Ì Bá Dára Ká Ní Afẹ́fẹ́ Mímọ́ Gaara Díẹ̀!
LÁTI ỌWỌ́ AṢOJÚKỌ̀RÒYIN JÍ! NÍ BRITAIN
NÍGBÀ tí o bá ń mí, ṣé afẹ́fẹ́ mímọ́ gaara lo ń mí sínú? Dókítà kan tí a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London sọ pé ìbafẹ́fẹ́jẹ́ òde òní jẹ́ “ọ̀tá kan tí ó burú ju sìgá mímu lọ.” Ní England àti ní Wales, afẹ́fẹ́ tí a kó èérí bá ń pa nǹkan bí 10,000 ènìyàn lọ́dọọdún. Ipò náà burú jákèjádò ayé, ní pàtàkì, ní àwọn ìlú ńlá.
Ọ̀pọ̀ ń dẹ́bi fún ilé iṣẹ́ ohun ìrìnnà fún bíba afẹ́fẹ́ àyíká jẹ́. Láti dín èéfín eléwu kù, a ń ṣe ọ̀pọ̀ ọkọ̀ tuntun pẹ̀lú ẹ̀yà ara tí ń dín èérí inú èéfín ọkọ̀ kù, tí ó sì ń yí èérí yìí padà di ohun aláìlóró. Afẹ́fẹ́ hydrocarbon inú gáàsì èéfín ọkọ̀ ti lọ sílẹ̀ sí ìpín 12 nínú ọgọ́rùn-ún iye tí ó jẹ́ ní 1970, pẹ̀lú irúfẹ́ ìdínkù kan náà nínú afẹ́fẹ́ nitrogen oxide àti carbon monoxide. Àwọn ọmọ tí a ń gbé kiri nínú kẹ̀kẹ́ ọmọdé ní ń fara gbà á jù, ní pàtàkì, nítorí pé kẹ̀kẹ́ náà máa ń wà ní ìwọ̀n déédéé ibi tí àwọn ọkọ̀ gbà ń tú èéfín jáde. Ṣùgbọ́n ìbafẹ́fẹ́jẹ́ ń fi àwọn tí ń bẹ nínú ọkọ̀ pàápàá sínú ewu. A gbọ́ ìròyìn pé ìbàjẹ́ náà jẹ́ ìlọ́po mẹ́ta nínú ọkọ̀ ju ní ìta rẹ̀ lọ. Àfikún ewu ń wá bí o ti ń fa oruku benzene sínú nígbà tí o ń rọ epo sínú ọkọ̀.
Ìròyìn ìsọfúnni oníṣirò kan nípa àyíká tí àjọ Ìparapọ̀ Orílẹ̀-Èdè gbé jáde fún 1993 sí 1994 sọ pé oríṣi ìbafẹ́fẹ́jẹ́ tí ó gbilẹ̀ jù lọ kárí ayé ní báyìí ni “Egunrín Ohun Tíntìntín Inú Afẹ́fẹ́.” Ó ṣe kedere pé ẹ̀gbọ̀n èédú, tàbí egunrín ohun tíntìntín, lè wọnú ẹ̀dọ̀fóró lọ, kí ó sì kó àwọn kẹ́míkà aṣèbàjẹ́ jọ síbẹ̀.
Ìmújoro ìpele ozone tí ó bo ayé mọ́lẹ̀ ń gbàfiyèsí ilé iṣẹ́ ìròyìn. Bí ó ti wù kí ó rí, ní ìpele ilẹ̀yílẹ̀, ìtànṣán oòrùn ń nípa lórí afẹ́fẹ́ nitrogen oxide àti àwọn ohun tí ó lágbára láti ba afẹ́fẹ́ jẹ́ mìíràn láti pèsè ọ̀pọ̀ yanturu ìwọ̀n ozone. Ìwọ̀n yìí ti di ìlọ́po méjì ní Britain láàárín ọ̀rúndún yìí. Àwọn gáàsì wọ̀nyí ń ba ọ̀dà àti àwọn ohun ìkọ́lé mìíràn jẹ́, wọ́n ń fa àrùn lára igi, ewéko, àti irè oko, ó sì jọ pé wọ́n ń fa ìṣòro èémí fún àwọn ènìyàn kan. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé, ọ̀pọ̀ jù lọ ìsọdèérí ozone yìí ń ṣẹlẹ̀ ní àwọn ìlú ńlá, ó yani lẹ́nu pé àwọn agbègbè àrọko ní ń jìyà àbájáde rẹ̀ búburú jù lọ. Ní àwọn agbègbè ìlú ńlá, afẹ́fẹ́ nitrogen oxide ń fa àpọ̀jù afẹ́fẹ́ ozone gbẹ, ṣùgbọ́n níbi tí afẹ́fẹ́ oxide kò ti pọ̀, afẹ́fẹ́ ozone ní òmìnira láti ṣe ìjàm̀bá.
Láfikún, ìwé agbéròyìnjáde The Times ròyìn pé ìbafẹ́fẹ́jẹ́ “tó ìlọ́po 70 nínú ilé ju níta lọ.” Níhìn-ín ni èéfín láti inú ohun amáfẹ́fẹ́ tura, ohun atasánsán tí a fi ń lé àwọn kòkòrò jaṣọjaṣọ dà nù, àti àwọn aṣọ tí a fọ̀ pàápàá ń ba afẹ́fẹ́ jẹ́. Èéfín sìgá bákan náà ń fi kún ewu ìlera nínú ilé.
Nígbà náà, kí ni o lè ṣe láti dáàbò bo ìdílé rẹ? Ìwé agbéròyìnjáde The Times ti London dá àwọn àbá wọ̀nyí.
• Dín ìlò ọkọ̀ rẹ kù. Bí ó bá ṣeé ṣe, bá àwọn mìíràn wọkọ̀ pọ̀. Wa ọkọ̀ geere. Bí o bá há sínú súnkẹrẹ-fàkẹrẹ ọkọ̀, tàbí tí o wà lójú kan ju ìwọ̀n ìṣẹ́jú díẹ̀, paná ọkọ̀. Bí ó bá ṣeé ṣe, gbé ọkọ̀ rẹ síbòòji ní ọjọ́ tí oòrùn bá mú hanhan láti dín ìbafẹ́fẹ́jẹ́, tí epo tí oòrùn ń fà, ń mú wá kù.
• Máa ṣeré ìmárale lọ́wọ́ àárọ̀ nígbà tí ìpele ozone máa ń kéré níta ní gbogbogbòò.
• Fòfin de mímu sìgá nínú ilé.
• Máa ṣí fèrèsé ibùsùn níwọ̀nba lálẹ́ láti dín ọ̀rinrin kù, kí ohun tí ó bá lè ṣàìbára dé sì lè jáde síta.
Dájúdájú, ìwọ yóò gbà pé: Ì bá dára ká ní afẹ́fẹ́ mímọ́ gaara díẹ̀!