ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍNTÁNẸ́Ẹ̀TÌ ti Watchtower
ÀKÁ ÌWÉ ORÍ ÍŃTÁNẸ́Ẹ̀TÌ
ti Watchtower
Yorùbá
ọ́
  • ẹ
  • ọ
  • ṣ
  • ń
  • ẹ́
  • ẹ̀
  • ọ́
  • ọ̀
  • BÍBÉLÌ
  • ÌTẸ̀JÁDE
  • ÌPÀDÉ
  • g96 1/8 ojú ìwé 3-5
  • Ìgbìyànjú Láti Gba Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Là

Kò sí fídíò kankan ní apá yìí.

Má bínú, fídíò yìí kò jáde.

  • Ìgbìyànjú Láti Gba Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Là
  • Jí!—1996
  • Ìsọ̀rí
  • Àpilẹ̀kọ Míì Tó Jọ ọ́
  • Ewu Tí Ń Ga Sí I
  • Ìgbìyànjú Láti Dáàbò Bo Pílánẹ́ẹ̀tì
  • A Ha Ti Borí Ìjàkadì Náà bí?
    Jí!—1996
  • Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Ẹlẹgẹ́—Báwo Ni Ọjọ́ Ọ̀la Yóò Ṣe Rí?
    Jí!—1996
  • Ì Bá Dára Ká Ní Afẹ́fẹ́ Mímọ́ Gaara Díẹ̀!
    Jí!—1996
  • Ojú Ọjọ́ Júujùu
    Jí!—1998
Àwọn Míì
Jí!—1996
g96 1/8 ojú ìwé 3-5

Ìgbìyànjú Láti Gba Pílánẹ́ẹ̀tì Wa Là

LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYÌN JÍ! NÍ SPANIA

YURY, tí ń gbé ní ìlú ńlá Karabash ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà, ní ọmọ méjì, àwọn méjèèjì ló sì ń ṣàìsàn. Ó kó ìdààmú bá a, àmọ́ kò yà á lẹ́nu. Ó ṣàlàyé pé: “Kò sọ́mọ tó lera níhìn-ín.” Wọ́n ń fún àwọn ènìyàn Karabash ní májèlé jẹ. Lọ́dọọdún, ilé iṣẹ́ àdúgbò kan máa ń tú 162,000 tọ́ọ̀nù èérí sínú afẹ́fẹ́—ní ìpíndọ́gba tọ́ọ̀nù 9 fún ọkùnrin, obìnrin, àti ọmọdé kọ̀ọ̀kan tí ń gbé níbẹ̀. Ní Nikel àti Monchegorsk, níbi Ìyawọlẹ̀ Omi Kola, tí ó wà ní ìhà àríwá Arctic Circle, “méjì lára àwọn ilé iṣẹ́ tí a ti ń yọ́ nickel tí ó tóbi jù lọ, tí ó sì lọ́jọ́ lórí jù lọ lágbàáyé . . . ń tú ògidì mẹ́táàlì àti sulfur dioxide púpọ̀ sí i sínú afẹ́fẹ́ lọ́dọọdún ju bí àwọn ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ mìíràn tí wọ́n rí bẹ́ẹ̀ ṣe ń ṣe ní ilẹ̀ Rọ́ṣíà.”—The New York Times.

Afẹ́fẹ́ ti Ìlú Ńlá Mexico náà kò sàn. Ìwádìí kan tí Dokita Margarita Castillejos ṣe ṣàwárí pé, ní àwọn agbègbè tí àwọn ọlọ́rọ̀ tilẹ̀ wà ní ìlú ńlá náà pàápàá, àwọn ọmọdé máa ń ṣàìsàn ọjọ́ 4 nínú ọjọ́ 5. Ó sọ pé: “Sí wọn, láti máa ṣàìsàn ti di ọmọ ìyá ara wọn.” Ó sọ pé, ọ̀kan lára àwọn lájorí ohun tí wọ́n di ẹ̀bi náà rù ní, arukutu èéfín tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn ọkọ̀, tí ó bo òpópónà ìlú náà pitimọ, ń mú jáde. Àwọn èérí tí ó kóra jọ síbi ìpele ozone ti fi ìlọ́po mẹ́rin ré kọjá ààlà tí Ètò Àjọ Ìlera Àgbáyé gbé kalẹ̀.

Ní Australia, ewu náà kò ṣeé rí—àmọ́ gbẹ̀mígbẹ̀mí ni òun náà bákan náà. Ó di dandan fún àwọn ọmọdé báyìí láti máa dé fìlà nígbà tí wọ́n bá ń ṣeré ní pápá ìṣiré ilé ìwé. Ìbàjẹ́ tí ó ti ṣe sí ara ìji ìdáàbòboni ozone ní Gúúsù Ìlàjì Ayé ti mú kí àwọn ará Australia máa bẹ̀rẹ̀ sí í wo oòrùn gẹ́gẹ́ bí ọ̀tá, dípò ọ̀rẹ́. Wọ́n tilẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í ní ìlọsókè jẹjẹrẹ ara onílọ̀ọ́po mẹ́ta.

Ní àwọn apá ibòmíràn ní ilẹ̀ ayé, rírí omi tí ó tó jẹ́ ìjàkadì ojoojúmọ́ kan. Nígbà tí Amalia jẹ́ ọmọ ọdún 13, ọ̀dá bẹ́ sílẹ̀ ní Mozambique. Agbára káká ni wọ́n fi rí omi tí ó tó fún ọdún àkọ́kọ́, eku káká ni wọ́n sì fi rí rárá ní ọdún tí ó tẹ̀ lé e. Àwọn ewébẹ̀ rọ, wọ́n sì kú. Ó di dandan kí Amalia àti ìdílé rẹ̀ máa jẹ èso ìgbẹ́, tí wọ́n sì ń walẹ̀ etí odò láti lè rí omi dídára èyíkéyìí tí wọ́n bá lè rí.

Ní Rajasthan, ìpínlẹ̀ kan ní India, pápá ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pòórá tán. Phagu, tí ó jẹ́ ẹ̀yà àwọn alákòókiri, sábà máa ń ní èdèkòyedè pẹ̀lú àwọn àgbẹ̀ àdúgbò. Kò rí koríko fún agbo àwọn àgùntàn àti ewúrẹ́ rẹ̀. Nítorí àìsí ilẹ̀ ọlọ́ràá rárá, ìbágbépọ̀ àlálàáfíà tí ó ti wà láàárín àwọn àgbẹ̀ àti àwọn alákòókiri fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ti bàjẹ́.

Ọ̀ràn náà tilẹ̀ burú jù ní Sahel, sàkáánì kan níbi tí òjò kò ti fi bẹ́ẹ̀ pọ̀, ní ìhà gúúsù Sahara ní Africa. Nítorí igbó pípa run àti ọ̀dá tí ó tẹ̀ lé e, gbogbo agbo màlúù ti kú, àìmọye ahéré sì ti pòórá mọ́lẹ̀ aṣálẹ̀ tí ń gbòòrò sí i náà. Àgbẹ̀ kan tí ó jẹ́ Fulani tí ó wá láti Niger, lẹ́yìn tí ó rí i tí ọkà bàbà rẹ̀ jóná mọ́lẹ̀ ní ìgbà keje, sọ pé: “N kò ní gbin nǹkankan mọ́.” Àìsí koríko ṣẹ̀ṣẹ̀ pa màlúù rẹ̀ ni.

Ewu Tí Ń Ga Sí I

Ohun kan ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ lókè ọ̀dá, ọ̀gbìn tí ń jóná mọ́lẹ̀, àti afẹ́fẹ́ tí a ti sọ deléèérí tí ó ń díni lọ́fun ní gbogbo ìlú ńlá ńlá, tí à ń rí ní lọ́ọ́lọ́ọ́ yìí. Àmì pílánẹ́ẹ̀tì kan tí ń ṣàìsàn ni wọ́n jẹ́, pílánẹ́ẹ̀tì kan tí kò lè kojú gbogbo àlòjù tí àwọn ènìyàn ń lò ó mọ́.

Kò sí ohun tí ó tún ṣe pàtàkì fún ìwàláàyè wa ju afẹ́fẹ́ tí à ń mí sínú, oúnjẹ tí à ń jẹ, àti omi tí à ń mu lọ. Láìsọsẹ̀, àwọn ohun pàtàkì tí ń gbé ìwàláàyè ró yìí ni—àwọn ènìyàn fúnra wọn—ń sọ deléèérí tàbí tí wọ́n tilẹ̀ ń run díẹ̀díẹ̀. Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, ipò tí àyíká wà ti di èyí tí ń wu ìwàláàyè léwu ná. Gẹ́gẹ́ bi ààrẹ Soviet tẹ́lẹ̀ rí, Mikhail Gorbachev, ti sọ ọ́ ní kedere, “ìṣòro ibùgbé àwọn ohun alààyè ti gbá wa lọ́rùn mú ṣínkún.”

Ewu náà kì í ṣe èyí tí a lè fi ọwọ́ yẹpẹrẹ mú. Iye àwọn olùgbé ayé ń lọ sókè ṣáá, àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì tí a sì nílò ń lọ́po sí i. Lester Brown, ààrẹ Ẹ̀ka Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Àgbáyé, sọ láìpẹ́ yìí pé, “ewu bíburú jù lọ fún ọjọ́ ọ̀la wa kì í ṣe jàgídíjàgan àwọn ológun, àmọ́ ìbàyíká pílánẹ́ẹ̀tì wa jẹ́.” A ha ń ṣe nǹkan tí ó mọ́yán lórí láti lè yí ọ̀ràn ìbànújẹ́ náà padà bí?

Ìgbìyànjú Láti Dáàbò Bo Pílánẹ́ẹ̀tì

Ó ṣòro láti ran ọ̀mùtí kan tí ó gbà gbọ́ pé òun kò ní ìṣòro àmujù lọ́wọ́. Bákan náà, ìgbésẹ̀ àkọ́kọ́ láti lè mú kí ara pílánẹ́ẹ̀tì wá yá ni, láti mọ bí àrùn náà ṣe rinlẹ̀ tó. Ó ṣeé ṣe kí ó jẹ́ pé ìmọ̀ ẹ̀kọ́ ni àṣeyọrí kíkàmàmà jù lọ nípa àyíká ní ọdún àìpẹ́ yìí. Ọ̀pọ̀ àwọn ènìyàn lónìí mọ̀ dáradára pé a ti jẹ ìfun àti ẹ̀dọ̀ ilẹ̀ ayé tán, a sì ti sọ ọ́ deléèérí—àti pé a gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan nípa rẹ̀. Ewu ìbàyíkájẹ́ tilẹ̀ ń fì dùgbẹ̀dùgbẹ̀ ju ewu ogun ọ̀gbálẹ̀gbaràwé lọ.

Àwọn aṣáájú lágbàáyé kò ṣàìmọ̀ nípa ìṣòro náà. Nǹkan bí àwọn olórí orílẹ̀-èdè 118 ló pésẹ̀ síbí Àpérò Nípa Ọ̀ràn Ilẹ̀ Ayé ní 1992, nígbà tí wọ́n gbé ìgbésẹ̀ bíi mélòó kan láti lè dáàbò bo òfuurufú àti àwọn ọrọ̀ àlùmọ́nì ilẹ̀ ayé tí ń joro. Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè fọwọ́ sí ìwé àdéhùn kan nípa ojú ọjọ́, nínú èyí tí wọ́n ti fohùn ṣọ̀kan láti gbé ìṣètò kan kalẹ̀ láti máa fi sọ ìyípadà nínú carbon tí ń tú jáde, pẹ̀lú ète mímú kí gbogbo èyí tí ń tú jáde wà bákan náà ní ọjọ́ iwájú. Wọ́n tún ronú nípa àwọn ọ̀nà tí wọ́n lè gbà dáàbò bo ìjóníran-ànǹran àwọn ohun alààyè, àpapọ̀ iye àwọn ẹ̀yà ewéko àti ẹranko. Wọn kò lè fohùn ṣọ̀kan lórí dídáàbò bo àwọn ẹgàn àgbáyé, àmọ́ àpérò náà gbé ìwé àkọsílẹ̀ méjì jáde—“Ẹ̀jẹ́ Rio” àti “Ajẹnda 21,” tí ó ní àwọn ìtọ́sọ́nà lórí bí ọwọ́ àwọn orílẹ̀-èdè ṣe lè tẹ “ìtẹ̀síwájú onígbà pípẹ́ títí” nínú.

Gẹ́gẹ́ bí onímọ̀ nípa àyíká, Allen Hammond, ti ṣàlàyé, “àdánwò tí ó le koko jù lọ ni ti bóyá wọn yóò pa àdéhùn tí wọ́n ṣe ní Rio mọ́—bóyá àwọn ọ̀rọ̀ onígboyà tí wọ́n sọ yóò sún wọn gbé ìgbésẹ̀ ní àwọn oṣù àti ọdún tí ń bẹ níwájú.”

Bí ó ti wù kí ó rí, ìgbésẹ̀ pàtàkì kan tí wọ́n gbé ni ti Ìwé Ẹ̀jẹ́ Àdéhùn Montreal ti 1987, èyí tí o ní àdéhùn tí gbogbo orílẹ̀-èdè ṣe láti dáwọ́ ṣíṣe àwọn chlorofluorocarbon (CFC) dúró láàárín ààlà àkókó kan tí wọ́n fi lélẹ̀.a Kí ló fa àníyàn náà? Nítorí pé, wọ́n sọ pé, CFC máa ń dá kún yíyára tí ìpele adáàbòboni ozone yára máa ń bà jẹ́. Ozone tí ó wà ní òkè pátápátá ojú sánmà máa ń ṣe ribiribi nínú sísẹ́ àwọn ìtànṣán olóró oòrùn, èyí tí ó lè fa jẹjẹrẹ ara àti ẹbọ́ ojú. Èyí kì í ṣe ìṣòro ní kìkì Australia nìkan. Láìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ṣàwárí pé, ìpele ozone ìgbà òtútù joro ní nǹkan bí ìpín mẹ́jọ nínú ọgọ́rùn-ún, lókè àwọn agbègbè tí òjò kì í ti í fi bẹ́ẹ̀ rọ̀ kan ní Àríwá Ìlàjì Ayé. Ogún mílíọ̀nù tọ́ọ̀nù CFC ló tilẹ̀ ti fẹ́ lọ sójú sánmà lókè lọ́hùn-ún.

Níwọ̀n bí ìbàyíkájẹ́ gígogò yìí ti ko àwọn orílẹ̀-èdè ayé lójú, wọ́n ti gbé àwọn èdèkòyedè wọn tì sẹ́gbẹ̀ẹ́ kan, wọ́n sì ti gbé ìgbésẹ̀ tí ó ṣe gúnmọ́. Ìgbésẹ̀ míràn tí ó jẹ́ káàkiri orílẹ̀-èdè tún ń bọ̀ lọ́nà láti dáàbò bo àwọn ẹ̀yà ewéko àti ẹranko tí ó wà nínú ewu, láti dáàbòbo Antarctica, àti láti ṣèkáwọ́ bí pàǹtírí olóró ti ń lọ kiri.

Ọ̀pọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè ń gbé ìgbésẹ̀ láti mú kí àwọn odò wọn wà ní mímọ́ (àwọn ẹja salmon tún ti padà sí Odò Thames ní England lẹ́ẹ̀kan sí i báyìí), láti ṣèkáwọ́ bíba afẹ́fẹ́ jẹ́ (ó ti lọ sílẹ̀ pẹ̀lú ìpín mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún ní àwọn ìlú ńlá ńlá United States tí wọ́n ní arukutu èéfín tí ó burú jù lọ), láti lè ṣàmúlò àwọn orísun agbára tí ń mú ẹ̀rọ ṣiṣẹ́ tí kò fi púpọ̀ le jù fún àyíká (ìpín ọgọ́rin nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ilé tí ó wà ní Iceland ni à ń fi agbára ẹ̀rọ tí ń wá láti inú ooru abẹ́ ilẹ̀ mú gbóná), kí wọ́n baà sì lè pa àwọn ohun ìní àdánidá wọn mọ́ (Costa Rica àti Namibia ti yí nǹkan bí ìpín méjìlá nínú ọgọ́rùn-ún lára gbogbo ilẹ̀ wọn padà sí ọgbà ìtura).

Ìwọ̀nyí ha jẹ́ àmì tí ó dára láti fi hàn pé aráyé ti ń fi ọwọ́ gidi mú ewu náà bí? Ṣé kò ní pẹ́ mọ́ tí pílánẹ́ẹ̀tì wa yóò fi padà bọ̀ sípò dídára? Àwọn ọ̀rọ̀ ẹ̀kọ́ tí ó tẹ̀ lé e yóò wọ́nà láti dáhùn àwọn ìbéèrè wọ̀nyí.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wọ́n máa ń lo CFC lọ́pọ̀ yanturu láti fi ṣe nǹkan fínfín tí a ṣe pa sínú agolo, ẹ̀rọ amúǹkantutù, àwọn ẹ̀rọ amúlétutù, àwọn èròjà tí a fi ń nu nǹkan, àti láti fi ṣe fùkẹ̀fùkẹ̀ àfiboǹkan. Wo Jí! ti December 22, 1994, “Nígbà tí A Bá Ba Afẹ́fẹ́ Àyíká Wa Jẹ́.”

    Yorùbá Publications (1987-2025)
    Jáde
    Wọlé
    • Yorùbá
    • Fi Ráńṣẹ́
    • Èyí tí mo fẹ́ràn jù
    • Copyright © 2025 Watch Tower Bible and Tract Society of Pennsylvania
    • Àdéhùn Nípa Lílò
    • Òfin
    • Ètò Nípa Ìsọfúnni Rẹ
    • JW.ORG
    • Wọlé
    Fi Ráńṣẹ́