ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • ijwwd àpilẹ̀kọ 32
  • Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Malle Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Malle Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀
  • Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • ‘Ẹ Dúró Nínú Ọ̀rọ̀ Mi’
    Ilé Ìṣọ́ Tí Ń Kéde Ìjọba Jehofa—2003
  • Máa Lo Ọ̀nà Ìgbọ́rọ̀kalẹ̀ Tó Gbéṣẹ́
    Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa—2012
  • Àwọn Òbí Tó Fọwọ́ Sowọ́ Pọ̀ Tí Wọ́n sì Mọṣẹ́ Wọn Níṣẹ́
    Jí!—2009
  • Àwọn Oyin Mi Bá Adìyẹ Pamọ!
    Jí!—1998
Ta Ló Ṣiṣẹ́ Àrà Yìí?
ijwwd àpilẹ̀kọ 32
Ẹyẹ mallee.

Albert Wright/iStock via Getty Images

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Iṣẹ́ Àrà Tí Ẹyẹ Mallee Ń Ṣe Lórí Ìtẹ́ Rẹ̀

Ẹyẹ kan wà tí wọ́n ń pè ní mallee ní gúúsù orílẹ̀-èdè Ọsirélíà. Ẹyẹ yìí máa ń ṣe ohun kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀. Ohun náà sì ni pé ó máa ń jẹ́ kí ìtẹ́ rẹ̀ móoru ní ìwọ̀n 34 degrees Celsius nígbà gbogbo láìka bójú ọjọ́ ṣe rí. Báwo ni ẹyẹ yìí ṣe ń ṣe é tí ìtẹ́ rẹ̀ fi máa ń móoru láàárọ̀, lọ́sàn-án àti lálẹ́ jálẹ̀ ọdún?

Tó bá ti dìgbà òtútù tàbí ọyẹ́, ẹyẹ yìí máa gbẹ́ ilẹ̀ tó jìn tó mítà kan, tó sì fi bíi mítà mẹ́ta fẹ̀. Akọ ẹyẹ yìí máa wá kó ewé àti koríko sínú ẹ̀. Á wá dúró kí òjò rọ̀ sí i. Lẹ́yìn náà, á gbẹ́ apá kan tí abo máa yé ẹyin sí, á sì da iyẹ̀pẹ̀ bò ó. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, ewé àti koríko náà á máa jẹrà, ìyẹn á sì mú kí ìtẹ́ náà máa móoru ní ìwọ̀n tó yẹ, kí ẹyin tó wà níbẹ̀ lè di ọmọ.

Àwòrán ẹyẹ mallee méjì àti ìtẹ́ wọn. A. Ẹyin mẹ́ta nínú ìtẹ́ tí wọ́n kọ́ fún ẹyin. B. Ewé àti koríko yí ibi tí wọ́n gbẹ́ fún ẹyin ká. C. Iyẹ̀pẹ̀ tí wọ́n fi bo ibi tí wọ́n kọ́ fún ẹyin. D. Akọ ẹyẹ mallee fi ẹsẹ̀ wa iyẹ̀pẹ̀ sórí ìtẹ́ náà, abo ẹyẹ náà sì ń wò ó.

Kó lè pamọ (A), ẹyẹ mallee máa ń lo ooru tó ń wá látara oòrùn àti koríko tó ń jẹrà (B). Bó ṣe máa ń wa iyẹ̀pẹ̀ tó fi bo ẹyin ẹ̀ jáde, tó sì máa ń bò ó pa dà (D), ooru tó wà níbi tó yé ẹyin sí máa ń wà ní ìwọ̀n tó yẹ, ìyẹn nǹkan bí 34 degrees Celsius, ó sì máa ń wà bẹ́ẹ̀ fún ọ̀pọ̀ oṣù. Kí èyí lè ṣeé ṣe, ẹyẹ yìí máa ń fi ẹsẹ̀ wa ọ̀pọ̀lọpọ̀ iyẹ̀pẹ̀ lọ bọ̀ lójoojúmọ́ (E)

Gbogbo ìgbà tí abo ẹyẹ yìí bá fẹ́ yé ẹyin, ṣe ni akọ ẹyẹ náà máa wa iyẹ̀pẹ̀ tí wọ́n dà bo ibi tí wọ́n gbẹ́ fún ẹyin jáde. Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ tí abo náà bá sì yé ẹyin tán, akọ náà máa da iyẹ̀pẹ̀ bò ó pa dà. Abo lè yé ẹyin tó tó márùndínlógójì (35) láti oṣù September sí February.a

Látìgbàdégbà ni ẹyẹ yìí máa ń ki ẹnu bọlẹ̀, kó lè wo bí ìtẹ́ náà ṣe móoru tó. Lẹ́yìn náà, á wá ṣe àtúnṣe tó bá yẹ sí ìtẹ́ náà bí ojú ọjọ́ bá ṣe rí. Bí àpẹẹrẹ:

  • Tó bá ti ń di oṣù September sí November, àwọn ewé àti koríko tó ń jẹrà náà á bẹ̀rẹ̀ sí í mú kí ìtẹ́ náà móoru ju bó ṣe yẹ lọ. Akọ ẹyẹ náà á wá fi ẹsẹ̀ wa iyẹ̀pẹ̀ tó bo ibi tí wọ́n yé ẹyin sí jáde, kí ooru tó wà níbẹ̀ lè dín kù. Tí iyẹ̀pẹ̀ náà bá ti tutù, á fi bò ó pa dà.

  • Tó bá dìgbà ẹ̀ẹ̀rùn, akọ ẹyẹ náà máa fi kún iyẹ̀pẹ̀ tó wà lórí ibi tí ẹyin náà wà kó lè dáàbò bò ó lọ́wọ́ oòrùn. Àmọ́ tó bá ti di àárọ̀, á wa iyẹ̀pẹ̀ náà kúrò kí ìtẹ́ náà lè tutù, tí ìtẹ́ náà bá ti tutù tó bó ṣe fẹ́, á fi iyẹ̀pẹ̀ ọ̀tọ̀ bò ó pa dà.

  • Tó bá ti ń di oṣù March sí May, ewé àti koríko náà á ti jẹrà tán, kò sì ní móoru mọ́. Akọ ẹyẹ náà á wá kó gbogbo iyẹ̀pẹ̀ tó wà lórí ẹyin náà kúrò kí oòrùn lè ta sí ẹyin náà àti iyẹ̀pẹ̀ ní ọ̀sán. Tó bá yá, á fi iyẹ̀pẹ̀ tí oòrùn ti pa dáadáa náà bo ẹyin náà, ìyẹn á jẹ́ kí ẹyin náà lè móoru lóru mọ́jú.

Lójoojúmọ́, akọ ẹyẹ náà máa ń fi ohun tó lé ní wákàtí márùn-ún ṣiṣẹ́. Iyẹ̀pẹ̀ tó sì máa ń wà lọ wà bọ̀ lójoojúmọ́ máa ń wúwo tó nǹkan bí àpò símẹ́ǹtì mẹ́tàdínlógún (17). Àǹfààní míì wà nínú bó ṣe ń wa iyẹ̀pẹ̀ lọ bọ̀ lójoojúmọ́, ìyẹn ni pé kì í jẹ́ kí iyẹ̀pẹ̀ náà dìpọ̀ débi tó fi máa le, ó sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọmọ ẹyẹ náà láti jáde nínú ẹ̀ tí àkókò bá tó.

Wo bí ẹyẹ mallee ṣe ń fi ẹsẹ̀ wa iyẹ̀pẹ̀ lórí ìtẹ́ rẹ̀

Kí lèrò ẹ? Ṣé ọgbọ́n tí ẹyẹ mallee ń dá láti mú kí ìtẹ́ rẹ̀ móoru kàn ṣàdédé wà ni? Àbí ẹnì kan ló ṣiṣẹ́ àrà yìí?

a Ẹyin ẹyẹ yìí máa ń lò tó ọ̀sẹ̀ méje sí mẹ́jọ kó tó pa. Torí náà, akọ ẹyẹ yìí máa ń ṣiṣẹ́ lórí ìtẹ́ náà títí di nǹkan bí oṣù April.

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́