni àwọn méjèèjì ń jẹ́. Kò sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà kankan tó ń gbé níbẹ̀, síbẹ̀ iṣẹ́ tí àwọn arábìnrin yìí ṣe méso jáde gan-an. Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mẹ́sàn-án ni wọ́n darí lóṣù àkọ́kọ́, wọ́n darí méjìlá [12] lóṣù kejì, mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lóṣù tó tẹ̀ lé e àti méjìdínlógún [18] léyìí tó tẹ̀ lé ìyẹn! Wọ́n pinnu láti dúró sí ìlú Manglisi, kí wọ́n lè máa bójú tó àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.
Àwọn arábìnrin yìí ní láti mọ béèyàn ṣe ń sọ tọ́rọ́ di kọ́bọ̀, kí wọ́n lè máa gbọ́ bùkátà ara wọn. Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń wá sí ìlú Manglisi ló mọyì iṣẹ́ ọwọ́ táwọn èèyàn ibẹ̀ mọ̀ ọ́n ṣe, ìyẹn bí wọ́n ṣe ń fi èèpo èso igi ahóyaya ṣe ohun kan tó ń ṣara lóore. Torí náà, àwọn arábìnrin náà máa kọ́kọ́ kó èèpo èso yìí ní tútù, wọ́n á fi ṣe ohun tó ń ṣara lóore táwọn èèyàn mọ̀ dáadáa yìí, wọ́n á sì lọ tà á lọ́jà. Àmọ́ ṣàdédé ni wọ́n rí ohun kan gbà táá máa mówó wọlé.
Lọ́jọ́ kan, ẹnì kan tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kó ọmọ adìyẹ púpọ̀ wá fún wọn. Ó ṣàlàyé fún wọn pé, ìkan nínú àwọn adìyẹ òun lọ́ yé ẹyin pa mọ́, ó sì kó àwọn ọmọ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ pa wá sílé. Torí pé adìyẹ tí obìnrin yìí ní ti pọ̀ sí i láìròtẹ́lẹ̀, ó fẹ́ fi ṣe ẹ̀bùn fún àwọn tó ń kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà mọ bí wọ́n ṣe ń sin adìyẹ, ni wọ́n bá pinnu láti ní ọgbà kékeré kan tí wọ́n á ti máa sin adìyẹ, kí wọ́n lè máa rí nǹkan tọ́jú ara wọn.
Ọ̀kan lára àwọn arábìnrin náà sọ pé: “Jèhófà ràn wá lọ́wọ́, àwọn ará àtàwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì náà ò fi wá sílẹ̀, ìyẹn ló mú ká lè lo ọdún márùn-ún nílùú Manglisi.” Ní báyìí, àwùjọ kan ti dúró níbẹ̀, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin sì ń ṣèpàdé déédéé.
Khatuna Kharebashvili àti Khatuna Tsulaia nílùú Manglisi
Àwọn Aṣáájú-ọ̀nà Ń Wàásù Lédè Míì
Láwọn ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn ará Jọ́jíà ti ń rí bí ọ̀pọ̀ èèyàn láti orílẹ̀-èdè míì ṣe ń ya wọlé. Ọ̀pọ̀ àwọn aṣáájú-ọ̀nà ló sì rí i pé àǹfààní ló ṣí sílẹ̀ fún wọn yìí láti wàásù. Ni wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ oríṣiríṣi èdè, bí èdè Lárúbáwá, Azerbaijani, Chinese, Gẹ̀ẹ́sì, èdè ilẹ̀ Páṣíà àti ti Tọ́kì.
Bí ọ̀pọ̀ aṣáájú-ọ̀nà ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn ìjọ àtàwọn àwùjọ tó ń sọ èdè ilẹ̀ míì, bẹ́ẹ̀ ni àwọn míì nínú wọn ń lọ sórílẹ̀-èdè míì láwọn àgbègbè tí wọ́n ti túbọ̀ nílò àwọn oníwàásù. Giorgi àti Gela ti lé lógún [20] ọdún nígbà tí wọ́n kó lọ sí orílẹ̀-èdè tí kò jìnnà sí tiwọn. Giorgi sọ pé, “A fẹ́ ṣe gbogbo ohun tá a lè ṣe fún Jèhófà, bá a sì ṣe kó lọ síbẹ̀ jẹ́ àǹfààní tó bá a mu wẹ́kú láti ṣe bẹ́ẹ̀.
Gela rántí àkókò tó lò níbẹ̀, ó sọ pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni mo kọ́ bí mo ṣe jẹ́ alàgbà nírú ìpínlẹ̀ yẹn. Kò sóhun tá a lè fi wé kí Jèhófà máa lo ẹnì kan láti ran àwọn ‘àgùntàn rẹ̀ kéékèèké’ lọ́wọ́.”—Jòh. 21:17.
Giorgi fi kún un pé: “Ìṣòro yọjú lóòótọ̀, àmọ́ iṣẹ́ ìsìn wa la gbájú mọ́, a ò sì máa ro bá a ṣe máa kúrò. A gbà pé ohun tó yẹ ká ṣe là ń ṣe.”
Arákùnrin kan tí òun náà ń jẹ́ Gela fi ọdún mélòó kan ṣiṣẹ́ ìwàásù ní orílẹ̀-èdè Tọ́kì. Ó sọ pé: “Níbẹ̀rẹ̀, mi kì í fi bẹ́ẹ̀ láyọ̀, torí èdè àwọn ará ibẹ̀ ni mò ń bá fà á. Àmọ́, nígbà tí mo wá lè bá àwọn arákùnrin mi, àwọn arábìnrin mi àtàwọn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù sọ̀rọ̀ fàlàlà, ayọ̀ tí mo ní ò ṣeé fẹnu sọ.”
Ó ti lé lọ́dún mẹ́wàá tí Nino ti ń ṣe aṣáájú-ọ̀nà nílùú Istanbul, lórílẹ̀-èdè Tọ́kì. Ó sọ bó ṣe rí lára rẹ̀ báyìí pé: “Àtọjọ́ àkọ́kọ́ tí mo ti kó débí ni mo ti rí bí Jèhófà ṣe ń tì mí lẹ́yìn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé ojoojúmọ́ lèèyàn á máa ní irú ‘àwọn ìrírí tó máa ń wà nínú Ìwé Ọdọọdún’ téèyàn bá lọ sìn lórílẹ̀-èdè míì.”