ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 6-11
  • A Ha Ti Borí Ìjàkadì Náà bí?

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • A Ha Ti Borí Ìjàkadì Náà bí?
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Òtítọ́ Ṣíṣe Kókó Mẹ́ta Nípa Ẹ̀kọ́ Nípa Ibùgbé Àwọn Ohun Alààyè
  • Báwo Ni Ìbàjẹ́ Tí A Ti Ṣe Ti Pọ̀ Tó?
  • Apá Ènìyàn Ha Lè Ká Ìṣòro Náà Bi?
  • Ìgbìyànjú Láti Gba Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Là
    Jí!—1996
  • Àwọn Àlùmọ́ọ́nì Ilẹ̀ Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Run Tán
    Jí!—2005
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 6-11

A Ha Ti Borí Ìjàkadì Náà bí?

“Ẹ TỌ́JÚ pílánẹ́ẹ̀tì yí o, ẹyọ kan náà tí a ní nìyẹn.” Èyí jẹ́ ẹ̀bẹ̀ wíwọni lọ́kàn tí Ọmọọba Philip ará Britain, tí ó jẹ́ ààrẹ Ètò Ìkówójọ Káàkiri Àgbáyé fún Àbójútó Ìṣẹ̀dá ṣe.

Ní ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ṣáájú ìyẹn, olórin náà kọ̀wé pé: “Ọ̀run àní ọ̀run ni ti Olúwa; ṣùgbọ́n ayé ni ó fi fún àwọn ọmọ ènìyàn.” (Orin Dafidi 115:16) Ọlọrun ti fi ayé yìí fún wa gẹ́gẹ́ bí ibùgbé wa, a sì gbọdọ̀ tọ́jú rẹ̀. Gbogbo ohun tí “ecology,” ẹ̀kọ́ nípa ibùgbé àwọn ohun alààyè dá lé lórí nìyẹn.

Ní ti gidi, ọ̀rọ̀ náà, “ecology,” túmọ̀ sí “ẹ̀kọ́ nípa ibùgbé.”a Ìtumọ̀ kan tí ìwé atúmọ̀ èdè The American Heritage Dictionary fún un ni “ẹ̀kọ́ nípa àbájáde búburú tí ọ̀làjú òde òní ń ní lórí àyíká, láti lè dènà rẹ̀ tàbí ṣàtúnṣe rẹ̀ nípa pípèsè ààbò.” Kí a má fọ̀pá pọ̀ọ̀lọ̀pọọlọ pejò, ecology túmọ̀ sí ṣíṣàwárí ìbàjẹ́ tí àwọn ènìyàn ti ṣe àti wíwá ọ̀nà láti ṣàtúnṣe rẹ̀. Kò sí èyí tí ó rọrùn láti ṣe nínú méjèèjì.

Òtítọ́ Ṣíṣe Kókó Mẹ́ta Nípa Ẹ̀kọ́ Nípa Ibùgbé Àwọn Ohun Alààyè

Nínú ìwé rẹ̀ Making Peace With the Planet, Barry Commoner, onímọ̀ nípa àwọn ohun alààyè, dábàá àwọn òfin rírọrùn mẹ́ta nípa ẹ̀kọ́ nípa ibùgbé àwọn ohun alààyè, èyí tí ó ṣàlàyé ìdí rẹ̀ tí ilẹ̀ ayé fi rọrùn láti lò ní ìlòkulo tó bẹ́ẹ̀.

Gbogbo nǹkan ló so kọ́ra wọn lọ. Gan-an gẹ́gẹ́ bí eyín kan tí ó bà jẹ́ ṣe lè nípa lórí gbogbo ara, bẹ́ẹ̀ ní ìbàjẹ́ tí a ń ṣe sí ohun àmúsọrọ̀ àdánidá pàtó kan ṣe lè tanná ran ìsokọ́ra jàn-ànràn jan-anran àwọn ìṣòro àyíká.

Fún àpẹẹrẹ, ní 40 ọdún tí ó kọjá, wọ́n ti gé àádọ́ta ìpín nínú ọgọ́rùn-ún lára igbó Nepal, ní Himalaya lulẹ̀, nítorí igi ìdáná tàbí nítorí àwọn ohun tí à ń fi gẹdú ṣe. Níwọ̀n bí a ti gbaṣọ igi rẹ̀ lára rẹ̀, gbogbo iyẹ̀pẹ̀ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè náà ni ó wọ́ lọ nígbà tí òjò ẹlẹ́fùúùfù dé. Láìsí yanrìn tí ó wà lókè yẹ̀pẹ̀, àwọn igi tuntun kò lè tètè fẹkàn múlẹ̀, ọ̀pọ̀ àwọn òkè sì di aṣálẹ̀. Nítorí igbó pípa run, Nepal ń pàdánù àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tọ́ọ̀nù àwọn yanrìn tí ó wà lókè yẹ̀pẹ̀ lọ́dún báyìí. Ìṣòro náà kò sì mọ sí Nepal nìkan.

Ní Bangladesh, òjò tí ó máa ń ya gbùúgbùú, tí àwọn igi máa ń fà mu tẹ́lẹ̀, ń ya kọjá àwọn òkè tí a ti sọ sí ìhòhò goloto náà, lọ sí ìhà etíkun, níbi tí ó ti ń fa ìkún omi alájàálù, láìsí ìdádúró kankan. Láyé àtijọ́, Bangladesh máa ń ní àkúnya omi lẹ́ẹ̀kan ní gbogbo 50 ọdún; nísinsìnyí, ó máa ń ṣẹlẹ̀ ní gbogbo ọdún 4 tàbí kí ó má tilẹ̀ tó bẹ́ẹ̀.

Ní àwọn ibòmíràn ní ayé, igbó pípa run ti fa ìsọ̀gbẹ́daṣálẹ̀ àti ìyípadà nínú ojú ọjọ́ àdúgbò. Ọ̀kan lásán ni igbó jẹ́ nínú àwọn ohun àmúsọrọ̀ àdánidá tí àwọn ènìyàn ń lò nílò yàwàlù pẹ̀lú àṣejù. Níwọ̀n bí ó ti jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ ni àwọn onímọ̀ nípa ibùgbé àwọn ohun alààyè ṣì mọ̀ nípa ìsokọ́ra ètò kíkàmàmà ìṣiṣẹ́ dídíjúpọ̀ ti àwọn ohun alààyè àti àyíká wọn, a lè má fura sí ìṣòro kan títí tí yóò fi ṣe ìbàjẹ́ lílé kenkà. Èyí jẹ́ òtítọ́ nínú ọ̀ràn dída pàǹtírí nù, èyí tí ó máa ń ṣàpẹẹrẹ òfin kejì ti ẹ̀kọ́ nípa àwọn ibùgbé àwọn alààyè, lọ́nà tí ó dára.

Gbogbo nǹkan ní láti darí gba ibì kan. Ronú nípa bí ilé gidi kan yóò ti rí bí a kì í bá da ìdọ̀tí nù. Irú ìṣètò báyẹn gan-an ni pílánẹ́ẹ̀tì wa—gbogbo àwọn pàǹtírí wa gbọ́dọ̀ bórí já ibì kan ní ilé ayé. Dídà tí ìpele ozone di àjákù fi hàn pé, àní àwọn afẹ́fẹ́ tí wọ́n tilẹ̀ dà bí èyí tí kò lè pani lára, irú bí àwọn chlorofluorocarbon (CFC), kì í ṣe ohun tí afẹ́fẹ́ kàn ń gbé lọ lásán láú bẹ́ẹ̀. Ọ̀kan lásán ni CFC jẹ́ nínú ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ohun tí ó lè di eléwu tí à ń tú sójú òfuurufú, sínú odò, àti sínú òkun.

Òtítọ́ ni pé, àwọn ohun èèlò kan—tí a pè ní “èyí tí ó le rà”—lè jẹra bí ó bá yá, kí àwọn ìṣiṣẹ́ ìṣẹ̀dá sì gbé e jẹ, àmọ́ àwọn kan kò lè ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn oríṣiríṣi gologóló oníke, tí yóò máa wà nílẹ̀ fún àwọn ẹ̀wádún tí ń bọ̀ ti ba àwọn òkun ayé jẹ́. Àwọn pàǹtírí onímájèlé ti ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ, tí a sábà máa ń wá ibì kan bò ó mọ́lẹ̀ sí, kò fi bẹ́ẹ̀ hàn síta. Bí kò tilẹ̀ sí níbi tí ojú ti lè rí i, kò sí ìdánilójú pé a ó gbàgbé rẹ̀ pátápátá. Ó ṣì lè ṣàn wọnú àwọn omi tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀, kí ó sì fa àwọn ewu ìlera lílé kenkà fún àwọn ènìyàn àti ẹranko. Onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ Hungary kan ní Ilé Ẹ̀kọ́ Nípa Omi ti Budapest, sọ pé: “A kò mọ ohun tí a lè ṣe pẹ̀lú gbogbo àwọn kẹ́míkà tí ilé iṣẹ́ òde òní ń mú jáde. A kò tilẹ̀ lè tọpa gbogbo wọn tán.”

Ìdọ̀tí líléwu jù lọ nínú gbogbo wọn ni pàǹtírí ìtànṣán olóró, ohun kan tí àwọn ilé iṣẹ́ iná mànàmáná ń mú jáde. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún tọ́ọ̀nù pàǹtírí olóró ni wọ́n ń kó pamọ́ síbì kan fún ìgbà ráńpẹ́, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ti kó àwọn kan dà sínú òkun. Láìka ìwádìí ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ tí wọ́n ti ṣe fún ọ̀pọ̀ ọdún sí, kò tí ì sí ojútùú kankan tí wọ́n ṣàwárí rẹ̀ fún kíkó pàǹtírí pamọ́ tàbí kíkó o dànù lọ́nà tí ó láàbò, tí ó sì wà pẹ́ títí, bẹ́ẹ̀ ni kò sì sí ọ̀kankan tí ó ṣeé rí pé yóò wà fún ọjọ́ ọ̀la. Kò sí ẹni tí ó mọ ìgbà tí ìbọn tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ibùgbé àwọn ohun alààyè yìí yóò bú gbàù. Ó dájú pé ìṣòro náà kò ní tán nílẹ̀—pàǹtírí ìtànṣán olóró yóò máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tàbí ẹgbẹẹgbẹ̀rúndún tí ń bọ̀, tàbí títí di ìgbà tí Ọlọrun yóò gbé ìgbésẹ̀. (Ìṣípayá 11:18) Kíkà tí àwọn ènìyàn kò ka ọ̀ràn ìdapàǹtírí nù sí tún jẹ́ ìránnilétí kan nípa òfin kẹta ti ẹ̀kọ́ nípa ibùgbé àwọn ohun alààyè.

Ẹ fi ìṣẹ̀dá lọ́rùn sílẹ̀. Ní èdè míràn, ó yẹ kí àwọn ènìyàn fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn ìṣètò ìṣẹ̀dá, dípò tí wọn ì bá fi máa gbìyànjú láti ré wọn kọjá pẹ̀lú ohun kan tí wọ́n rò pé ó sàn jù. Àwọn oògùn apakòkòrò kan jẹ́ àpẹẹrẹ èyí. Nígbà tí a kọ́kọ́ gbé wọn jáde, wọ́n mú kí ó ṣeé ṣe fún àwọn àgbẹ̀ láti pa oko, tí ó sì jẹ́ pé gbogbo àwọn kòkòrò ajẹkorun ni wọ́n fẹ́rẹ̀ẹ́ pa tán. Ó dà bí ẹni pé wọ́n mú àwọn irè oko bọ̀ọ̀lìbọ̀ọ̀lì dá àwọn ènìyàn lójú. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó yá, gbogbo rẹ̀ dà rú. Àwọn èpò àti kòkòrò bẹ̀rẹ̀ sí í pe oògùn apakòkòrò kan tẹ̀lé òmíràn lékèé, ó sì wá hàn kedere pé àwọn oògùn apakòkòrò náà ń kó májèlé bá àwọn ẹ̀dá tí ń pa àwọn kòkòrò náà, àwọn ẹranko, àti àwọn ènìyàn pàápàá fúnra wọn. Bóyá májèlé oògùn apakòkòrò ti kó bá ìwọ náà. Tí ó bá rí bẹ́ẹ̀, o jẹ́ ọ̀kan lára, ó kéré tán, àádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn tí ó ti kó bá káàkiri àgbáyé.

Ohun tí ó tilẹ̀ wá jáni kulẹ̀ jù lọ pátápátá ni ẹ̀rí tí ń pọ̀ sí i pé, àwọn oògùn apakòkòrò tilẹ̀ lè máà máa mú kí irè oko sunwọ̀n sí i ní paríparí rẹ̀. Ní United States, àwọn kòkòrò ń jẹ apá tí ó pọ̀ jù lọ lára ire oko run nísinsìnyí ju bí wọ́n ti ń ṣe kí wọ́n tó gbé ìjọba oògùn apakòkòrò dé. Bákan náà, Ẹ̀ka Ìwádìí Nípa Ìrẹsì Káàkiri Àgbáyé, tí ó fìdí kalẹ̀ sí Philippines, ti wá rí i pé àwọn oògùn apakòkòrò kò mú kí irè ìrẹsì pọ̀ sí i mọ́ ní apá Gúúsù Ìlà Oòrùn Asia. Ó tilẹ̀ ti ṣeé ṣe fún ètò kan tí ìjọba Indonesia ṣonígbọ̀wọ́ rẹ̀, tí kò gbára lé àwọn oògùn apakòkòrò tán pátápátá láti rí ìlọsókè ìpín mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú ọgọ́rùn-ún nínú iye ìrẹsì tí wọn ń mú jáde láti 1987, láìka pé wọ́n mú kí oògùn apakòkòrò tí wọ́n ń lò lọ sílẹ̀ ní ìwọ̀n ìpín márùndínláàádọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún. Láìka ìyẹn sí, àwọn àgbẹ̀ lágbàáyé ṣì ń lo oògùn apakòkòrò lọ́pọ̀ yanturu síbẹ̀ lọ́dọọdún.

Àwọn òfin mẹ́ta ti ẹ̀kọ́ nípa ibùgbé àwọn ohun alààyè tí a mẹnu kan lókè yìí, ràn wá lọ́wọ́ láti ṣàlàyé ìdí tí nǹkan fi ń dojú rú. Àwọn ìbéèrè ṣíṣe kókó mìíràn ni pé, Báwo ni ìbàjẹ́ tí a ti ṣe tẹ́lẹ̀ ti pọ̀ tó, a ha sì le ṣàtúnṣe rẹ̀ bí?

Báwo Ni Ìbàjẹ́ Tí A Ti Ṣe Ti Pọ̀ Tó?

Àwòrán ilẹ̀ ayé tí ó wà lára ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ yìí (wo ojú ìwé 8 sí 9) ṣàfihàn àwọn lájorí ìṣòro bíi mélòó kan àti ibi tí wọ́n le sí jù lọ. Ó dájú pé, nígbà tí àdánù ibùgbé bíbójú mu tàbí àwọn okùnfà míràn bá fa ìparun irú ẹ̀yà àwọn ewéko tàbí ẹranko kan, àwọn ènìyàn kì í lè ṣàtúnṣe ìbàjẹ́ náà. Àwọn ìbàjẹ́ mìíràn—irú bí ìpele ozone tí ó ti bà jẹ́—ti ṣẹlẹ̀ ná. Ìbàyíkájẹ́ tí ń bá a lọ láìdáwọ́ dúró ńkọ́? A ha ti ní ìtẹ̀síwájú nínú ṣíṣàtúnṣe rẹ̀ tàbí ó kéré tán, kí a tilẹ̀ fawọ́ rẹ̀ sẹ́yìn díẹ̀ bí?

Ohun méjì tí ó ṣe pàtàkì jù lọ tí a lè fi wọn bí ìbàjẹ́ ibùgbé àwọn ohun alààyè ti pọ̀ tó ni iṣẹ́ àgbẹ̀ àti iṣẹ́ ẹja pípa. Èé ṣe? Nítorí pé, bí irè tí wọ́n ń mú jáde yóò ti pọ̀ tó sinmi lórí àyíká tí ó dára, àti nítorí pé ìwàláàyè wa sinmi lórí ìpèsè oúnjẹ tí ó ṣeé fọkàn tẹ̀.

Àwọn apá méjèèjì ní ń fi àmí hàn pé àwọ́n ti di èyí tí a bà jẹ́. Àjọ Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Oúnjẹ àti Iṣẹ́ Àgbẹ̀ ti Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè tí ṣírò rẹ̀ pé, gbogbo agbo apẹja lágbàáyé kò lè pa ju ẹja tọ́ọ̀nù 100 mílíọ̀nù láìjẹ́ pé wọ́n wu ìpèsè ẹja léwu lọ́nà tí ó lé kenkà. Wọ́n sì ré kọjá iye náà ní 1989, bí wọ́n sì ṣe ń retí ló ṣe ṣẹlẹ̀, ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e, iye ẹja tí a pa káàkiri àgbáyé fi tọ́ọ̀nù mílíọ̀nù mẹ́rin lọ sílẹ̀. Ìlọsílẹ̀ tí ó wúwo rinlẹ̀ ti wà nínú àwọn ibi tí àwọn ẹja fi ń ṣelé. Fún àpẹẹrẹ, ní ìhà àríwá ìlà oòrùn Atlantic, iye ẹja tí wọn ń pa ti lọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìpín méjìlélọ́gbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún jálẹ̀ 20 ọdún tí ó kọja lọ. Àwọn ohun tí ó jẹ́ lájorí ìṣòro ni àpajù ẹja, sísọ òkun deléèérí, àti pípa ilé ìyẹ́yin àwọn ẹja run.

Nǹkan dídáni níjì yìí tún fara hàn nínú irè oko tí à ń mú jáde. Ní àwọn ọdún 1960 àti 1970, àwọn ẹ̀yà irè oko tí a mú sunwọ̀n sí i pa pọ̀ pẹ̀lú ìbomirin oko àti lílo ọ̀pọ̀ yanturu àwọn oògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀ oníkẹ́míkà mú kí ọkà tí à ń mú jáde lọ sókè lọ́nà tí ó jọjú. Ní báyìí, àwọn oògùn apakòkòrò àti ajílẹ̀ kò gbéṣẹ́ mọ́, àìtó omi àti ìbàyíkájẹ́ sì ń pa kún irè oko tí kò tó nǹkan.

Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye ẹnu tí a ní láti bọ́ ń fi 100 mílíọ̀nù lọ sókè lọ́dún kọ̀ọ̀kan, ní gbogbo ọdún mẹ́wàá tí ó kọjá lọ, ìlọsílẹ̀ ti wà nínú iye gbogbo oko tí à ń dá. Ilẹ̀ tí ó sì dára fọ́gbìn yìí kò fi bẹ́ẹ̀ lọ́ràá mọ́. Ẹ̀ka Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé ṣírò rẹ̀ pé àgbàrá ti mú kí àwọn àgbẹ̀ pàdánù yẹ̀pẹ̀ orí ilẹ̀ tí ó tó 500 bílíọ̀nù tọ́ọ̀nù ní 20 ọdún tí ó kọjá. Níwọ̀n bí kò sì ti ṣeé yẹ̀ sílẹ̀, oúnjẹ tí à ń mú jáde ti bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sílẹ̀. Ìròyìn State of the World 1993 ṣàlàyé pé, “àfàìmọ̀ kí ó máà jẹ́ pé lílọ sílẹ̀ tí ọkà tí ó wà lárọ̀ọ́wọ́tó ẹnì kan lọ sílẹ̀ fún ìpín mẹ́fà nínú ọgọ́rùn-ún láàárín ọdún 1984 sí ọdún 1992 [ni] ọ̀ràn ọ̀rọ̀ ajé dídani láàmú tí ó wọ́pọ̀ jù lọ ní ayé lónìí.”

Ó ṣe kedere pé, ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ènìyàn ti wà nínú ewu ná nítorí kíkà ti àwọn ènìyàn kò ka àyíká sí nǹkan kan.

Apá Ènìyàn Ha Lè Ká Ìṣòro Náà Bi?

Àní bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ènìyàn ti wá ń mọ nǹkan nípa ohun tí ń dojú rú náà báyìí, kò rọrùn láti tún un ṣe. Ìṣòro àkọ́kọ́ ni pé owó tí yóò náni yóò pọ̀—ó kéré tán, 600 bílíọ̀nù dọ́là lọ́dún—láti lè fi àwọn àbá gbígbórín tí a gbé kalẹ̀ níbi Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé ní 1992 sílò. Yóò tún pọn dandan kí wọ́n ṣe àwọn ìrúbọ ṣíṣe kókó—àwọn ìrúbọ irú bíi dídín àwọn nǹkan tí à ń fi ń ṣòfò kù àti ṣíṣàtúnlò ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan sí i, gígán omi àti iná mànàmáná lò, wíwọ àwọn ọkọ̀ èrò dípò níní tara ẹni, àti èyí tí ó tilẹ̀ wá ṣòro jù nínú gbogbo rẹ̀, ríronú nípa pílánẹ́ẹ̀tì dípò àǹfààní tẹni. John Cairns, Jr., alága ìgbìmọ̀ fún ìṣàtúnṣe ètò ìṣiṣẹ́ dídíjúpọ̀ ti àwọn ohun alààyè inú omi àti àyíká wọn, ní United States, ṣàkópọ̀ ìṣòro náà pé: “Mo ń fojú sọ́nà fún ohun tí ó dára nípa ohun tí a lè ṣe. Mò ń fojúsọ́nà fún ohun tí kò dára nípa ohun tí a óò ṣe.”

Ọ̀wọ́ iye tí ìpalẹ̀ẹ̀dọ̀tímọ́ ńláǹlà yóò ná ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn orílẹ̀-èdè pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí wọ́n fi yàn láti ti ọjọ́ ìjíyìn sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan ná. Ní àkókò yánpọnyánrin ti ọrọ̀ ajé, àwọn ìkálọ́wọ́kò tí ó ní í ṣe pẹ̀lú àyíká ní a máa ń wò gẹ́gẹ́ bí ewu fún iṣẹ́ tàbí ohun tí ń fawọ́ agogo ọrọ̀ ajé sẹ́yìn. Ẹnú dùn ún ròfọ́. Ìwé Caring for the Earth ṣàpèjúwe ohun tí ìdáhùpadà àwọn ènìyàn ti jẹ́ títí di bí a ti ń sọ̀rọ̀ yìí pé, ó dà bí “ọ̀gbáàràgbá ẹnu lásán tí iṣẹ́ kò bá rìn.” Àmọ́ láìka àìfìkanṣèkan yìí sí, ṣé ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ tuntun kò lè wá ìwòsàn tí kò la ìrora lọ fún àwọn àìsàn pílánẹ́ẹ̀tì yìí ni—bí a bá fún un lákòókò? Ó hàn gbangba pé kò ṣeé ṣe.

Nínú àlàyé kan tí Ilé Ẹ̀kọ́ Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ ti Orílẹ̀-Èdè United States àti Ẹgbẹ́ Aláyélúwà ti London jọ sọ, wọ́n sọ ojú abẹ níkòó pé: “Bí àwọn àsọtẹ́lẹ̀ tí wọ́n ń sọ ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí pé iye àwọn ènìyàn yóò lọ sókè sí i bá di òtítọ́, tí ọ̀nà tí àwọn ènìyàn gbà ń ṣe ìgbòkègbodò wọn nínú pílánẹ́ẹ̀tì yìí kò bá sì yí padà, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àti ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ lè má lè dáwọ́ ì báà ṣe ìbàyíkájẹ́ tí kò ṣeé ṣàtúnṣe tàbí ipò òṣì tí ń bá a lọ tí ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn wà nínú rẹ̀ láyé dúró.”

Ìṣòro pàǹtírí olóró, tí kò sí ibi tí a lè kó o dànù sí, tí ń páni láyà jẹ́ ìránnilétí kan pé, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ kì í ṣe ọ̀gbàgbà tí ń gba aráàlú. Fún 40 ọdún, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tí ń wá ibi tí ó láàbò tí wọ́n lè kó àwọn pàǹtírí ìtànṣán olóró onípele gíga pamọ́ sí pátápátá. Ìwádìí dà bí èyí tí ó le tó bẹ́ẹ̀ tí àwọn orílẹ̀-èdè kan, irú bí Itali àti Argentina, fi parí rẹ̀ sí pé àwọn kò lè rí ibì kan títí di ọdún 2040, ó yá tán. Germany, tí ó tilẹ̀ jẹ́ orílẹ̀-èdè tí ó ní ìfojúsọ́nà rere jù lọ nínú ọ̀ràn yìí, nírètí láti parí àwọn ìwéwèé nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2008.

Eé ṣe ti pàǹtírí olóró fi jẹ́ ìṣòro tó bẹ́ẹ̀? Konrad Krauskopf, tí ó jẹ́ onímọ̀ nípa ilẹ̀, ṣàlàyé pé: “Kò sí onímọ̀ ìjìnlẹ̀ tàbí onímọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kan tí ó lè mú un dá wa lójú pé pàǹtírí olóró kò ní rú jáde síta lọ́jọ́ kan ní ìwọ̀n tí ó léwu, àní bí ibi tí a kó o pamọ́ sí ì báà ti wù kí ó dára tó.” Àmọ́ láìka ìkìlọ̀ tí a tètè ń ṣe nísinsìnyí nípa ìṣòro dída pàǹtírí nù sí, àwọn ìjọba àti ilé iṣẹ́ ohun ìjà olóró ń fi orí kunkun bá a lọ, ní rírò pé ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ọjọ́ ọ̀la yóò mú ojútùú kan wá. Ojútùú náà kò fìgbà kan dé.

Bí ìmọ̀ iṣẹ́ ẹ̀rọ kò bá rí ojútùú pàjáwìrì kan sí yánpọnyánrin àyíká, àwọn yíyàn míràn wo ló tún kù? Pípọn dandan tí ó pọn dandan yóò ha mú àwọn orílẹ̀-èdè lápàpàǹdodo láti ṣiṣẹ́ pa pọ̀ kí wọ́n lè dáàbò bo pílánẹ́ẹ̀tì yìí bí?

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti inú ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà, oiʹkos (ilé, ibùgbé) àti lo·giʹa (ẹ̀kọ́).

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 7]

Wíwá Orísun Àwọn Ohun Àmúṣagbára Tí Ó Ṣeé Sọ Dọ̀tun Kiri

Ọ̀pọ̀ nínú wa kì í ka ohun àmúṣagbára sí bàbàrà—àfìgbà tí iná bá lọ tàbí ti epo bá léwó. Bí ó ti wù kí ó rí, ohun àmúṣagbára tí à ń lò jẹ́ okùnfà gíga jù lọ fún ìbàyíkájẹ́. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn ohun àmúṣagbára tí à ń lò ń wá láti ara igi tí à ń jó nínà tàbí láti ara àkẹ̀kù igi tàbí ẹranko, ọ̀nà yìí sì máa ń mú kí àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tọ́ọ̀nù afẹ́fẹ́ carbon dioxide tú sínú afẹ́fẹ́, ó sì máa ń pa igbó ayé run.

Ohun àmúṣagbára tí ń wá láti inú átọ́míìkì tí ó tún jẹ́ yíyàn míràn ti wá ń di èyí tí kò fi bẹ́ẹ̀ gbayì mọ́ sí i, nítorí ewu ìjàm̀bá àti ìṣòro kíkó àwọn pàǹtírí ìtànṣán olóró pamọ́. Yíyàn míràn ni a mọ̀ sí orísun ohun àmúṣagbára tí ó ṣeé sọ dọ̀tun, níwọ̀n bí wọ́n ti ń ṣàmúlò àwọn orísun àwọn ohun àmúṣagbára àdánidá tí ó wà káàkiri lọ́fẹ̀ẹ́lófò. Àwọn wọ̀nyí pín sí oríṣi pàtàkì márùn-ún.

Ohun àmúṣagbára tí ń wá láti inú oòrùn. A lè lo èyí tìrọ̀rùn tìrọ̀rùn láti mú nǹkan gbóná, àti ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, irú bí Israeli, ọ̀pọ̀ ilé ní àwọn ohun ìkọ́lé tí ó ní ohun àmúṣagbára tí ń wa láti inú oòrùn, fún mímú omi wọn gbóná. Fífi oòrùn mú iná mànàmáná jáde ṣòro gan-an ni, ṣùgbọ́n ní báyìí ná, àwọn ọgbọ́n ìhùmọ̀ tí ó ní í ṣe pẹ̀lú ohun àmúṣagbára oòrùn ti ń pèsè iná mànàmáná ní àwọn agbègbè kan, wọ́n sì ti wá ń di ohun tí ń dínni lówó kù sí i.

Ohun àmúṣagbára tí ń wá láti inú ẹ̀fúùfù. Ní báyìí, àwọn ẹ̀rọ àfatẹ́gùnyípo gìrìwò gìrìwò pọ̀ káàkiri ní ọ̀pọ̀ àwọn ibi tí ọwọ́ ẹ̀fúùfù ti máa ń le ní ayé. Owó tí iná mànàmáná, tí ohun àmúṣagbára tí ń wá láti inú ẹ̀fúùfù yìí, gẹ́gẹ́ bí àwọn ènìyàn ṣe máa ń pè é, ń mú jáde ń náni, ti lọ sílẹ̀ gẹ̀rẹ̀gẹ̀rẹ̀, ó sì dínwó ju àwọn ìpèsè ohun àmúṣagbára tí a ti mọ̀ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ lọ ní àwọn apá ibì kan.

Iná mànàmáná tí omi ń mú jáde. Ìpín ogún nínú ọgọ́rùn-ún gbogbo iná mànàmáná ayé ń wá láti ilé iṣẹ́ iná mànàmáná tí omi ń mú jáde, àmọ́, ó bani nínú jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ nínú àwọn àyíká tí ó dára ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti gòkè àgbà ni wọ́n ti jẹ run tán. Àwọn ìsédò gbàǹgbà-gbàǹgbà pẹ̀lú lè ṣe ìbàjẹ́ tí ó pọ̀ díẹ̀ sí ibùgbé àwọn ohun alààyè. Ó dà bí ẹni pé ohun tí ó tún sàn díẹ̀, pàápàá jù lọ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà, ni kí wọ́n kọ́ àwọn ilé iṣẹ́ iná mànàmáná kéékèèké.

Ohun àmúṣagbára tí ń wá láti inú ooru abẹ́ ilẹ̀. Ó ti ṣeé ṣe fún àwọn orílẹ̀-èdè kan, ní pàtàkì jù lọ, Iceland àti New Zealand, láti ṣàmúlò “ọ̀nà ìmómigbóná” tí ó wà nínú ilẹ̀. Àwọn ooru tí òke ayọnáyèéfín tí ó wà ní abẹ́ ilẹ̀ ń yọ máa ń mú omi gbóná, èyí sì ni a lè lò láti mú ilé móoru àti láti mú iná mànàmáná wọlé. Itali, Japan, Mexico, Philippines àti United States náà ti ń ṣàmúlò orísun ohun àmúṣagbára àdánidá yìí dé ìwọ̀n kan.

Ohun àmúṣagbára tí ìṣa òun ìyọ omi ń mú jáde. Wọ́n ń lo ìṣa òun ìyọ omi láti fa iná mànàmáná wọlé ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, irú bíi Britain, Faransé àti Rọ́síà. Bí ó tiwù kí ó rí, ibi kéréje ní ayé ni o ti lè rọrùn, tí yóò sì gbéṣẹ́ láti pèsè irú ohun àmúṣagbára yìí ní iye tí owó rẹ̀ kò ní pọ̀.

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Díẹ̀ Lára Àwọn Lájorí Ìṣòro Àyíká Ayé

Pípa igbó run. A ti pàdánù ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin igbó tí ó wà níbi tí ojú ọjọ́ ti dára, ìlàjì igbó ilẹ̀ olóoru àgbáyé, ìwọ̀n tí àwọn ènìyàn sì gbà ń pagbó run ti lọ sókè lọ́nà tí ń páni láyà ní ẹ̀wádún tí ó kọjá yìí. Ìṣirò lọ́ọ́lọ́ọ́ ti igbó olóoru tí à ń pa run jẹ́ nǹkan bí 150,000 sí 200,000 kìlómítà níbùú lóròó lọ́dún, ó fẹ́rẹ̀ẹ́ tóbi tó Uruguay.

Pàǹtírí onímájèlé. Ìdajì kẹ́míkà 70,000 tí wọ́n ń mú jáde ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí ni a kà sí májèlé. United States nìkan ń mú tọ́ọ̀nù pàǹtírí onímájèlé tí ó jẹ́ 240 mílíọ̀nù jáde lọ́dọọdún. Àìsí àkọsílẹ̀ kò mú kí ó ṣeé ṣe láti ṣírò iye tí àpapọ̀ gbogbo rẹ̀ jẹ́ lágbàáyé. Ní àfikún, nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000, pàǹtírí ìtànṣán olóró tí a ti kó pamọ́ síbì kan fún àkókó ráńpẹ́ ná yóò fẹ́rẹ̀ẹ́ tó 200,000 tọ́ọ̀nù.

Bíba ilẹ̀ jẹ́. À ń fi igbó píparun wu ìdámẹ́ta orí ilẹ̀ ayé léwu. Ní àwọn apá ibì kan ní Africa, Aṣálẹ̀ Sahara ti gbòòrò tó 350 kìlómítà ní kìkì 20 ọdún. Ná, ìgbésí ayé àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ènìyàn ti wà nínú ewu.

Àìtó omi. Nǹkan bíi bílíọ̀nù méjì ènìyàn ní ń gbé ní àwọn agbègbè tí àìtó omi ti rinlẹ̀ gbingbin. Ohun tí ó tún wá jẹ́ kí àìtó omi náà lọ sókè ni gbígbẹ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn kànga ń gbẹ nítorí àwọn ihò omi abẹ́ ilẹ̀ tí ń lọ sílẹ̀ sí i.

Àwọn ẹ̀yà ohun alààyè wà nínú ewu àkúrun. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé iye náà jẹ́ èyí tí a finú rò lọ́nà kan, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ fojú díwọ̀n pé nǹkan bíi 500,000 sí 1,000,000 ẹ̀yà ẹranko, ewéko, àti kòkòrò ni yóò ti di àkúrun nígbà tí yóò bá fi di ọdún 2000.

Bíba àyíká jẹ́. Ìwádìí kan tí àjọ Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè ṣe ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1980 ṣírò rẹ̀ pé bílíọ̀nù kan àwọn ènìyàn ní ń gbé ní ìlú ńlá tí ó ṣí payá sí ìwọ̀n èéfín tàbí afẹ́fẹ́ onímájèlé tí ó lè sọni di aláàárẹ̀, irú bíi sulfur dioxide, nitrogen dioxide, àti carbon monoxide. Láìsí iyè méjì, títóbi tí àwọn ìlú ńlá ń yára tóbi sí i ní ẹ̀wádún tí ó kọjá yìí ti mú kí ìṣòro náà burú sí i. Síwájú sí i, tọ́ọ̀nù carbon dioxide bílíọ̀nù 24 ni à ń tú sínú afẹ́fẹ́ lọ́dọọdún, àwọn ènìyàn sì ń bẹ̀rù pé “afẹ́fẹ́ ooru ilẹ̀ ayé” náà lè jẹ́ ìkìlọ̀ kan fún gbogbo àgbáyé.

[Àwòrán ilẹ̀]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Pípa igbó run

Pàǹtírí olóró

Bíba àyíká jẹ́

Àìtó omi

Irú ẹ̀yà àwọn ohun alààyè wà nínú ewu

Bíba ilẹ̀ jẹ́

[Àwọn Credit Line]

Mountain High Maps™ copyright© 1993 Digital Wisdom, Inc.

Fọ́tò: Hutchings, Godo-Foto

Fọ́tò: Mora, Godo-Foto

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́