Wíwá Ojútùú Ṣíṣètẹ́wọ́gbà
OHUN ÌRÌNNÀ nìkan kọ́ ní ń fa ìbàyíkájẹ́. Àwọn ilé àdáni, ilé iṣẹ́ ẹ̀rọ aṣeǹkanjáde, àti ilé iṣẹ́ amúnáwá gbọ́dọ̀ ṣàjọpín ẹ̀bi náà. Síbẹ̀, ipa tí ohun ìrìnnà ń kó nínú ìbàyíkájẹ́ kárí ayé tó gbàfiyèsí.
Ní gidi, ìwé 5000 Days to Save the Planet tiraka sọ pé: “Bí a bá ní láti ro ti gbogbo ewu tí ọkọ̀ ń fà wọ̀nyí—ní pàtàkì, ewu tí ìtújáde afẹ́fẹ́ carbon dioxide fi ń wu ojú ọjọ́ wa—a jẹ́ pé a kì bá tí ṣe ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ rárá.” Síbẹ̀síbẹ̀, ó gbà pé: “Ṣùgbọ́n ìyẹ́n jẹ́ yíyàn kan tí yálà àwọn tí ń ṣe ọkọ̀ jáde, tàbí àwọn tí ń la títì, tàbí àwọn ẹ̀ka iṣẹ́ ìjọba, tàbí ará ìlú ní gbogbogbòò gan-an, tí ìgbé ayé wọ́n sinmi lórí níní ọkọ̀ ara ẹni, kò múra tán láti gbé yẹ̀ wò.”
Kò ha yẹ kí ìmọ̀ ẹ̀rọ tí ó gbé ènìyàn dé orí òṣùpá lè mú ọkọ̀ tí kì í bàyíká jẹ́ jáde? Ṣíṣe kò fìgbà kankan rọrùn bíi sísọ, nítorí náà, títí a óò fi borí àwọn ìdènà sí ṣíṣe ọkọ̀ tí kò lè bàyíká jẹ́, wíwá ojútùú ṣíṣètẹ́wọ́gbà ń bá a lọ.
Dídín Àwọn Ohun Aṣèbàjẹ́ Kù
Ní àwọn ọdún 1960, United States ṣòfin tí ń béèrè pé kí a fi àwọn ohun ti ń dín ìtújáde ohun aṣèbàjẹ́ kù sínú àwọn ohun ìrìnnà. Àwọn orílẹ̀-èdè àti ìjọba mìíràn ti ṣe bákan náà láti ìgbà náà wá.
Ohun tí ń yí èéfín olóró padà, tí ń bèèrè fún lílo epo mọ́tò tí kò ní òjé nínú, ni a ń lò níbi púpọ̀ nísinsìnyí láti fi sẹ́ àwọn ohun eléwu tí ń bàyíká jẹ́ dà nù. Láàárín ọdún 1976 sí 1980, lẹ́yìn tí ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ onímọ́tò bẹ̀rẹ̀ sí í lo epo mọ́tò tí kò ní òjé, ìwọ̀n òjé inú ẹ̀jẹ̀ àwọn ará America lọ sílẹ̀ ní ìdá mẹ́ta. Ó sì dára pé ó ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí àpọ̀jù òjé lè ba ètò ìgbékalẹ̀ ọpọlọ jẹ́, kí ó sì ṣèdíwọ́ fún agbára ìkẹ́kọ̀ọ́. Bí ó ti wù kí ó rí, ó bani nínú jẹ́ pé, nígbà tí ìwọ̀n òjé inú ara ti dín kù ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè tí ó ti gòkè àgbà, kò rí bẹ́ẹ̀ ní àwọn orílẹ̀-èdè tí kò ì gòkè àgbà.
Àṣeyọrí tí àwọn ohun tí ń yí èéfín olóró padà ti ṣe ń tẹ́ni lọ́rùn, ṣùgbọ́n awuyewuye ṣì wà lórí lílò wọ́n. Nítorí ìdínkù tí ó bá agbára ọ̀nà ìṣiṣẹ́ ẹ̀rọ nígbà tí a kò lo òjé mọ́, a yí àpòpọ̀ afẹ́fẹ́ hydrocarbon inú epo mọ́tò padà. Èyí ti yọrí sí ìlọsókè nínú ìtújáde àwọn ohun mìíràn tí ń fa àrùn jẹjẹrẹ, bí èròjà benzene àti toluene, tí àwọn ohun tí ń yí èéfín olóró padà kì í dín ìwọ̀n ìtújáde wọn kù.
Yàtọ̀ sí ìyẹn, àwọn ohun tí ń yí èéfín olóró padà nílò èròjà platinum. Gẹ́gẹ́ bí Ọ̀jọ̀gbọ́n Iain Thornton, ti Kọ́lẹ́ẹ̀jì Imperial ní Britain ti wí, ọ̀kan lára àbájáde búburú wọn ni ìsọdipúpọ̀ èròjà platinum nínú eruku etí títì. Ó kìlọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí “apá tí ń yòrò nínú èròjà platinum wọnú ètò àyípoyípò oúnjẹ.”
Láìka àṣeyọrí yòówù kí “àwọn ohun tí ń yí èéfín olóró padà ní Àríwá America, Japan, Gúúsù Korea àti ọ̀gọ̀ọ̀rọ̀ orílẹ̀-èdè Europe” ti ní sí, ìwé 5000 Days to Save the Planet jẹ́wọ́ gbà kedere pé, “ìpọ̀rẹpẹtẹ iye ọkọ̀ kárí ayé ti ṣíji bo àǹfààní rẹ̀ lórí ìjójúlówó afẹ́fẹ́ pátápátá.”
Títẹ̀ Ẹ́ Jẹ́jẹ́
Ọ̀nà míràn láti dín ìtújáde afẹ́fẹ́ ọkọ̀ kù ni láti tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́. Ṣùgbọ́n ní United States, àwọn ìpínlẹ̀ kan ti fi kún ìwọ̀n eré sísá ọkọ̀ láìpẹ́ yìí. Ní Germany, gbígbé òfin kalẹ̀ kò ṣètẹ́wọ́gbà. Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn awakọ̀, àwọn tí ń ṣe ọkọ̀ jáde, tí kókó ìtẹnumọ́ ọjà títà wọ́n sinmi lórí bí wọ́n ti lè ṣe ọkọ̀ lílágbára tí ó lè fàyè gba títú u sílẹ̀ kọjá ìwọ̀n 150 kìlómítà ní wákàtí kan, nírọ̀rùn, kì í sábà fara mọ́ dídín ìwọ̀n eré ọkọ̀ kù. Bí ó ti wù kí ó rí, nísinsìnyí, ó jọ pé púpọ̀ sí i àwọn ará Germany ń fẹ́ láti fara mọ́ fífi òté lé eré ọkọ̀, kì í ṣe nítorí ìbàyíkájẹ́ lásán, ṣùgbọ́n nítorí ààbò pẹ̀lú.
Ní àwọn orílẹ̀-èdè kan, a béèrè pé kí àwọn awakọ̀ máa tẹ̀ ẹ́ jẹ́jẹ́ nígbà ti ìbàyíkájẹ́ bá dé ìpele kan tí kò bára dé—tàbí bóyá kí wọ́n tilẹ̀ ṣíwọ́ ọkọ̀ wíwà fúnra rẹ̀ gan-an. Ìwádìí kan ní ọdún 1995 fi hàn pé ìpín 80 nínú ọgọ́rùn-ún àwọn ará Germany yóò fara mọ́ fífi òté lé eré sísá bí ìpele ozone bá ga jù. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìlú ńlá kárí ayé, títí kan Ateni àti Romu, ti gbé ìgbésẹ̀ fífòfin de ọkọ̀ wíwà lábẹ́ àwọn ipò kan. Àwọn mìíràn ń ṣàgbéyẹ̀wò ṣíṣe bákan náà.
Lílo Kẹ̀kẹ́
Láti dín ohun ìrìnnà kù, àwọn ìlú ńlá kan ti dín owó wíwọ bọ́ọ̀sì kù. Àwọn mìíràn pèsè wíwọ bọ́ọ̀sì lọ́fẹ̀ẹ́ fún àwọn awakọ̀ tí wọ́n ń san owó pọ́ọ́kú láti gbé ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ wọn síbi ìgbọ́kọ̀sí tí ó wà ládùúgbò. Àwọn ìlú mìíràn ní àkànṣe òpópó ọ̀nà fún kìkì àwọn bọ́ọ̀sì àti takisí láti mú kí ìrìn wọ́n yá kánkán.
Láìpẹ́ ni a sọ nípa ọ̀nà ọ̀tun kan láti kojú ìṣòro náà nínú ìwé agbéròyìnjáde The European pé: “Bí ìgbétásì kan ní Netherlands ní apá ìparí àwọn ọdún 1960 ṣe sún wọn ṣiṣẹ́, àwọn ará Denmark ti gbé ìwéwèé kan kalẹ̀ láti dín ìbafẹ́fẹ́jẹ́ àti ìlọ́lùpọ̀ ọkọ̀ kù nípa rírọ àwọn ènìyàn láti máa gun kẹ̀kẹ́ dípò wíwọ mọ́tò.” A kó àwọn kẹ̀kẹ́ sí onírúurú ibi ní gbogbo òpópó Copenhagen. Wíwulẹ̀ sọ owó ẹyọ kan sínú ẹ̀rọ àdọ́gbọ́nṣe kan yóò mú kẹ̀kẹ́ kan wà lárọ̀ọ́wọ́tó fún lílò. O lè gba owó àsansílẹ̀ náà padà nígbà tí o bá dá kẹ̀kẹ́ náà padà síbi yíyẹ kan. Bóyá ìṣètò yìí yóò gbéṣẹ́, tí yóò sì ṣètẹ́wọ́gbà, kò tí ì dájú.
Láti fún lílo kẹ̀kẹ́ dípò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ níṣìírí, àwọn ìlú kan ní Germany fàyè gba àwọn agunkẹ̀kẹ́ láti máa lọ bọ̀ lójú ọ̀nà tí ó wà fún àlọ nìkan! Níwọ̀n bí nǹkan bí ìdá mẹ́ta gbogbo ìrìn àárín ìlú àti èyí tí ó lé ní ìdá mẹ́ta ìrìn àrọko ti dín ní kìlómítà mẹ́ta, ọ̀pọ̀ ará ìlú lè fẹsẹ̀ rìn wọ́n tàbí kí wọ́n gun kẹ̀kẹ́. Èyí yóò dín ìbàyíkájẹ́ kù; nígbà kan náà, àwọn agunkẹ̀kẹ́ yóò máa ṣe eré ìmárale tí ará nílò.
Títún Ìgbékalẹ̀ Ṣe
A ṣì ń báṣẹ́ lọ lórí ṣíṣàgbékalẹ̀ àwọn ọkọ̀ tí kì í bàyíká jẹ́. A ti ṣe àwọn ọkọ̀ oníná mànàmáná tí ń lo bátìrì, ṣùgbọ́n agbára wọ́n mọ níwọ̀n ní ti ìwọ̀n eré sísá àti àkókò tí wọ́n fi ń ṣiṣẹ́. Bákan náà ni ó rí pẹ̀lú àwọn tí ń lo agbára oòrùn.
Ṣíṣeé ṣe mìíràn tí a ń wádìí lé lórí ni fífi afẹ́fẹ́ hydrogen ṣiṣẹ́. Afẹ́fẹ́ hydrogen ń ṣiṣẹ́ láìtú ohun asọǹkandèérí jáde, ṣùgbọ́n ó wọ́nwó jù.
Ní mímọ àìní náà láti tún àmújáde ọkọ̀ ṣe, ààrẹ United States, Clinton, kéde ní 1993 pé ìjọba àti ilé iṣẹ́ ohun ìrìnnà ti United States yóò fọwọ́ sowọ́ pọ̀ láti ṣàgbékalẹ̀ ọkọ̀ tí yóò bá ọjọ́ iwájú mu. Ó wí pé: “A óò gbìyànjú láti fi gbankọgbì ìdáwọ́lé iṣẹ́ ẹ̀rọ tàkàntakan kan lọ́lẹ̀, tí yóò gba òye iṣẹ́ gan-an bí ìdáwọ́lé èyíkéyìí tí orílẹ̀-èdè wa tí ì ṣe rí.” A kò tí ì lè pinnu bóyá yóò ṣeé ṣe “láti ṣẹ̀dá ohun ìrìnnà tí yóò gbéṣẹ́ láìkù síbì kan, tí yóò sì bá àyíká àti ohun alààyè rẹ̀ mu fún ọ̀rúndún kọkànlélógún” tí ó ń sọ. Ìwéwèé náà sọ ọ́ di dandan láti ṣe àwòkọ́ṣe kan láàárín ẹ̀wádún kan—ní iye owó gegere kan, bí ó ti wù kí ó rí.
Àwọn olùṣèmújáde ọkọ̀ kan ń ṣiṣẹ́ lórí oríṣi ọkọ̀ tí yóò máa lo epo mọ́tò àti iná mànàmáná lápapọ̀. Ọ̀kan tí ó ti wà lárọ̀ọ́wọ́tó ní Germany—ní iye owó gíga—ni ọkọ̀ ayárakánkán onílẹ̀kùn méjì tí ń lo iná mànàmáná, tí a lè mú yára sáré dé orí 100 kìlómítà láàárín ìṣẹ́jú àáyá mẹ́sàn-án tí ó bá gbéra, tí ó sì ń yára sáré lọ sórí 180 kìlómítà ní wákàtí kan. Ṣùgbọ́n bí ó bá ti rin 200 kìlómítà, yóò dúró gbọnyin dìgbà tí àwọn bátìrì rẹ̀ bá tún gbagbára fún wákàtí mẹ́ta, ó kéré tán. Ìwádìí ṣì ń bá a lọ, a sì ń fojú sọ́nà fún ìtẹ̀síwájú sí i.
Kìkì Apá Kan Lára Ìṣòro Náà
Kíkásẹ̀ ìtújáde onímájèlé nílẹ̀ wulẹ̀ jẹ́ apá kan ìṣòro náà ni. Àwọn ọkọ̀ tún máa ń fa ìbàyíkájẹ́ ariwo, ohun kan tí àwọn tí ń gbé ẹ̀bá títì tí ọkọ̀ ń kún fọ́fọ́ mọ̀ dáradára. Níwọ̀n bí ariwo ọkọ̀ tí ń bá a lọ láìdẹwọ́ ti lè pa ìlera lára, èyí pẹ̀lú jẹ́ apá ìpìlẹ̀ kan nínú ìṣòro náà tí a ní láti yanjú.
Àwọn tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ ohun àdánidá pẹ̀lú lè tọ́ka sí i pé ọ̀pọ̀ àrọko ẹlẹ́wà àdánidá ni a ti bà jẹ́ pẹ̀lú àwọn òpópónà ọlọ́pọ̀ ibùsọ̀, pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn ibi ìtajà àti pátákó ìpolówó ọjà tí a lè tò sẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ wọn. Ṣùgbọ́n bí iye àwọn ọkọ̀ ti ń pọ̀ sí i ni a ṣe ń nílò títì púpọ̀ sí i tó.
Àwọn ohun ìrìnnà kan, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún tí wọ́n ti fi ba àyíká jẹ́ lọ́wọ́ ẹni tí ó ni wọ́n, tún ń bá ìbàyíkájẹ́ náà lọ “lẹ́yìn ikú” wọn pàápàá. Àwọn ògbólógbòó ọkọ̀ tí a ti pa tì, tí wọ́n wulẹ̀ ń ba ìran ojú jẹ́, ti di ìṣòro ńlá tó bẹ́ẹ̀ tí ó fi di dandan ní àwọn ibì kan láti ṣòfin, kí a lè dènà bí wọ́n ṣe ń ba agbègbè àrọko jẹ́ láìyẹ. Ǹjẹ́ a óò ha ṣe ọkọ̀ tí ó bá nǹkan mu jù lọ, tí a fi àwọn ohun tí a lè tún lò ṣe láé bí? A kò ì róye irú ohun ìrìnnà bẹ́ẹ̀ rárá.
Ìwé agbéròyìnjáde ẹnu àìpẹ́ yìí kan sọ pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ará Germany ni ọ̀ràn àyíká ń jẹ lọ́kàn gan-an,” ní fífi kún un pé, “ṣùgbọ́n ìwọ̀nba díẹ̀ ní ń ṣe nǹkan kan nípa rẹ̀.” A fa ọ̀rọ̀ òṣìṣẹ́ ìjọba kan yọ tí ó sọ pé: “Kò sí ẹni tí ń ronú sí ara rẹ̀ bí ọ̀dádá náà, tàbí ẹni tí ó fẹ́ kí a tọ́ka sí òun bẹ́ẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ ni, àwọn ìṣòro kò rọrùn láti yanjú nínú ayé kan tí ó ní àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ “olùfẹ́ ara wọn” àti “aláìṣeé bá ṣe àdéhùn kankan.”—2 Timoteu 3:1-3.
Síbẹ̀, wíwá ojútùú ṣíṣètẹ́wọ́gbà ń bá a lọ. A ha lè rí ojútùú tí ó bá a mu jù lọ sí ìbàyíkájẹ́ àti ohun ìrìnnà láé bí?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Lílo ọkọ̀ èrò, àjùmọ̀lò ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí gígun kẹ̀kẹ́, ha lè dín ìbàyíkájẹ́ kù bí?